Saudatu Mahdi
Saudatu Mahdi MFR | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | 20 Oṣù Kẹrin 1957 Katsina State |
Orílẹ̀-èdè | Nigeria |
Iléẹ̀kọ́ gíga | Ahmadu Bello University, Zaria |
Iṣẹ́ | Women’s Rights Advancement and Protection Alternative (WRAPA) - Secretary General |
Gbajúmọ̀ fún | Advocacy, Development, Women's Rights |
Notable work | Bring Back Our Girls |
Saudatu Mahdi (bíi ni ọjọ́ ogún, oṣù kẹrin ọdún 1957) jẹ́ àjàfẹ̀tọ́ fún àwọn obìnrin ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Òun ní akọ̀wé fún ẹgbẹ́ Women's Rights Advancement and Protection Alternative (WARPA).[1] Ó ti kọ ìwé tí ó lé ní ogún lórí bí ìyà ṣe ń jẹ àwọn obìnrin.[2] Mahdi ni ó jẹ́ adarí fún àwọn tó parapọ̀ láti jà fún obìnrin tí wọ́n fẹ́ pá nítorí wípé ó bí ọmọ láì ṣe ìgbéyàwó.[3][4][5]
Ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ayé àti ẹ̀kọ́ rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Wọ́n bí Mahdi ní ọjọ́ ogún, oṣù kẹrin ọdún 1957 sí ìpínlẹ̀ Katsina ní Nàìjíríà. Ní ọdún 1964, ó bẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní ilé ẹ̀kọ́ Kaduna Central Primary school. Ní ọdún 1970, ó lọ sí ilé ẹ̀kọ́ Queen Amina College ní Ìpínlẹ̀ Kàdúná.[6] Ní ọdún 1978, ó gboyè jáde láti ilé ẹ̀kọ́ gíga tí Ahmadu Bello University ní ìpínlẹ̀ Zaria.
Iṣẹ́
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ bí olùkó ní ilé ìwé ṣáájú kí ó tó kọ̀wé ìfìpòsílẹ̀. Ní oṣù kẹjọ ọdún 1989, ó di olórí ilé ìwé Government Girls Secondary School ni ìpínlẹ̀ Bauchi. Ní ọjọ́ kejìlá oṣù kẹrin ọdún 1995, wọ́n fi ṣe alákòóso ilé ẹ̀kọ́ gíga tí Abubakar Tatari Ali Polytechnic ní Bauchi, ó sì di ipò náà mú títí di ọjọ́ kọkànlá oṣù kọkànlá ọdún 1998 tí ó wà fi iṣẹ́ náà sílẹ̀. Ó jẹ́ akọ̀wé gbogbogbò fún ẹgbẹ́ Women's Rights Advancement and Protection Alternative (WARPA)[7].
Àmì ẹ̀yẹ
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ní ọjọ́ kẹẹdọgbọn oṣù kọkànlá ọdún 2011, Ààrẹ orílẹ̀ èdè tẹ́lẹ̀ rí, Goodluck Jonathan fún ní ẹ̀bùn National Honours Award.[8]
Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "Board of Trustees - Wrapa". Wrapa. Retrieved 29 December 2016.
- ↑ "BOARD OF DIRECTORS". Nigerian Women's Trust Fund. NWTF. Archived from the original on 30 October 2016. Retrieved 29 December 2016.
- ↑ "Ms. Magazine Women of the Year: Heroes for Extraordinary Times". www.msmagazine.com. MS Magazine. Retrieved 29 December 2016.
- ↑ Kozieł, Patrycja. Hausa Women’s Rights and Changing Perception of Gender in Northern Nigeria. https://www.academia.edu/28829422/Hausa_Women_s_Rights_and_Changing_Perception_of_Gender_in_Northern_Nigeria. Retrieved 29 December 2016.
- ↑ "Ms. Magazine Women of the Year: Heroes for Extraordinary Times". www.msmagazine.com. MS Magazine. Retrieved 29 December 2016.
- ↑ "Convention on the Elimination of All Forms of Discrimination against Women" (PDF). UN. United Nation. Retrieved 29 December 2016.
- ↑ "RECOGNITION FOR THE AMAZONS". TheNigerianVoice.com. The Nigerian Voice. Retrieved 29 December 2016.
- ↑ "RECOGNITION FOR THE AMAZONS". TheNigerianVoice.com. The Nigerian voice (The Nigerian Voice). 15 November 2011. https://www.thenigerianvoice.com/news/75127/recognition-for-the-amazons.html. Retrieved 29 December 2016.