Jump to content

Radio Lagos

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
(Àtúnjúwe láti Radio Eko)
Radio Lagos
CityÈkó
Broadcast areaÌpínlẹ̀ Èkó
Frequency107.5 MHz FM
Language(s)Èdè ìbílẹ̀ abínibí ati èdè Gẹ̀ẹ́sì
Transmitter coordinates6°37′10.767″N 3°21′12.719″E / 6.61965750°N 3.35353306°E / 6.61965750; 3.35353306Coordinates: 6°37′10.767″N 3°21′12.719″E / 6.61965750°N 3.35353306°E / 6.61965750; 3.35353306
OwnerLagos State Radio Corporation

Radio Lagos 107.5 FM tí a tún Mo sí (Tiwa n' Tiwa) ni ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní pẹrẹu ní ọdún 1977 ni ó jẹ́ ẹ̀ka ti Nigerian Broadcasting Corporation. Ilé-iṣẹ́ asọ̀rọ̀mágbèsì yí jẹ́ ilé-iṣẹ́ ìròyìn àkọ́kọ́ tí yóò jẹ́ ti Ìpínlẹ̀ lórí ìkanì FM.

Ilé-iṣẹ́ asọ̀rọ̀mágbésì yí ń gbòhùn sáfẹ́fẹ́ lórí ìkànì A.M méjì (990 kHz.303mtrs àti 918 kHz.327mtrs) tẹ́lẹ̀. Látàrí ìṣèwádí ọ̀nà ọ̀tun láti lè ma kàn sí ọ̀gọ̀rọ̀ ènìyàn ni ó bí ojú-òpó Radio Lagos tí ó wà ní orí ìkànì 107.5 FM (Tiwa n'Tiwa) lábẹ́ àṣẹ àti ìdarí ilé-iṣẹ́ Lagos State Radio Service ní ọdún 2001.

Ilé-iṣẹ́ asọ̀rọ̀mágbèsì Radio Lagos ni ó kọ́kọ́ jẹ́ ilé-iṣẹ́ agbóhùn-sáfẹ́fẹ́ tí ó ń lo èdè Yorùbá àti èdè Ègùn láti fi gbóhùn -sáfẹ́fẹ́ tí wọ́n sì ń lo ìdá méjì péré nínú ìdá ọgórùn ún èdè Gẹ̀ẹ́sì láti fi sọ ìròyìn. Àwọn tí ilé-iṣẹ́ rédíò yí fi sọ́kàn jùlọ láti jẹ́ olùgbọ́ wọn ni àwọn ọmọ Yorùbá nílé àti kókó. [1]

Àwọn itọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. Haris Aslam (20 November 2014). "Radio Lagos 107.5 Online". RadioAfrican. Archived from the original on 1 October 2020. Retrieved 13 March 2021. 

Àdàkọ:Lagos


Àdàkọ:Africa-radio-station-stub Àdàkọ:Lagos-stub