Sòbìà

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Sòbìà
SòbìàLílo igi ìṣaná láti yọ sòbìà kúrò lẹ́sẹ̀ ènìyàn
SòbìàLílo igi ìṣaná láti yọ sòbìà kúrò lẹ́sẹ̀ ènìyàn
Lílo igi ìṣaná láti yọ sòbìà kúrò lẹ́sẹ̀ ènìyàn
Ìpínsọ́wọ̀ àti àwọn òkunfà ìta
ICD/CIM-10B72. B72.
ICD/CIM-9125.7 125.7
DiseasesDB3945

Sòbìà, tí a tún mọ̀sí ààrùn sòbìà (GWD), jẹ́ àkóràn ti àràn sòbìà.[1] Ènìyàn maa ń ṣàkóràn rẹ̀ bí ó bá mu omi tí ó ní eṣinṣin omi àkóràn aràn sòbìà ọmọ kòkòrò.[1] Lákọkọ́ kòsí àwọn aamì.[2] Lẹ́hìn ọdun kan, ènìyàn yóòní ìgbóná ara nígbà tí òbí aràn bá fa ọgbẹ́ sí àwọ̀, pàápàá lábẹ́ ẹsẹ̀.[1] Aràn yó̀o jáde lára lẹ́hìn oṣù mélòó.[3] Ní àkókò yíì, ó lè nira láti rìn tàbí ṣiṣẹ́.[2] Kò wọ́pọ̀ kí àrùn yí ó mú ikú dání.[1]

Àwọn ènìyàn nìkan ni irúfẹ́ ẹranko tí àràn sòbìà ń mú.[2] Àràn yíì a fẹ̀ ní ìwọ̀n mìlímítà méjì àwọn tí ó ti dàgbà nínu wọn a maa gùn tó 60 sí 100 sẹ̀ntìmítà(àwọn akọ ló kúrú jù).[1][2] Láìsí lára àwọn ènìyàn, àwọn ẹyin lè pẹ́ tó oṣụ̀ mẹ́ta.[4] Lámilámi gbọ́dọ̀ jẹ wọ́n ṣáájú èyí .[1] Ọmọ inú lámilámi lè wà láyé fún bí oṣù mẹ́rin.[4] Èyí nipé àrùn yíì gbọ́dọ̀ wáyé lọ́dọ́ọdún lára àwọn ènìyàn láti wá ní agbegbè.[5] Ìmọ àrùn yíì lè wáyé nìkan nípa àwọn àpẹẹrẹ àti ààmì.[6]

Ìdẹ́kun lè wáyé bí a bá tètè ṣàwarí àrùn àti àìgba ẹni náà láyè láti kó egbò wọ inú omi mímu.[1] Àwọn ipa mìíràn ni: ìráàyè sí omi tómọ́ gaara àti sísẹ́ omi bí kò bámọ́́.[1] Síṣẹ́ nípa lílo aṣọ náà to.[3] Omi tí ó ti ní àbàwọ́n ni a lè tọ́jú nípa lílo kẹ́míkà tí a ńpè ní temefos láti pa ọmọ kòkòrò.[1] Kòsí egbògi tàbí òògùn ìtọjú tí o ṣiṣẹ́ lòdì sí àrùn náà.[1] A lè yọ àràn náà kúrò díẹ̀díẹ̀ láárin ọ̀sẹ̀ díẹ̀ nípa yíyí lóri igi.[2] Ọgbẹ́ ti àràn tí o ń jáde yi ńfa ni o lè ní kòkòrò àkóràn.[2] Ìrora lè tẹ̀siwajú fún àwọn oṣù díẹ̀ lẹ́hìn tí a yọ aràn kúrò.[2]

