Sandra Duru-Eluobi

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Sandra Chidinma Duru-Eluobi jẹ́ oníṣòwò àti olùdásílẹ̀ Pre-Adult Affairs Organization.Òun ni alákoso ilé iṣẹ́ Sanchhy Nigeria Limited[1], Zest Media and Entertainment àti Executives Cable and Electronics Company.[2] Ó jẹ́ onímòràn fún Standard Organization, Police Women Units, Police Service Commission àti Kulfana Mining Company. Ó kọ ipa ribiti nínú bíi Rochas Okorocha ṣe di gómìnà Ìpínlẹ̀ Ímò ni odun 2011.[3] Ní ọdún 2013, ó gbìyànjú láti dá ẹgbẹ́ òṣèlú tirẹ̀ kalẹ̀, kí ó ba le díje fún ipò gómìnà. Ní ọdún 2015, ó dá ètò Bare It Out! With Sandra Duru.[4] Ní ọdún 2014, àmbásẹ́dọ̀ Nàìjíríà fún orílè-èdè Ivory Coast fun ní àmì ẹ̀yẹ fún ipa tí ó kó láti wá àtúnṣe fún ìṣòro aìníṣẹ́, ìjà àti bí ó ṣe pèsè ẹ̀kọ́ fún àwọn ọmọ Nàìjíríà.[5] Ní ọdún 2016, ó gbé ètò tuntun kan kalẹ̀ tí ó pè ní The Up Project.[6] Ní ọdún 2014, ó fẹ́ Emmanuel Ebuka Eulobi tí ó jé agbábọ́lù, wọ́n sì bí ọmọkùnrin kan ní oṣù kẹfà ọdún 2016.[7]

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]