Jump to content

Pornhub

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Pornhub
Pornhub-logo.svg
RegistrationOptional
Available language(s)English, German, French, Spanish, Italian, Portuguese, Polish, Russian, Japanese, Dutch, Czech, Simplified Chinese
Current statusOnline

Pornhub jẹ́ ìtàkùn orí ẹ̀rọ-ayélujára fún fọ́nrán ìwòkuwò lóríṣiríṣi, èyí tó jẹ́ tí ìlú Canada. Ọkàn lára àwọn ìtàkùn ayélujára náà tó gbajúmọ̀ ni ti eré-ìdárayá àwọn àgbàlagbà, ti Aylo.[1][2] Títí di Oṣù Kejìlá 2023, Pornhub jẹ́ ìtàkùn ayélujára ẹlẹ́ẹ̀kẹrìnlá tí àwọn ènìyàn ń wò jù lọ ní àgbáyé. Òun sì ni ẹlẹ́ẹ̀kejì tí àwọn àgbàlagbà máa ń wò jù lọ, lẹ́yìn XVideos.[3] Ìtakùn yìí gba àwọn àlejò láàyè láti wo fọ́nrán ìwòkuwò lóríṣiríṣi láti oríṣiríṣi ìpele. Ó sì tún gbani láàyè láti fi fọ́nrán tirẹ̀ sí orí ìtakùn náà, níwọ̀n ìgbà tí ó bá ti bá òfin wọn mu.[4] Wọ́n sì tún máa ń ṣe ìgbà àmì-ẹ̀yẹ lọ́dọọdún. Ní oṣù kejìlá, ọdún 2020, lẹ́yìn tí The New York Times tú àṣírí àwọn kan tí wọ́n ń nípìn-ín nínú ìfipábánilò àti ìṣenibáṣubàṣu, àwọn ẹ̀rọ ìsanwó bíi Mastercard àti Visa yọ ọwọ́ wọn kúrò nínú gbogbo nǹkan tó jẹ́ ti Pornhub. Èyí sì mú kí Pornhub yọ àwọn fọ́nrán tí ò bá òfin wọn mu,[5] èyí sì mú kí àwọn fọ́nrán náà díkù láti mílíọ̀nù mẹ́tàlá (13 million) wọ mílíọ̀nù mẹ́rin (4 million).[6] Ètò kan ní ọdún 2023, tí wọ́n pè ní Money Shot: The Pornhub Story, ṣàfihàn ìdojúkọ wọn àti àríwísí àwọn tó ń ṣe àwọn fọ́nrán ìwòkuwò yìí.[7]

Ìtàn[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n ṣe ìdásílẹ̀ Pornhub ní ọjọ́ karùndínlọ́gbọ̀n oṣù karùn-ún, ọdún 2007, láti ọwọ́ Matt Keezer, gẹ́gẹ́ bíi ìtàkùn ayélujára láàrin ilé-iṣẹ́ Interhub.[8] Ní oṣù kẹta ọdún 2010, Fabian Thylmann ra ilé-iṣẹ́ náà gẹ́gẹ́ bíi àfikún sí Manwin conglomerate (tí ó ti wá di Aylo báyìí).[9] Ní ọdún 2013, Thylmann ta ìpín rẹ̀ fún Feras Antoon àti David Tassillo, tó ṣiṣẹ́ títí wọ ọdún 2022, gẹ́gẹ́ bíi CEO àti COO.[10][11]

Látàrí ìgbìyànjú láti ṣe ìdásílẹ̀ fọ́nrán tó pé dáadáa, ilé-iṣẹ́ náà ṣe ìdásílẹ̀ ètò kan tí wọ́n pè ní "Pornhub Select" ní oṣù kẹwàá ọdún 2013.[12] Pornhub tún ṣe ìdásílẹ̀ ètò kan ní ọjọ́ kẹsàn-án oṣù kẹwàá ọdún 2013, tí wọ́n pè ní "PornIQ", èyí tó ń lo ìmọ̀ ẹ̀rọ láti ṣàtòjọ oríṣiríṣi fọ́nrán fún àwọn òǹwòran ní ìbámu pẹ̀lú àwọn fọ́nrán tí wọ́n ti wò sẹ́yìn àti àsìkò tí wọ́n ń wo àwọn fọ́nrán náà.[13][14]

Ní ọdún 2009, ìtàkùn ayélujára ti àwọn fọ́nrán ìwòkuwò mẹ́ta tó tóbi jù lọ, ìyẹn RedTube, YouPorn àti Pornhub ní tó àlejò mílíọ̀nù ọgọ́rùn-ún (100 million).[15]

Ní oṣù kẹfà ọdún 2015, Pornhub ṣe ìkéde pé wọ́n máa ṣàgbéjáde fíìmù àgbéléwò tó dá lórí ìwòkuwò tí wọ́n sì máa pè ní Sexplorations. Èròǹgbà wọn ni láti bẹ̀rẹ̀ ìyafọ́nrán fíìmù náà ní ọdún 2016, tí wọ́n sì máa gbọ́ gbogbo owó tí wọ́n nílò, àmọ́ wọ́n máa tọrọ $3.4 million láti ọwọ́ IndieGogo crowdfunders. Tí wọ́n bá rí owó náà gbà, fíìmù náà máa jáde ní ọdún 2016. [16][17]

