Samuel Ọlásẹ̀hìndé

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Jump to navigation Jump to search

Samuel Ọláolúwa Ọlásẹ̀hìndé tí wọ́n bí ní Ọjọ́ kẹrìndínlógún oṣù kẹfà (16th July) jẹ́ òṣèré sinimá àgbéléwò ọmọ bíbí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Bàbá rẹ̀ ni gbajúgbajà aláwàdà òṣèré sinimá àgbéléwò, Káyọ̀dé Ọlásẹ̀yìndé tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Pa James.[1] Ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ tíátà nígbà tí ó wà lọ́mọ ọdún márùn-ún nígbà tí ó kópa nínú sinimá àgbéléwò kan tí àkọ́lé rẹ̀ ń Arówólò. Kódà, ó gba àmìn ẹ̀yẹ fún ipa tí ó kó nínú sinimá yìí. Lẹ́yìn náà, ó tún kópa nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ sinimá àgbéléwò nígbà èwe rẹ̀. [2]

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "Dad is a no-nonsense person, he is only comical in movies – Pa James’ son". Punch Newspapers. 2015-12-15. Retrieved 2020-01-11. 
  2. Author (2019-03-09). "Samuel Olaseinde". My Gold Pen. Retrieved 2020-01-11.