Samsoni Ọlajuwọn Kokumọ Ọlayide
Samsoni Ọlajuwọn Kokumọ Ọlayide bí ni, Iléṣà, Ìpínlẹ̀ ìwọ̀ oòrùn Nàìjíríà tẹ́lẹ̀: (1928 - 1984),jẹ́ Olùkọ́ àti Ọ̀jọ̀gbọ́n ní ìmọ̀ ọrọ̀ ajé ajẹmọ́-ohun-ọ̀gbìn-ati- ìsìn.
Àwọn òbí rẹ̀ ni Josiah Ogunpooo Ọláyídé (ti ẹgbẹ́ Ògbóni ipele gíga ní Iléṣà) àti Mariam Ọláyídé (Ọmọ Oni - Ìbátan Lisa ti Eti-Ooni ní Ìjẹ̀sà). Ó fẹ́ Theresa Folashade Ọláyídé (ọmọ Ikoli, ọmọ gbajúmọ̀ olóṣèlú, olùfẹ́-orílẹ̀èdè àti oníròyìn Ernest Sessei Ikoli) ní 1961. Ó bí ọmọ mẹ́rin àwọn náà ni Biodun, Tokunbo, Oluwole, àti Olajide
Ọláyídé kẹ́kọ̀ọ́ ní Iléẹ̀kọ́ Alákọ̀bẹ́ẹ̀rẹ̀ Ṣọ́ọ̀sì Àpọ́sítélì (Apostolic Church Primary School) ní Iléṣà àti Kọ́lẹ́jì àwọn olùkọ́ tí ìjọba ní Ìbàdàn kí ó tó tẹ̀síwájú lọ sí Yunifásítì ti ìlú Lọ́ndọ́nnù ní 1955, níbi tí ó ti gba oyè BA nínú ẹ̀kọ́ ọrọ̀ - ajé ní 1957. Ó lọ sí US níbi tí ó ti gba oyè MSc àti òye Ọ̀mọwé ní ẹ̀kọ́ ọrọ̀-ajé ajẹmọ́-ohùn-ọ̀gbìn- àti - ọsìn.
Ó jẹ́ Gíwá láàrin ọdún 1979 sí 1983, wọ́n sì yàn án láti du ipò fún sáà kejì kí ó tó kú lójijì ní March 1984. òǹkọ̀wé àti alákòóso tó gbámúṣe ni. Bákan náà ni ó ti di àwọn ipò bí olùwádìí àti olùdarí mú, púpọ̀ gbajúmọ̀ ní Benin - Owena River Basin Authority, NIFOR, NISER, FAO (Àjọ oúnjẹ àti ajẹmọ́-ọ̀gbìn-àti-ọ̀sìn ní Milan, Ìtàló) àti ẹ̀ka ìṣàkóso ètò ajẹmọ́-ohùn- ọ̀gbìn-àti-ọ̀sìn tí Ìjọba Àpapọ̀ Naijiria (Federal Agricultural Coordinating Units FACU.
Ọláyídé ti gbé ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ àpilẹ̀kọ jáde ní àwọn ìwé àtìgbàdégbà(jọ́nà) tí orílẹ̀èdè àti jọ́nà àgbáyé ajẹmọ́-ìmọ́ báyéṣerí, èyí tí ó gbayì jù ni àpilẹ̀kọ rẹ̀ lórí "Ìṣòro oúnjẹ orílẹ̀èdè Nàìjíríà" tí ó kà ní 1974 tí ó jáde nínú ìwé àtìgbàdégbà (jọ́nà) ti Ibùdó-ìmọ̀ ìwádìí ajẹmọ́ ìbáraẹnigbépọ àti ọrọ̀ ajé tí Orílẹ̀èdè Nàìjíríà - (Nigerian Institute of Social and Economic Research (NISER)). Bákan náà ni ó jẹ́ òǹkọ̀wé ogúnlọ́gọ̀ àwọn ìwé ní ọrọ̀ ajé, àtúpalẹ̀ àti tíọ́rì ọrọ̀-ajé àti ọrọ̀-ajé ajẹ́mọ́-ohun ọ̀gbìn àti ọ̀sìn.