Jump to content

Rafiatou Karimou

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Rafiatou Karimou

Rafiatou Karimou (2 May 1946 – 4 January 2018)[1] jẹ́ òṣèlú àti olùkọ́ ọmọ orílẹ̀ ède Benin. Karimou ni obìnrin àkọ́kọ́ láti di mínísítà ní orílẹ̀ ède Benin.[2][3][4]

A bí Rafiatou Karimou ní ọdún 1946 ní Sakété, ní gúúsù ibi tí a mọ̀ sí Benin lóde òní. Ní ọdún 1975, òun ni obìnrin àkọ́kọ́ tí a yàn gẹ́gẹ́ bi olóyè àgbègbè àti ní ọdún 1989, ó di obìrin àkọ́kọ́ láti di mínísítà ni orílẹ̀ ède Benin nígbà tí àárẹ̀ orílẹ̀ èdè náà, Mathieu Kérékou yàn án sípò mínísítà fún ètò ìlera àdúgbò.[4]

Ó di ipò yìí mú di ọdún 1990. A tún yàn án láti láti dípò mínísítà fún ètò ẹ̀kọ́ Prámárì àti Sẹ́kọ́ndírì, ó sì di ipò náà mú láti ọdún 2003 títí di 2006.[5][6]

Àwọn ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. "Décès de Karim Rafiatou hier à Paris La première femme ministre du Bénin n'est plus". Retrieved 1 May 2018. 
  2. "Le FED de Karimou Rafiatou se prononce: Actualité politique au Bénin | Jolome News - La pluralité de l'information". bj.jolome.com (in Èdè Faransé). Retrieved 2017-11-07. 
  3. rédaction, La. "La nouvelle carte politique de Sakété" (in fr-FR). La Nouvelle Tribune. Archived from the original on 2019-05-24. https://web.archive.org/web/20190524045637/https://lanouvelletribune.info/archives/benin/politique/5785-la-nouvelle-carte-politique-de-sakete. 
  4. 4.0 4.1 Attanasso, Marie-Odile (2013) (in fr). Femmes et pouvoir politique au Benin des origines dahoméennes a nos jours. Friedrich-Ebert-Stiftung. ISBN 9789991914114. https://books.google.com/books?id=1bf0oAEACAAJ&q=9789991914114. 
  5. Houngnikpo, Mathurin C.; Decalo, Samuel (2013) (in en). Historical Dictionary of Benin. Rowman & Littlefield. ISBN 9780810871717. https://books.google.com/books?id=0yGPTsRubWEC. 
  6. Marie-Odile, Attanasso C. (2012) (in fr). Femmes et pouvoir politique au Bénin : Des origines dahoméennes à nos jours. Fondation Friedrich Ebert. http://library.fes.de/pdf-files/bueros/benin/10194.pdf.