Paul Émile Chabas

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Paul Émile Chabas
Chabas circa 1897
Ilẹ̀abínibí Faransé
Pápá ayàwòrán
Iṣẹ́ September Morn (1912)

Paul Émile Chabas (Ọjọ́ keje Oṣù kẹta Ọdún 1869 – Ọjọ́ kẹwá Oṣù karún Ọdún1937) jẹ́ olùyàwòrán ará Faransé àti ọmọ ẹgbẹ́  Académie des Beaux-Arts.

Ìgbésíayé[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Paul Chabas's September Morn, 1912, epo lórí igbokun, Metropolitan Museum of Art, New York

Wọ́n bíi ní Nantes, ó sì kọ iṣẹ́ ọnà lábẹ́ William-Adolphe àti Tony Robert-Fleury. Ó kọ́kọ́ ṣe àfihàn iṣẹ́ rẹ̀ ní Salon ní ọdún 1890. Chabas gba ẹbùn Prix National ní ọdún 1899 ní Paris Salon pẹ̀lú Joyeux Ébats rẹ̀.[1] Wọ́n fún ní ẹ̀bùn góòlú ní Exposition Universelle of 1900 àti ní ọdun 1912 tí ó gba Médaille d’honneur.[2] Àwọn ẹka ọnà tí ó fẹ́ràn ni yíya ọoṃdébìrin tí ó wà ní ìhòho. Wọ́n gbàá ní ọ̀gá ní yiya ìhòhò ní gbogbo ilẹ̀ Yúróòpù.[1]

Àwọn àwòrán rẹ̀ tó lókìkí jùlọ ni , September Morn (1912), tí ó di "succès de scandale" ní  United States ní oṣù karún ọdún 1913, nígbàtí  Anthony Comstock, olórí New York Society for the Suppression of Vice, ṣe àtako àwòrán yìí wípé kò bójú mu. Inú bí Chabas púpọ̀ lori rògbòdìyàn tí àwòrán yìí fà. Ní igbàkan ó ṣàìfi ara hàn ní Gúúsù ti France.[3]  Ìpolongo pọ̀ lórí rẹ̀ tí wọ́n ṣe àtùnyà rẹ̀ tí wọ́n sì ń tàá fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún. Wọ́n maa ń lo September Morn  gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ fún kitsch. Chabas kọ̀ jạ́lẹ̀ láti wọ́n mọ ẹni tí àwòrán yìí jẹ́, ọ́ kàn pèé ní "Marthe"..[4]

Bíótilẹ̀jẹ́pé rògbòdìyàn yìí kò dáwọ́ dúró. Ní bíi ìkẹyìn ọdún 1935, àwọn ènìyàn gbọ́ ìró wípé ọmọbìrin tí ó jẹ́ àwòran yìí jẹ ẹnìkan tí ìyà ń jẹ́ tí ó n gba lẹ́tà láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn ní U.S tí ó maa ràn-àn lọ́wọ́. Ó tún rántí bí àwọn ènìyàn kan ní U.S ti sọ wípé àwòrán yìí kò bójú mu ní bíi ogún ọdún ṣ́yìn.[5] Chabas kọ́kọ́ lọ sí United States ní ọdún 1914 fún abala ìyàwòrán kan. Kí ó to rin ìrìnàjò yìí, ó sọ wípé oun kò fẹ́ran US, tí ó sì kọ̀ láti ta September morn fún olùtẹ̀jáde ìwé ìròyìn US, lẹ́yìn tí rògbòdìyàn nípa àwòrán yìí bẹ̀rẹ̀. Ó sọ wípé oun kò ní ìpinu láti ta àwòrán yìí, nítorí oun ni ìyàwó rẹ̀ fẹ́ràn jùlọ. Nígbà tí ó ọjà àwòran, ó dá ẹgbẹ̀rún lọ́nà mẹ́wá dọ́là lée lórí tí ó sì ní ìgbàgbọ́ wípé kò sí ẹni tí ó maa ràá. Leon Mantashev, ọmọ Alexander Mantashev, gbajúgbajà elépo ni ó fẹ́ ràá tí ó sì tàá fun.[6]

Gallery[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]