Jump to content

Osu caste

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Àṣà Osu caste jẹ́ àṣà ní |Ilẹ̀ Ìgbò tí ó lòdì sí ìbádọ́rẹ́ àti fífẹ́ àwọn ènìyàn kan tí wọ́n ń pè ní Osu.[1][2] Nínú ìtàn, àwọn Osu jẹ́ ẹrú òrìṣà (Alusi) ti àwọn Igbo; wọ́n gbàgbọ́ pé àwọn Osu kìí ṣe ènìyàn pàtàkì bi Nwadiala tàbí diala.[3]

Bí ó ti bẹ̀rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n ti mọ àwọn kan bi osu láti ìgbà tí àwọn ilẹ̀ íbọ̀ ti wà lábé òfin ilẹ̀ tí a ń pè ní Odinani. Òrìṣà tí wọ́n ń pè ní Ala ni ó ṣe òfin tí àwọn ènìyàn gbọ́dọ̀ tẹ̀lẹ́ kí wọ́n bà le ṣe rere, kí elédùmarè tí wọ́n sì ma ń pè ní Chukwu, ba le súre fún wọn. Àwọn tí ó pa tàpá sí òfin yìí ni wọ́n ma lé jáde kí òrìṣà má bà bínú sí wọn, àti pé, kí ìwà yí má bá ma tàn káàkiri, àwọn ènìyàn tí wọ́n lé jáde yìí ni wọ́n ń pè ní Osu. Wọ́n ma ń tà wọ́n fún ẹrú tàbí kí wọ́n fi wọ́n rúbọ sí àwọn òrìṣà tí wọ́n gbàgbọ́ pé ó ń bẹ̀rẹ̀ fún ìrúbọ láti "wẹ ilẹ̀ náà mọ́".[4] Àwọn míràn di oṣú nítorí pé wọn kò tẹ̀lẹ́ ìlànà ọba tàbí ìlànà ìlú.[5]

Àwọn Ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. Ugoji Egbujo (13 March 2015). "The Osu caste system: The shame of a Nation". Vanguard. http://www.vanguardngr.com/2015/03/the-osu-caste-system-the-shame-of-a-nation/. 
  2. Andew Walker (7 April 2009). "The story of Nigeria's 'untouchables'". BBC News. Archived from the original on 11 June 2015. https://web.archive.org/web/20150611095010/http://news.bbc.co.uk/2/hi/africa/7977734.stm. 
  3. David Aduge-Ani, Stanley Uzoaru & Okechukwu Obeta (31 October 2014). "Osu Caste System: How It Affects Marriages In The S/East". Leadership Nigeria. http://www.leadership.ng/features/388826/osu-caste-system-affects-marriages-seast.  Alt URL
  4. Amadife, ‘The Culture That Must Die’ Sunday Times, March 23, 1988.
  5. Ezekwugo, C.M (1987). Ora-Eri Nnokwa and Nri Dynasty. Enugu: Lengon Printers.