Ní ọjọ́ kìíní oṣù kejì ọdún 2016, Pornhub ṣe ìdásílẹ̀ ètò onítẹ́tẹ́ lórí ẹ̀rọ-ayélujára èyí tí Betsoft, Endorphina àti 1x2 gaming jẹ́ onígbọ̀ọ́wọ́ rẹ̀.[18] Ní oṣù kẹwàá ọdún 2017, igbá kejì Ààrẹ, ìyẹn Corey Price ṣe ìkéde pé Pornhub máa lo ìmọ̀-ẹ̀rọ láti ṣàwárí fọ́nrán lórí ẹ̀rọ náà tí ó sì máa fúnni ní ìròyìn nípa fọ́nrán àti àwọn ọ̀ṣèré inú fọ́nrán náà.[19][20]

Ní ọjọ́ kẹtàdínlógún oṣù kẹrin ọdún 2018, ìtàkùn Pornhub bẹ̀rẹ̀ sí ní gba crypto currency gẹ́gẹ́ bíi ọkàn lára àwọn ọ̀nà láti san owó.[21]

Ní oṣù kejìlá ọdún 2020, lẹ́yìn ìròyìn kan ní The New York Times láti ọwọ́ Nicholas Kristof mú kí[22] Mastercard àti Visa yọ Ọwọ́ wọn cut their services to Pornhub. Pornhub then removed all videos by unverified users.[23]

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

 1. "Talk Talk fails to block Pornhub". The Inquirer. 6 December 2011. Archived from the original on 7 January 2012. Retrieved 23 May 2013.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
 2. "World's biggest porn site reveals how major events affect viewing habits". New.com.au. 27 November 2013. Archived from the original on 24 May 2014. Retrieved 22 December 2014.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
 3. "pornhub.com". www.similarweb.com. Archived from the original on 14 April 2020. Retrieved 20 April 2020.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
 4. "Terms Of Service | Pornhub.com". www.pornhub.com. Archived from the original on 8 June 2023. Retrieved 2023-06-07.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
 5. "Pornhub Just Purged All Unverified Content From the Platform". www.vice.com. 14 December 2020. Archived from the original on 14 December 2020. Retrieved 14 December 2020.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
 6. "Pornhub removes millions of videos after investigation finds child abuse content". the Guardian. 14 December 2020. Archived from the original on 28 June 2021. Retrieved 24 June 2021.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
 7. DeVille, Cherie (2023-03-11). "Why I Chose to Appear in Netflix's Controversial Pornhub Documentary" (in en-US). Rolling Stone. https://www.rollingstone.com/tv-movies/tv-movie-reviews/money-shot-the-pornhub-story-netflix-cherie-deville-porn-documentary-sex-trafficking-1234692557/. Retrieved 2023-12-13. 
 8. "The Geek-Kings of Smut". New York. New York Media, LLC. 28 January 2011. Archived from the original on 3 February 2011. Retrieved 22 December 2014.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
 9. Buse, Uwe (20 December 2012). "Harnessing the Internet: The German Porn King's Revolutionary Model". Der Spiegel. http://www.spiegel.de/international/zeitgeist/fabian-thylmann-and-his-revolutionary-porn-business-model-a-873802-2.html. 
 10. Woods, Ben (3 March 2016). "The (almost) invisible men and women behind the world's largest porn sites". The Next Web. Archived from the original on 30 December 2017. Retrieved 21 April 2020.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
 11. Krishna, Rithika; Dasgupta, Shounak (22 June 2022). "Pornhub-owner MindGeek CEO, COO resign". Reuters. Archived from the original on 13 September 2023. Retrieved 13 December 2023.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
 12. "Pornhub Launches a New Feature for Amazing Hand-Picked Curated Porn". Pornhub.com. 1 October 2013. Archived from the original on 15 June 2021. Retrieved 19 February 2021.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
 13. Gray, Lila (9 October 2013). "PornHub to Roll Out Porn IQ". Xbiz. Archived from the original on 19 August 2014. Retrieved 18 August 2014.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
 14. Holmes, David (9 October 2013). "What media companies can learn from Pornhub and its new PornIQ service". PandoDaily. Archived from the original on 18 November 2014. Retrieved 18 August 2014.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
 15. Lanxon, Nate (22 May 2009). "Twitter more popular than free porn: fact! | CNET UK". Crave.cnet.co.uk. Archived from the original on 24 April 2012. Retrieved 23 May 2013.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
 16. First sex in space: Pornhub is going to make a porn film in space Archived 7 May 2019 at the Wayback Machine., independent.co.uk
 17. "Pornhub Space Program – Sexploration". Indiegogo. Retrieved 30 April 2019. 
 18. "Porn + Gambling = PornHub Casino". lcb.org. 6 February 2016. https://lcb.org/news/9753-porn-gambling-pornhub-casino. 
 19. Biggs, John. "PornHub uses computer vision to ID actors, acts in its videos". TechCrunch. https://techcrunch.com/2017/10/11/pornhub-uses-computer-vision-to-id-actors-acts-in-its-videos/. 
 20. Cole, Samantha (11 October 2017). "Facial Recognition for Porn Stars Is a Privacy Nightmare Waiting to Happen". Vice Media. https://motherboard.vice.com/en_us/article/a3kmpb/facial-recognition-for-porn-stars-is-a-privacy-nightmare-waiting-to-happen. 
 21. Liao, Shannon (2018-04-17). "Pornhub starts accepting cryptocurrency". The Verge. Retrieved 2020-12-14. 
 22. Kristof, Nicholas (4 December 2020). "The Children of Pornhub". The New York Times. Archived from the original on 9 June 2021. Retrieved 12 June 2021.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
 23. "Pornhub: Mastercard and Visa to block use of cards on site after child abuse allegations". The Guardian. 10 December 2020. Archived from the original on 15 August 2021. Retrieved 12 June 2021.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)