Jump to content

Oyún

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Pregnancy_trimesters Pregnant_woman

Oyún jẹ́ àkókò tí ọ̀kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ, ọmọ tí ń dàgbà sínú ilé-ọmọ obìnrin.

Oyún púpọ̀ kan máa ń jẹ́ ju ọmọ kan lọ, gẹ́gẹ́ bí Ìbejì.[1] Oyún máa ń wáyé nípasẹ̀ ìbálòpọ̀, ṣùgbọ́n ó tún lè wáyé nípasẹ̀ àwọn ìlànà ìrànlọ́wọ́ ìmọ̀-ẹ̀rọ láti gbáyán mì.[2] Oyún lè já sí ìbímọ láàyè, ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó wáyé nígbà tí oyún bá jábọ́ lára obìnrin, ìṣẹyun, tàbí ìbímọ tí ọmọ ti kú láti inú wá. Ìbímọ máa ń wáyé ní àyíká ogójì ọ̀sẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀ àkókò nǹkan oṣù tí ó kẹ́hìn, ìgbà tí a mọ̀ sí ọjọ́ oyún. [3] Èyí ju oṣù mẹ́ẹ̀sán lọ. Tí a bá ka àkókò tí olẹ̀ sọ, àkókò ẹ̀ jẹ́ bí èjì-dín-lógójì ọ̀sẹ̀. [3]

Oyún jẹ́ ìfarahàn ọlẹ̀ tó so nínú obìnrin; ìfarahàn yìí máa ń wáyé ní ó kéré jù ọjọ́ mẹ́jọ sí mẹ́sàán lẹ́hìn tí ọlẹ̀ bá so. [4]

Ọmọ inú oyún jẹ́ ọ̀rọ̀ fún ọmọ tó ń ṣẹ̀ṣẹ̀ ń dàgbà sókè ní ọ̀sẹ̀ méje àkọ́kọ́ tí ọlẹ̀ ti so (àpẹẹrẹ: ọjọ́-orí oyún: ọ̀sẹ̀ mẹ́wàá), lẹ́hìn tí a ma lo ọ̀rọ̀ - ọmọ inú oyún títí di ìbímọ tí ọmọ ma sọ̀. [5]

Omi Omú

Ilé-omo