Robert Adéyínká Adébáyọ̀
Robert Adeyinka Adebayo (tí a bí ní Ọjọ́ Kẹ̀sán-án oṣù kẹta ọdún 1928 tí ó sì fáyé lẹ̀ ní ọjọ́ kẹjọ oṣù Kẹta ọdún 2017) jẹ́ ọ̀gágun àti Gómìnà ètò ìṣèjọba-àná ní ìwọ-oòrùn, ilẹ̀ Yorùbá, lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà láti ọdún 1966 sí 1971. Òun náà ní Adarí àwọn òṣìṣẹ́ ológun àti ọ̀gá àgbà ilé ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ àwọn ológun (the Nigerian Defence Academy). [1] [2]
Ìgbésí-ayé rẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Adéyínká Adébáyọ̀ tí a bí lọ́dún 1928 jẹ́ ọmọ òṣìṣẹ́ ìjọba ní Ìpínlẹ̀ Èkìtì lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ó bẹ̀rẹ̀ ìwé kíkà rẹ̀ ní All Saints School, Iyin-Ekiti, ó tẹ̀síwájú nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní Eko Boys High School àti Christ's School Ado Ekiti. Ó dára pọ̀ mọ́ ilé-ìwé àwọn ológun, the West African Frontier Force lọ́dún 1948, níbi tí ó ti gboyè ológun kí ó tó tẹ̀síwájú nínu ẹ̀kọ́ láti gboyè ológun síi ní ìlú Teshie lorílè-èdè Ghana lọ́dún 1950 sí 1952. Lẹ́yìn tí ó pegedé tí ó sì kàwé gboyè ológun (War Office Examination for Commonwealth cadets) lọ́dún, ó tún tẹ̀síwájú láti ríi pé òun kàwé pegedé nínú ìdánwò 1952 as well as ilé ìwé gíga (the West African) lọ́dún 1953 wọ́n fún un ní oyè ológun nílé ẹ̀kọ́ ológun ti the Royal West African Frontier Force) gẹ́gẹ́ bí ọmọ ìwọ oòrùn Afíríkà ẹlẹ́ẹ̀kẹ̀tàlélógún tó kàwé gboyè ológun (West African military officer), òun sì ni ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà keje tí ó kàwé gboyè ológun bẹ́ẹ̀ lẹ́yìn ìtẹ̀síwájú ẹ̀kọ́ ológun rẹ̀ ní Eaton Hall lórílẹ̀ èdè Gẹ̀ẹ́sì. Ó tún kàwé gboyè ní Staff College Camberley (Surrey) lọ́dún 1960, àti ní ilé ìwé ológun tí Imperial Defence College, ní ìlú Gẹ̀ẹ́sì bákan náà lọ́dún 1965.[3] [4]
Adéyínká Adébáyọ̀ gẹ́gẹ́ bí Gómìnà
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Adéyínká Adébáyọ̀ di ọ̀gágun lọ́dún 1953. Àwọn ìjọba ológun fi í jẹ Gómìnà apá ìwọ-oòrùn lọ́dún 1966 sì 1971. Nígbà tí ó jẹ Gómìnà, ó dá ilé ẹ̀kọ́ gíga tí ìṣèwáàdí àti ẹ̀kọ́ lórí iṣẹ́ àgbè sí ìlú Ìbàdàn. Òun ni ìṣèjọba rẹ̀ ṣokùnfà Ogun Àgbẹ̀kọ̀yà lọ́dún 1968 sí 1969. [5] [6]
Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "Ex-Governor of Western Nigeria, Adeyinka Adebayo, is dead". Premium Times Nigeria. 2017-03-08. Retrieved 2019-11-21.
- ↑ Books, Better World (2010-06-22). "People from ekiti state". Better World Books. Retrieved 2019-11-21.
- ↑ {{cite web | title=Adebayo, R. A. (Robert Adeyinka) [WorldCat Identities] | website=WorldCat.org | url=http://worldcat.org/identities/lccn-n88663180/ | access-date=2019-11-21}
- ↑ Ph.D, Jadesola Babatola (2015-08-03). FUNERAL ORATION IN HONOUR of MAJOR GENERAL (RTD.) ROBERT ADEYINKA ADEBAYO. https://www.academia.edu/33159516. Retrieved 2019-11-21.
- ↑ Onward soldier marches on : a biography of Major-General Robert Adeyinka Adebayo (Book, 1998) [WorldCat.org]. 1999-02-22. OCLC 42000983.
- ↑ "Major-General Adeyinka Adebayo". The Times. 2017-04-18. https://www.thetimes.co.uk/article/major-general-adeyinka-adebayo-qds5hf6mp.