Peter Fatomilola

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Jump to navigation Jump to search

{{subst:afd|help=off}}

Peter Fatomilola
Ọjọ́ìbí 16, January 1946
Ekiti State, Nigeria.
Orílẹ̀-èdè Nigerian
Orúkọ míràn First Papa Ajasco
Ọmọ orílẹ̀-èdè Nigerian
Iṣẹ́

olukotan
Akewi
osere ori-itage
Known for SangoWọ́n bí Peter Fátómilọ́lá ní ọjọ́ kẹrìndínlógún oṣù kínní ọdún 1946. Ó jẹ́ ọmọ bíbí ilẹ̀ Nàìjíríà,  ó sì jẹ́ òṣèré orí ìtàgé, olùkọ̀tàn, akéwì àti ògúná gbòǹgbò níbi ká kọ eré oníṣe (playwright.)[1]

Ìbẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n bí Peter Fátómilọ́lá ní ọjọ́ kẹrìndínlógún oṣù kínní ọdún 1946 sí ìjọba ìbílẹ̀ Ìfisàn Èkìtì. Ó jẹ́ ọmọ Olúwo, ní èyí tí a gbàgbọ́ ẃipé ó ṣe okùnfà àwọn ipa rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí babaláwo nínú ọ̀pọ̀ eré orí-ìtàgé ilẹ̀ Naijiria[2]. Ó dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèré Olókun ní 1967 lábẹ́ àkóso ọ̀jọ̀gbọ́n olóògbé Ọlá Rótìmí, gbajú gbajà òǹṣèré orí-ìtàgé (dramatist) àti olùkọ̀tàn àdídùn ní ilé-ẹ̀kọ́ àgbà ti Ilé-Ifẹ̀ tí wọ́n sọ di Ọbáfẹ́mi Awólọ́wò University[3] Bákan náà ni Peter tún jẹ́ ọ̀kan lára àwọn olùkọ́ ní ilé-ẹ̀kọ́ àgbà Ilé-Ifẹ̀ ìyẹn Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ University, níbi tí òun pàá pàá ti kẹ́kọ̀ọ́ gboyè ìmọ̀ Theatre Art ní 1978.[4] Òun náà tún ni ẹni tí ó kọ́kọ́ kópa gẹ́gẹ́ bíi "Papa Ajasco", nínú sinimá àgbéléwò tí ọ̀gbẹ́ni Wálé Adénúgà.[5] ń gbé jáde. Bákan náà ni ó tún ti kópa nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ eré orí-ìtàgé ilẹ̀ Nàìjíríà tó lààmì laaka gẹ́gẹ́ bí Ṣàngó, tí ó jẹ́ ìtàn akọni ìgbà ìwáṣẹ̀ tí Ọbáfẹ́mi Lasode gbé jáde tí Waĺé Ogunyemi sì ṣe àpilẹ̀kọ rẹ̀ ní ọdún 1997[6]

Ìkópa rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  • Sango (Film) (1997)

Àwọn ìtóka sí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "Fatomilola’s first film is ready, but…". The Punch - Nigeria's Most Widely Read Newspaper. Retrieved 20 January 2015. 
  2. BOLDWIN ANUGWARA. "Peter Fatomilola: Versatile, veteran Yoruba actor". Newswatch Times. Retrieved 20 January 2015. 
  3. Our Correspondent. "New Telegraph – Peter FaTomilola: I have always wanted to be a herbalist". newtelegraphonline.com. Retrieved 20 January 2015. 
  4. "Fayemi’s wife lifts Fatomilola’s spirit …donates N200,000 to his film project". The Punch - Nigeria's Most Widely Read Newspaper. Retrieved 20 January 2015. 
  5. "I was the first Papa Ajasco —Peter Fatomilola". tribune.com.ng. Retrieved 20 January 2015. 
  6. "Africultures - Fiche film : Sango". africultures.com. Retrieved 20 January 2015.