Philippe de Champaigne

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Philippe de Champaigne
Philippe de Champaigne, self-portrait.
Museum of Grenoble
Pápá Àwòrán yíyà
Movement Baroque

Philippe de Champaigne (ìpè Faransé: ​[ʃɑ̃paɲ]; Ọjọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n Oṣù karún Ọdún 1602 – Ọjọ́ kejìlá Oṣù kẹjọ Ọdún 1674) jẹ́ ayàwòrán ará Faransé tí a bí sí Brabançon , tí ó jẹ́ olùgbéga ilé ẹ̀kọ́ Faransé. Ó jẹ́ ara àwọn olùdásílẹ̀ Académie de peinture et de sculpture.

Ìgbésíayé àti iṣẹ́ rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ex-Voto de 1662, 1662, Louvre

Wọ́n bíi sí ẹbí òtòṣì kan ní Brussels (Duchy of Brabant, Gúúsù Netherlands), nígbà ayé Archduke Albert àti Isabella, Champaigne jẹ́ akẹ́kọ́ lọ́wọ́ olùyàwòrán tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́  Jacques Fouquières. Ní ọdún 1621 ó kọjá sí Paris, ní ibi tí ó ti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Nicolas Poussin níbi ìṣẹ̀ṣọ́ fún  Palais du Luxembourg lábẹ́ ìtọ́sọ́nà Nicolas Duchesne, tí ó fẹ́ ọmọ rẹ̀ married. Gẹ́gẹ́ biHoubraken ti sọọ́ di mímọ̀, inú bí Duchesne sí Champaigne nítorí wípé ó gbajúmọ̀ jùú lọ ní court, èyí ni ó jẹ́ kí Champaigne padà sí Brussels láti lọ maa gbé pẹ̀lú ẹ̀gbọ́n rẹ̀. Ìgbà tí ó gbọ ìròyìn nípa ikú Duchesne ni ó ṣẹ̀ṣẹ̀ padà lọ fẹ́ ọmọ rẹ̀.[1] Lẹ́yìn ikú  olùdáàbòbò Duchesne, Champaigne ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ìyá olorì, Marie de Medicis, tí o ti wa lára àwọn tí ó ṣe ààfin Luxembourg lẹ́ṣọ́.Ó yà àwọn àwòrán oríṣíríṣí fún Notre Dame Cathedral ní Paris, ní bíi ọdún 1638 sẹ́yìn. Ó tún ya àwọn àwòrán oní bèbí sí orí aṣo. Wọ́n yàn-án ní ayàwòrán àkọ́kọ́ fún olorì tí ó sì gba ẹgbẹ̀rún àti igba pọ́nhùn fún iṣẹ́ rẹ̀. O tún ṣe ẹ̀ṣọ́ fún ilé ìjọsìn Carmelite ti Faubourg Saint-Jacques, tí ó jẹ́ ìkan lara àwọn ilé ìjọsìn tí Iyá Olorì yàn lààyò.

Wọ́n ba ibẹ̀ jẹ́ nígbà àyípadà Faransé ṣùgbọ́n àwọn àwòrán wà tí wọ́n tọ́jú sí àwọn ilé ọnà tí ó wà lára àwọn ẹ̀ṣọ́ àkọ́kọ́ (Èyí tí wọ́n ṣe ní pẹpẹ wà ní Dijon, àjínde  Láśarù wà ní Grenoble tí ìgbàbọ́ ìbálé sì wà ní is  Louvre.

Ó tún ṣiṣẹ́ fún Cardinal Richelieu, tí ó ṣe ẹ̀ṣọ́ Palais Cardinal, tí ó jẹ́ òfúrufú Sorbonne àti àwọn ilé míràn. Champaigne ni oníṣẹ́ ọnà tí wọ́n gbà láàyè loáti ya àwòrán Richelieu tí wọ́n fi sàmì, tí ó ṣe ní ìgbà mọ́kànlá. Ó wà lára àwọn olùdásílẹ̀ Académie de peinture et de sculpture ní ọdún 1648. Nígbà ayé rẹ̀ (láti 1640 síwájú si), ó ṣalábápàdé Jansenism. Lẹ́yìn ìyanu tí ó gbé ọmọ rẹ̀ tí kò lè rìn dìde ní Port-Royal, ó ya àwòrán ẹ̀yẹ yìí Ex-Voto de 1662, tí ó wà ní Louvre, tí wọ́n fi ṣàpèjúwe ọmọ ayàwòrán yìí pẹ̀lú ìyá olọ́lájùlọ  Agnès Arnauld.

Ìṣẹ́ rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ounjẹ alẹ́ olúwa, Museum of Fine Arts of Lyon
Akẹ́wì ará Faransé Vincent Voiture tí wọ́ pè ní Saint Louis

Champaigne ya àwọn àwòrán tó pọ̀, tí ó ní ṣe pẹ̀lú iṣẹ́ ẹ̀sìn. Rubens tọ́ọ sọ́nọ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀, àwọn iṣẹ́ rẹ̀ sí dára. Philippe de Champaigne jẹ́ ayàwòrán tí iṣẹ́ rẹ̀ yàtọ̀, a dúpẹ́ fún àwọn àwọ̀ àrànbarà tí ó maa ń tayọ ní iṣẹ́ rẹ̀.[2]

Ilé àwòrán rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. Philips de Champanje biography in De groote schouburgh der Nederlantsche konstschilders en schilderessen (1718) by Arnold Houbraken, courtesy of the Digital library for Dutch literature
  2. "Getty Artists Philippe de Champaigne". www.getty.edu. Retrieved October 2014.  More than one of |accessdate= and |access-date= specified (help); Check date values in: |access-date= (help)