Sẹ́ríkí ń góómà
Sẹ́ríkí ń Góómà
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ọba mẹ́wàá ìgbà mẹ́wàá,
Ìgbà kan ò lolé ayé gbó
Sẹ́ríkí ń góómà, sànmọ́nì góómà
Ìgbà ti lọ ńlẹ̀ yìí
Ohun gbogbo ti yí padà ni wàràwàra.
Ejò ìgbà ti wọ́ kúò níbi tàná,
Ìgbà tó dé làwá ń lò ẹ̀bi wa kọ́ rárá,
Ọ̀pọ̀ èèyàn tí ò bá fẹ́ bágbà yí ló le máa jàgbùrín èṣí lọ́bẹ̀
Mo rántí lákòókò kan nílẹ̀ yí
Mo kúkú ti gbọ́njú, ń ò tí ì bàlágà ni.
Pẹ́bẹ́ lọ, pẹ́bẹ́ bọ̀ àtẹ́lẹsẹ̀ ni láti Èkó títí dé ‘Bàdàn,
Kò sí mọ́tò bẹ́ẹ̀ ni kò sí bàtà lẹ́sẹ̀
Bóòrùn ti ń pawọ ori, ...
Akinwùmi Fẹ̀yìn tì
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Òréré ilé ayé rèé,
Kò sóhun tó nibẹ̀rẹ̀ tí ò ní í lópin jọjọ
Bóòrùn ti lágbára to,
Tiná ọmọ ọrara ń pa tẹru-tọmọ
Bó pẹ́ bó yá ojú ọjọ́ a rọ̀ wọ̀ọ̀,
Òòrùn a sì wọ̀ọ̀kùn, ààjin dùndùn.
Òṣúpá jèréjèré, a-mọ́-láwọ̀ bí ọ̀kinkin,
Nǹkan rìbìtì tó ń tànmọ́lẹ̀ lálẹ́.
Tí gbogbo wá fí ń tànmọ́lẹ̀ lálẹ́.
Ti gbogbo wá fi ń gbáfẹ́ orí,
Ìgbà tòṣù bá sì dàràn-mọ́jú,
Ara kálukú a sì rọ̀ wọ̀ọ̀,
A sì di wọ̀mù lórí ibùsùn.
Bó ti wù kọ́mọdé gbádùn eréṣùpá tó.
Bóṣú bá paná, eré a sì dìkàsìn,...
Ori mi àpé
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Orí mi àpé,
Àyà mi àkóbì-bọ
Nígbà tórí ń gbeni
Kín lòòṣà ń wò?
Orí lẹja fi í labú já,
Orí lọ̀kàsà fi í ṣe rere lálẹ̀ odò
Orí la fi í mẹ́ran láwo
Tá à kì í fì í méyìí tó léegun
Orí lobìnrin fí í yan ọkọọre ńlé ayé,
Orí lobìnrin fí í jókòó nílé ọkọ rẹ̀
Kó tóó dòpìtàn.
Orí ló ṣọba tó fi dádé owò,
Orí ló ṣèjòyè tó fi tẹ̀pá ilẹ̀kẹ̀. ...
Bí mo bá lówó
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Onígbèsè mọ ọbẹ̀ẹ́ sè owó ni ò sí lọ́wọ́
Tálákà náà lè jẹ̀dọ̀ ẹran,
Ó le jẹ Ṣàkì, jabọ́dìí, jẹ ibi iké inú ẹran.
Ẹrú le ṣe bí Ọba, kò tún tẹ̀páàlẹ̀kẹ̀.
Ẹni bá ń ṣe fújà láìlówó lọ́wọ́,
Ṣe ló fẹ́ gbéra rẹ̀ sí kòtò
Èèyàn ò lówó lọ́wọ́.
Ó ní pẹ́tẹpẹ̀tẹ́ lè jábọ́
Bá a bá bẹ̀dí ọ̀rọ̀ wò,
Onitọ̀hún fẹ́ ṣu bára ni.
‘N ò nigbá, ń ò láwo’
Ẹni náà ò tí ì sọ ǹkan tí kò ní. ...
Débọ̀ Awẹ́ (2004), Ẹkún Elédùmarè Elyon Publishers, ISBN 978 2148 17
2, oju-iwe 1-20.