Ní 2013 ìṣẹlẹ̀ 148 àrùn náà ni a jábọ̀ rẹ̀.[1] Èyí wálẹ̀ sí 3.5 mílíọ́nù ìṣẹlẹ̀ ní 1986.[2] Orílẹ̀ èdè mẹ́rin péré ni ó wà ní Áfíríkà, èyí tí ó wálẹ̀ láti orílẹ̀ èdè 20 ní àwọn ọdún 1980.[1] Orílẹ̀ èdè tí ó ní jù ni Gúúsù Sudan.[1] Ó jọ bí àkọkọ́ kòkòrò àkóràn àrùn láti yọkúrò.[7] Àrùn sòbìà tì wà láti ìgbà àtijọ́.[2] A sọ nípa rẹ̀ nínu ègbògi Íjíbítì Ebers Papyrus, láti 1550 BC.[8] Orúkọ tí a ń pè ní dracunculiasis jẹyọ láti Látínì "Ìdojúkọ pẹ̀lú lámilámi kékeré",[9] nígbà tí orúkọ "sòbìà" jẹyọ nígbà tí àwọn òyìnbó rí àrùn náà ní Guinea etí òkun Ìwọ̀ oorùn Áfíríkà ní 17th ọgọ́rùn ọdún.[8] Irúfẹ́ ọ̀wọ́ tí àwọn sòbìà ńfa àrùn lára àwọn ẹranko.[10] Èyí kò jọ pé o ń ran ènìyàn.[10] A pin sí ìpele àrùn ipa ọ̀nà orùn tí a gbàgbé.[11]

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. 1.00 1.01 1.02 1.03 1.04 1.05 1.06 1.07 1.08 1.09 1.10 1.11 1.12 "Dracunculiasis (guinea-worm disease) Fact sheet N°359 (Revised)". World Health Organization. March 2014. Retrieved 18 March 2014. 
  2. 2.0 2.1 2.2 2.3 2.4 2.5 2.6 2.7 2.8 Greenaway, C (Feb 17, 2004). "Dracunculiasis (guinea worm disease).". CMAJ : Canadian Medical Association journal = journal de l'Associationmedicalecanadienne 170 (4): 495–500. PMC 332717. PMID 14970098. //www.pubmedcentral.nih.gov/articlerender.fcgi?tool=pmcentrez&artid=332717. 
  3. 3.0 3.1 Cairncross, S; Tayeh, A; Korkor, AS (Jun 2012). "Why is dracunculiasis eradication taking so long?". Trends in parasitology 28 (6): 225–30. doi:10.1016/j.pt.2012.03.003. PMID 22520367. 
  4. 4.0 4.1 Junghanss, Jeremy Farrar, Peter J. Hotez, Thomas (2013). Manson's tropical diseases. (23rd edition ed.). Oxford: Elsevier/Saunders. p. e62. ISBN 9780702053061. http://books.google.ca/books?id=GTjRAQAAQBAJ&pg=RA1-PA62. 
  5. "Parasites - Dracunculiasis (also known as Guinea Worm Disease) Eradication Program". CDC. November 22, 2013. Retrieved 19 March 2014. 
  6. Cook, Gordon (2009). Manson's tropical diseases. (22nd ed. ed.). [Edinburgh]: Saunders. p. 1506. ISBN 9781416044703. http://books.google.ca/books?id=CF2INI0O6l0C&pg=PA1506. 
  7. "Guinea Worm Eradication Program". The Carter Center. Carter Center. Archived from the original on 2015-03-11. Retrieved 2011-03-01. 
  8. 8.0 8.1 Tropical Medicine Central Resource. "Dracunculiasis". Uniformed Services University of the Health Sciences. Archived from the original on 2015-06-14. Retrieved 2008-07-15. 
  9. Barry M (June 2007). "The tail end of guinea worm — global eradication without a drug or a vaccine". N. Engl. J. Med. 356 (25): 2561–4. doi:10.1056/NEJMp078089. PMID 17582064. Archived from the original on 2010-07-06. https://web.archive.org/web/20100706035742/http://content.nejm.org/cgi/content/full/356/25/2561. Retrieved 2015-09-02. 
  10. 10.0 10.1 Junghanss, Jeremy Farrar, Peter J. Hotez, Thomas (2013). Manson's tropical diseases. (23rd edition ed.). Oxford: Elsevier/Saunders. p. 763. ISBN 9780702053061. http://books.google.ca/books?id=GTjRAQAAQBAJ&pg=PA763. 
  11. "Neglected Tropical Diseases". cdc.gov. June 6, 2011. Retrieved 28 November 2014.