Jump to content

Regina Askia-Williams

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Regina Askia
Regina Askia-Williams
Ọjọ́ìbíImaobong Regina Askia Usoro
Ọmọ orílẹ̀-èdèNàìjíríà
Iṣẹ́òṣèré àti afẹwàṣiṣẹ́

Regina Askia-Williams (tí àbísọ rẹ̀ n ṣe Imaobong Regina Askia Usoro) jẹ́ ọmọ bíbí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí ó n gbé ní Amẹ́ríkà. Ó jẹ́ òṣìṣẹ́ ìlera, ajìjàgbara fún ètò-ẹ̀kọ́, ònkọ̀tàn, àti sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ tí ó di ìlúmọ̀ọ́ká gẹ́gẹ́ bi òṣèré àti afẹwàṣiṣẹ́.[1][2][3]

Iṣẹ́ ìṣe rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ní ọdún 1988, wọ́n dé Askia-Williams ládé Miss Unilag, gẹ́gẹ́ bi ọmọbìnrin tí ó rẹwà jùlọ ní ilẹ́-ẹ̀kọ́ gíga Yunifásítì ìlú Èkó. Ní ọdún 1988 kan náà, ó díje nínu ìdíje ẹwà MBGN tí ó sì ṣe ipò kejì. Ní ọdún 1990, Askia-Williams tún ṣojú orílẹ̀-èdè Nàìjíríà níbi ìdíje ẹwà Miss Charm International tí ó wáyé ní ìlúLeningrad, orílẹ̀-èdè Rọ́síà tó sì tún ṣe ipò kejì.[4] Òun ni ẹni àkọ́kọ́ tí yóó ṣojú orílẹ̀-èdè Nàìjíríà níbi ìdíje Miss International, èyí tí ó wáyé ní orílẹ̀-èdè Japan

Lẹ́hìn tí ó di gbajúmọ̀ ní Nàìjíríà gẹ́gẹ́ bi olùdíje ẹwà, Askia-Williams bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣe iṣẹ́ afẹwàṣiṣẹ́. Gẹ́gẹ́ bi afẹwàṣiṣẹ́, ó ti ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìpolówó ọjà lóri tẹlifíṣọ̀nù àti ìwé-ìròyìn fún àwọn ilé-iṣé àti ilé-ìtajà bíi Kessingsheen, Collectibles àti Visine. Ní ọdún 2007 òun àti ọmọ rẹ̀ Stephanie Hornecker dìjọ ṣe ìpolówó fún ilé-iṣẹ́ 2000-N-Six.[5] Ní ọdún 2005 ó ṣètò ìfihàn kan ní ìlú New York, léte láti la àwọn ènìyàn lọ́yẹ̀ nípa àwọn ìṣòro tí ó dojú kọ àwọn ohun-èlò amáyédẹrùn ní Nàìjíríà. Ní ọdún 2006 bákan náà, ó tún ṣe ìfihàn míràn ní agbègbè Lehman College, ìlú New York láti ṣàfihàn iṣé àwọn aṣàpẹẹrẹ ilẹ̀ Áfríkà àti ti ilé-iṣẹ́ tirẹ̀ náà tí ó pè ní Regine Fashions.[6]

Askia-Williams kópa nínu eré tẹlifíṣọ̀nù tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Fortunes ní ọdún 1993 gẹ́gẹ́ bi Tokunbo Johnson. Eré náà ṣokùn fa ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ipa tí ó padà kó nínu àwọn fíìmù Nollywood . Ó ti gba ọríṣiríṣi àwọn àmì-ẹ̀yẹ fún àwọn iṣẹ́ takuntakun rẹ̀ tó fi mọ́ àmì-ẹ̀yẹ ti Afro Hollywood London ní ọdún 2000, gẹ́gẹ́ bi òṣèrébìnrin tí ó dára jùlọ ní Nàìjíríà.

Àṣàyàn àwọn eré rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Askia-Williams ti kópa nínu àwọn fíìmù wọ̀nyí.[7]

 • Slave Warrior: The Beginning (video) (2007)
 • Veno (video) (2004)
 • Dangerous Babe (2003)
 • Man Snatcher (video) (2003)
 • Festival of Fire (2002)
 • Vuga (video) (2000)
 • Vuga 2 (video) (2000)
 • The President's Daughter (2000)
 • Dirty Game (video) (1998)
 • Full Moon (1998)
 • Suicide Mission (1998)
 • Highway to the Grave (1997)
 • Juliet Must Die
 • Maximum Risk
 • Mena
 • Queen of the Night
 • Red Machete
 • Most Wanted

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

 1. "African Health Dialogues". African Views. Archived from the original on 30 December 2012. Retrieved 29 May 2012. 
 2. Segun-oduntan, Olumide (6 May 2012). "Regina Askia's life as a nurse". National Mirror (Nigeria). Archived from the original on 27 September 2013. https://web.archive.org/web/20130927221203/http://nationalmirroronline.net/index.php/features/39086.html. Retrieved 6 June 2013. 
 3. Ajiboye, Segun (30 July 2016). "Why I abandoned acting to become a nurse -Ex-beauty queen Regina Askia-Williams". The Nation. Retrieved 25 February 2018. 
 4. Miss Charm International Archived 16 July 2011 at the Wayback Machine.Àdàkọ:Unreliable source?
 5. 2000-N-Six Archived 10 October 2007 at the Wayback Machine.
 6. "Regine 2006 fashion Show in New York City to benefit children in Africa". African Events. Archived from Regine Fashions the original Check |url= value (help) on 20 March 2013. Retrieved 25 February 2018.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
 7. "Regina Askia". nigerian-movies.net. Archived from the original on 19 December 2010. Retrieved 29 May 2012.