Patience Ozokwor

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Patience Ozokwor níbi ìṣètò fiimu
Patience Ozokwor
Ọjọ́ìbíỌjọ́ kẹrìnlá oṣù kẹsàn-án ọdún 1958
Ngwo ní ìpínlè Enugu
Ọmọ orílẹ̀-èdèNaijiria
Iléẹ̀kọ́ gígaInstitute of management and technology
Iṣẹ́òṣèré . akọrin

Patience Ozokwor (tí wọ́n bí ní Ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kẹsàn-án ọdún 1958) jẹ́ òṣèré sinimá-àgbéléwò, akọrin ìyìn rere àti olùránṣọ ọmọ bíbí ìlú Ngwọ ní ìpínlẹ̀ Enugu lorílẹ̀-èdè Nàìjíríà.[1] Ó gbajúmọ̀ nípa ṣíṣe ère tí ẹ̀dá-ìtàn rẹ̀ sáàbà máa ń burú. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àmín ẹ̀yẹ ló ti gbà lórí siniá-àgbéléwò ṣíṣe. Lára wọn ni àmìn ẹ̀yẹ Movie Academy Awards fun amúgbalẹ̀gbẹ̀ẹ́ ẹ̀dá-ìtànbìrin tó dára jùlọ lọ́dún 2012 àti 2013. Ó gbajúmọ̀ débi pé Ìjọba Àpapọ̀ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà dá a lọ́lá pẹ̀lú àwọn mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún mìíràn nígbà ayẹyẹ ọgọ́rùn-ún ọdún ìsọdọ̀kan apá ìlà-oòrùn àti àríwá orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lọ́dún 2014.[2] [3] [4]

Ìtàn ìgbésí-ayé rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Gégé bí a ṣe sọ ṣáájú, wọ́n bí Patience Ozokwor ní ìlú Ngwo ní ìpínlè Enugu, lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà, ṣùgbọ́n ìlú Èkó ló ti bẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ rẹ̀ kíkà ní ilé-ìwé Abimbola Gibson Memorial School. Ó tẹ̀ síwájú nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní ilé ìwé gígaInstitute of management and technology ní ìpínlẹ̀ Enugu, níbi tí ó ti kàwé gboyè dìgírì àkọ́kọ́ nínú ìmọ̀ nǹkan yíyà (Fine Art). Láti ìgbà èwe rẹ̀, láti ilé ìwé àkọ́bẹ̀rẹ̀ ní Patience Ozokwor ti fẹ́ràn ère orí ìtàgé, láti ìgbà náà ló ti máa ń kópa oríṣiríṣi ní ilé-ìwé àkọ́bẹ̀rẹ̀. Nítorí ìdí èyí, ó ti di ìlúmọ̀ọ́kà kí ó tó gbajúmọ̀ nìdí sinimà àgbéléwò. Ó kópa pàtàkì nínú sinimà aṣàfihàn lórí ẹ̀rọ amọ́hùnmáwòrán, the Nigerian Television Authority (NTA), tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ "Someone Cares" Nígbà tí ó wà lọ́mọ ọdún ókàndínlógún ló ti fẹ́ oko, ó bímọ mẹ́ta fúnrarẹ̀, ó sìn gba ọmọ márùn-ún tọ́, tí gbogbo wọn sìn ń jẹ́ orúkọ rẹ̀. Ọkọ rẹ̀ kú lọ́dún 2000. Kò sìn lọ́kọ mìíràn mọ́.[5]

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "Patience Ozokwo’s Biography, Filmography". InformAfrica.com. 2012-05-08. Archived from the original on 2020-11-10. Retrieved 2019-11-20. 
  2. vanguard; vanguard (2014-03-01). "Jonathan decorates Obasanjo, Buhari, IBB, others with centenary awards". Vanguard News. Retrieved 2019-11-20. 
  3. "BlueHost.com". Welcome diamondcelebrities.com. 2014-03-25. Archived from the original on 2018-10-21. Retrieved 2019-11-20. 
  4. "Patience Ozokwor (Mama Gee) – Biography, Late Husband, Children, Facts". BuzzNigeria - Famous People, Celebrity Bios, Updates and Trendy News. 2014-05-26. Retrieved 2019-11-20. 
  5. "" I Miss My Husband's Love And Companion" Patience Ozokwor". Pulse Nigeria. 2014-03-25. Retrieved 2019-11-20.