Osborne Theomun Olsen

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Osborne Theomun Olsen
Osborne Theomun Olsen (ọdún 1883 sí ọdún 1971)
Ọjọ́ìbí(1883-06-09)Oṣù Kẹfà 9, 1883
Chicago, Illinois
AláìsíJanuary 9, 1971(1971-01-09) (ọmọ ọdún 87)
Chicago, Illinois
Iṣẹ́Porcelain
Olólùfẹ́
Augusta Schmidt (m. 1905–1971)
Àwọn ọmọPerry Olsen (1907-1974)
Evelyn Olsen (1909-2002)
Parent(s)Anna Maria Jensen (1854-c1895)
Peder Matthias Olsen (1849-1896)

Osborne Theomun Olsen (Ọjọ́ kẹsán Oṣù kẹfà Ọdún 1883 – Ọjọ́ kẹsán Oṣù kínín Ọdún 1971) olùdásílẹ̀ Art Studios ní Chicago, Illinois, tí ó wà láti 1910 di 1973.[1][2]

Ìgbésíayé rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n bi Osborne ní Chicago, Illinois ní Ọjọ́ kẹsán Oṣù kẹfà Ọdún 1883. Àwọn òbí ẹ ni  Anna Maria Jensen (1854-1896) àti Peder Matthias Olsen (1849-1896) ti ìlú  Farsund, Norway. Osborne ní àwọn àbúrò wọnyí: Jennie Olsen (1881-?), Perry Olsen (1885-1971), àti Harriet Olsen (1889-?).[1]

 Hyperthermia ni ó pa bàbá rẹ̀ ní ìgbà 1896 Eastern North America heat wave ní Chicago.

Àwọn òbí rẹ̀ méjèèjì kú ní bíi 1900, àwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin lọ gbé ọ̀dọ̀ àbúrò ìyà wọn Johanna Katrine Jensen (1857-1946). Katherine bí ọmọ méjì: Henry Barca (1886-1961) àti Leo Barca (1887-1924). Ní1900 Osborne ti ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bíi aṣenilẹ́ṣọ́.[3] Ní ìgbà tí ó maa fi di bíi Ọdún 1911 ó ti di ọmọ ẹgbẹ́ Art Institute of Chicago.[4]

Osborne fẹ́ ìyàwó tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Augusta Schmidt (1883-1974) ní ọjọ́ kẹta Oṣù kẹfà Ọdún 1905, ní Chicago tí wọ́n sì bí àwọn ọmọ wọ̀nyí: Perry Olsen (1907-1974) àti Evelyn Olsen (1909-2002). Ní  1910 ó bẹ̀rẹ̀ sí ní lo orúkọ  "Asbjorn T. Olsen".

O di olóògbé ní Ọjọ́ kẹsán Oṣù kínín Ọdún 1971, ètò ìsìnkú rẹ̀ sì di àtẹ̀jáde ní Chicago Tribune ní Ọjọ́ kọkànlá Oṣù kínín Ọdún 1971. Wọ́n sin Osborne ní Ọjọ́ kínín Oṣù kejìlá ní  Acacia Park Cemetery, Chicago. Opó rẹ̀ , Augusta, àti ọmọkùnrin rẹ̀, Perry tẹ̀síwájú nínú ịsẹ́ china rẹ̀ 1973.[1]

Osborne Art Studio[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Osborne ní Osborne Art Studio sí Chicago (wọ́n maa ń kọọ́ báyí ní ìgbàmíràn: "Osbourne Art Studio") tí ó maa ń ṣe porcelain àti àwọn àmọ̀ lẹ́ṣọ́ . Ó  maa ń ra  porcelin lọ́wọ́ Hutschenreuther àti àwọn míràn tí ó sì maa ṣéé lẹ́ṣọ́.

Helaine Fendelman àti Joe Rosson kọ́ pé: "Kò sí ẹni tí ó lè yiri ẹ̀ wò wípé iṣẹ́ Osborne kò dára ṣùgbọ́n wọ́n maa ń fẹ̀sùn kàn-án wípé ó maa ń wo iṣẹ́ oníṣẹ ṣe tirẹ̀ púpọ̀, èyí sì maa ń ṣàkóbá fún àwọn iṣẹ́ rẹ̀."[2]

Ibi ìṣàfihàn iṣẹ́ rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. 1.0 1.1 1.2 "Osborne Olsen".
  2. 2.0 2.1 Helaine Fendelman and Joe Rosson (May 1, 2001).
  3. 1900 US Census for Chicago, Illinois
  4. Art Institute of Chicago Annual Report.