Jump to content

Priscilla Ekwere Eleje

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Priscilla Ekwere Eleje
ọmọnìyàn
ẹ̀yàabo Àtúnṣe
orúkọ àfúnniPriscilla Àtúnṣe

Priscilla Ekwere Eleje jẹ́ obìnrin àkọ́kọ́ tí ó jẹ olùdarí iṣẹ́ tó ní ṣe pẹ̀lú owó tí à ń ná ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ní Central Bank of Nigeria (CBN). Òun sì ni obìnrin àkọ́kọ́ tí ìbuwọ́lù rẹ̀ hàn lórí owó tí à ń ná ní orílẹ̀-èdè náà.[1][2]

Ìgbésí ayé àti ètò-èkó rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Eleje jẹ́ ọmọ ìlú Afikpo ní ìpínlẹ̀ Ebonyi. Ó gba degree nínú Psychology ní University of Jos, ní ìpínlẹ̀ Plateau. Ó tún lọ sí Hubert H. Humphrey Fellowship in Banking and Management ní Boston University, Massachusetts, USA. Bákan náà, ó jẹ́ Certified Information System Auditor (CISA).[3]

Iṣẹ́ rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

A yan Eleje bíi substantive Director of Currency Operations of the Nigerian apex bank, CBN, ní oṣù kẹjọ ọdún 2018. Síwájú ìgbà tí a yàn-án fún ipò yìí, ó jẹ́ adelé ipò náà. Ọ̀wọ́ kìíní àwọn owó tí ó ní ìbuwọ́lù rẹ̀ nínú ni ẹgbẹ̀rún kan náírà tí ó yíká ní ọdún 2019.[4]. Yíyàn tí a yàn-án mú oríyìn wà látọ̀de àjọ lóríṣiríṣì tó ní ṣe pẹ̀lú obìnrin, pàápàá jù lọ The National Council of Women Societies (NCWS), ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.[5]

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "10 Quick Facts About Priscilla Ekwere Eleje". 16 April 2019. 
  2. Odunsi, Wale (22 April 2019). "Priscilla Ekwere Eleje: Nigerian women react to appointment of first female CBN Director of Currency - Daily Post Nigeria" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2019-05-12. 
  3. Famuyiwa, Damilare (2019-04-18). "8 things you don't know about CBN's Priscilla Ekwere Eleje". Nairametrics (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2019-05-12. 
  4. "P.M. News - Nigeria News, latest world news and breaking news". 
  5. Odunsi, Wale (22 April 2019). "Priscilla Ekwere Eleje: Nigerian women react to appointment of first female CBN Director of Currency - Daily Post Nigeria" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2019-05-12.