Queen Amina Statue

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Queen Amina Statue jẹ́ ère ajẹmésìn ti ́ wọ́n ṣe ní ìrántí Queen Amina, tí ó jẹ́ ajagun ilẹ̀ Hausa, àti ọba-bìnrin ilẹ̀ Zazzau.[1] Ben Ekanem ni ó kọ́ ṣe àwòrán ère náà ní ọdún 1975, nígba ayẹyẹ kejì ti àwọn aláwọ̀ dúdú tó jẹmáṣà àti iṣẹ́-ọnà lágbàáyé, wọ́n sì fi sí ẹnu-ọ̀nà àbáwọlé National Arts Theatre ní ìpínlẹ̀ Èkó. [2] Ère náà dà wó ní ọdún 2005, àmọ́, wọ́n tún un kọ́ ní ọdún 2014.[3]

Ìpìlẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Queen Amina jẹ́ ọmọ àkọ́kọ́ Queen Bakwa Turunku, tí ó jẹ́ olùdásílẹ̀ ìjọba Zazzau. Ó jé akínkanjú ajagun àti ọba-bìnrin ilẹ̀ Zazzau, tí ó jọba ní séńtúrì kẹrìndínlógún.[4] Wọ́n ṣe ère Queen Amina láti máa fi ṣe ìrántí ìwà akínkanjú rẹ̀ àti ipa ribiribi tí ókó.[5]

Àpèjúwe[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ère Queen Amina Statue jẹ́ èyí tí a fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ idẹ àti kọnkéré ṣe. Ó ṣe àfihàn Qeen Amina lórí ẹṣin pèlú idà lọ́wọ́.[6]

Àwọn ìtọ́ka sí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. Catherine Coquery-Vidrovitch (1997). Africaines. WestviewPress. ISBN 978-0-8133-2360-2. https://books.google.com/books?id=m_stAAAAYAAJ. 
  2. Drum. African Drum Publications. 1979. https://books.google.com/books?id=74E6AQAAIAAJ. 
  3. Ozolua Uhakheme; Moyosore Adeniji (3 September 2008). "Honour for heroes". The Nation. http://www.thenationonlineng.net/archive2/tblnews_Detail.php?id=61260. 
  4. Wale Ogunyẹmi (1999). Queen Amina of Zazzau. University Press PLC. ISBN 978-978-030-567-3. https://books.google.com/books?id=o3AgAQAAIAAJ. 
  5. Africa Woman. Africa Journal Limited. 1981. https://books.google.com/books?id=qVe3AAAAIAAJ. 
  6. Ginette Curry (1 January 2004). Awakening African Women: The Dynamics of Change. Cambridge Scholars Press. pp. 13–. ISBN 978-1-904303-34-3. https://books.google.com/books?id=07RsgNhi8l4C&pg=PA13. 

Àdàkọ:Coord missing