Rafiq Ahmad Pampori

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Rafiq Ahmad Pampori
Rector of Darul Uloom Ilahiya, Srinagar
Lọ́wọ́lọ́wọ́
Ó gun orí àga
1992
Asíwájú"post established"
Principal of Government Medical College, Srinagar
In office
1 October 2012 – 19 December 2015
AsíwájúQazi Masood
Arọ́pòKaisar Ahmad
Àdàkọ:Infobox religious biography

Rafiq Ahmad Pampori (born 13 February 1956) jẹ́ onímọ̀ Mùsùlùmí ti orílẹ̀-èdè India, onímọ̀ àti òǹkọ̀wé, tó ṣe ìdásílẹ̀ Darul Uloom Ilahiya, tó jẹ́ ilé-ìwé Islam ní ìlú Srinagar.

Ahmad kẹ́kọ̀ọ́ gboyè ní Sri Pratap College àti Government Medical College, Srinagar. Òun ni rector Darul Uloom Ilahiya, ní Srinagar àti olùdarí Illahiya Dialysis ní Soura. Ó fígbá kan jẹ́ ọ̀gá ilé-ìwé Government Medical College. Ó ti kọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwé bíi: Aijazul Qur'ān àti Ra'fatul Baari, ìwé alápá márùn-ún Sahih Bukhari.

Ìgbésí ayé rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n bí Rafiq Ahmad Pampori ní ọjọ́ 13 oṣù February, ọdún 1956 ní Safa Kadal, Srinagar. Ó lọ sí ilé-ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ti Karan Nagar, ó sì parí ẹ̀kọ́ girama ní Sri Pratap College, ní ọdún 1974.[1] Ó kẹ́ẹ̀kọ́ nípa ìṣègùn, ní Government Medical College, Srinagar, níbi tí ó ti gboyè Bachelor of Medicine and Surgery (MBBS) ní ọdún 1979, ó sì tún tẹ̀síwájú láti gboye Master of Surgery nínú ẹ̀kọ́ Otorhinolaryngology (ENT) láti ilé-ẹ̀kọ́ gíga náà, ní ọdún 1983.[2] Ó ṣe Neurotology fellowship ní All India Institute of Medical Sciences ní New Delhi.[1] Ó gba àǹfààní Muhammad Masihullah Khan nínú Sufism.[3]

Ní ọdún 1983, wọ́n yan Ahmad sípò alákòóso ìforúkọsílẹ̀ ti Government Medical College, ní Srinagar.[4] Ní ọdún 1990, wọ́n yàn án sípò olùkọ́ lábé ẹ̀ka ENT tí ilé-ẹ̀kọ́ náà, tí ó sì padà di olórí àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n.[4] Wọ́n yàn án sípò olùdarí ilé-ìwé náà, ní 1 oṣù October, ọdún 2012.[5][6] Ó gba ìsinmi lẹ́nu iṣẹ́ ní oṣù December, ọdún 2015, tó sì bèrè fún ìfẹ̀hìntì, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọjọ́ 1 oṣù February, ọdún 2018 ló yẹ kí ó fẹ̀yìntì.[4][7] Wọ́n fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé Lal Singh Chaudhary, tó jẹ́ olóṣèlú BJP kàn án nípá láti fẹ̀hìntí láìtọ́jọ́.[8]

Ahmad ṣe àyọkúrò ẹ̀bẹ̀ rẹ̀ fún ètò ìfẹ̀hìntì rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Mufti Mohammad Sayeed ṣe béèrè fun.[9] Àmọ́, Lal Singh ti yan Kaiser Ahmad gẹ́gẹ́ bí i olùdarí ilé-ìwé náà, ní ọjọ́ 19 oṣù December, ọdún 2015, tó kọ̀ láti fi ipò náà sílẹ̀.[10][11] Wọ́n ri bí i "ìfìgagbágba àti ogun láàrin PDP v/s BJP" láti ọwọ́ Omar Abdullah.[10]

Àwọn iṣẹ́ àtẹ̀jáde rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ahmad ti kọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwé bíi: Aijazul Qur'ān, Instrument For Understanding Qur'ān, Ra'fatul Baari (a five-volume commentary on Sahih Bukhari) àti The Need for Divine Guidance.[2] Àwọn iṣẹ́ àtẹ̀jáde rẹ̀ mìíràn ni:

  • Chronic Suppurative Otitis Media, 10th chapter in Textbook of Ear, Nose and Throat Diseases by Mohammad Maqbool and Suhail Maqbool.[12]
  • Primary tumor of the facial nerve: Diagnosis and management.[13]
  • Transcervical foreign body.[14]

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. 1.0 1.1 MANZOOR-UL-HASSSAN (14 March 2015). "Dr Rafiq Pampori is new GMC Principal". Greater Kashmir. https://www.greaterkashmir.com/more/dr-rafiq-pampori-is-new-gmc-principal. 
  2. 2.0 2.1 Khan & Ansar 2018, p. 78.
  3. Trāli & al-Azam 2015, pp. 428–432.
  4. 4.0 4.1 4.2 MANZOOR-UL-HASSSAN (14 March 2015). "Dr Rafiq Pampori is new GMC Principal". Greater Kashmir. https://www.greaterkashmir.com/more/dr-rafiq-pampori-is-new-gmc-principal. 
  5. "Transfers and postings in J&K administration". Scoop News. http://scoopnews.in/det.aspx?q=33751. 
  6. Sheikh Junaid (19 December 2015). "Health minister 'pushed' Kashmir medical college principal to resign". Kashmir Dispatch. Archived from the original on 9 July 2021. https://web.archive.org/web/20210709185300/https://kashmirdispatch.com/2015/12/19/health-minister-pushed-kashmir-medical-college-principal-to-resign/2644/. 
  7. "HC issues notice to C/S Health". Daily Excelsior. 5 February 2016. https://www.dailyexcelsior.com/hc-issues-notice-to-cs-health/. 
  8. VIVEK SHARMA (22 December 2015). "On CM's request, Dr Pampori withdraws retirement plea; joins". State Times. https://news.statetimes.in/132787-2/. 
  9. VIVEK SHARMA (22 December 2015). "On CM's request, Dr Pampori withdraws retirement plea; joins". State Times. https://news.statetimes.in/132787-2/. 
  10. 10.0 10.1 "PDP-BJP coalition making mockery of governance: Omar Abdullah". India Times. 23 December 2015. https://economictimes.indiatimes.com/news/politics-and-nation/pdp-bjp-coalition-making-mockery-of-governance-omar-abdullah/articleshow/50297530.cms?from=mdr. 
  11. "Dr Javed Chowdhary vs State Of J&K; And Others on 27 October, 2017". indiankanoon.org. Archived from the original on 9 July 2021. Retrieved 4 July 2021.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  12. Maqbool, Mohammad; Maqbool, Suhail (31 August 2013). Textbook of Ear, Nose and Throat Diseases. ISBN 9789350904954. https://books.google.com/books?id=oTgIAQAAQBAJ&q=Rafiq+Ahmad+Pampori&pg=PR15. Retrieved 4 July 2021. 
  13. Pampori, Rafiq Ahmad; Ahmad, Asif; Ahmad, Manzoor (January 2002). "Primary tumor of the facial nerve: Diagnosis and management". Indian Journal of Otolaryngology and Head and Neck Surgery 54 (1): 54–56. doi:10.1007/BF02911009. PMC 3450701. PMID 23119855. //www.pubmedcentral.nih.gov/articlerender.fcgi?tool=pmcentrez&artid=3450701. 
  14. Ahmad, Rauf; Pampori, Rafiq Ahmad; Wani, Asef Ahmad; Qazi, Sajjad Majid; Ahad, Sheikh Abdul (2000). "Transcervical foreign body". The Journal of Laryngology & Otology 114 (6): 471–472. doi:10.1258/0022215001905896. PMID 10962687. https://www.cambridge.org/core/journals/journal-of-laryngology-and-otology/article/abs/transcervical-foreign-body/9F4DB8C6FABD2A17ACB9EB6341F2C5DF. 

Bibliography[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ìjápọ̀ ìtagbangba[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]