Jump to content

Segilola Ogidan

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Segilola Ogidan
Ọjọ́ìbíNàìjíríà
Orílẹ̀-èdèNigerian
Iléẹ̀kọ́ gígaRoyal Holloway University of London
Iṣẹ́Actress, director, film producer
Notable workA Naija Christmas

Segilola Ogidan jẹ́ òṣèrébìnrin ilẹ̀ Nàìjíríà, ó si tún jẹ́ òǹkọ̀wé, olùdarí, àti olúṣe fíìmù.[1]

Ó gboyè ẹ̀kọ́ ní Royal Holloway University of London, ó sì tún gboyè Masters láti University of Bristol níbi tí ó ti kẹ́kọ̀ọ́ nípa iṣẹ́ sinemá.[2] Ó gbajúmọ̀ fún ṣíṣe ẹ̀dá-ìtàn "Ajike" nínú fíìmù Netflix kan, tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ A Naija Christmas.[3]

Ogidan bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ eré-ṣíṣe lẹ́yìn ìgbà tó parí ètò ẹ̀kọ́ rẹ̀, tó sì kópa nínú fíìmù Peter Pan, ní tíátà The Kings Head, èyí tí Stephanie Sinclaire darí.[4] Segilola farahàn nínú fíìmù RED Tv kan, tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ The Men's Club, níbi tí ó ti ṣe ẹ̀dá-ìtàn “Tonye”.[5] Ogidan sì ti kópa nínú àwọn fíìmù bí i Glamour Girls', Fault Lines, Payday, àti Mona.[6]

Àtòjọ àwọn fíìmù rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  • Glamour Girls
  • Fault lines
  • A Naija Christmas
  • The Olive
  • The Men's Club
  • Payday
  • Mona
  • Hot Pepper
  • Unspoken
  • Tainted Canvas

Ìdálọ́lá àti ìgbàmì-ẹ̀yẹ[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n yan Segilola fún àmì-ẹ̀yẹ NET ní ọdún 2022, fún òṣèrébìnrin tó dára jù lọ, látàrí ìkópa rẹ̀ nínú fíìmù A Naija Christmas.[7]

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "Segilola Ogidan: I’ve Always Been an Entertainer… – THISDAYLIVE". www.thisdaylive.com. Retrieved 16 July 2022. 
  2. "It hurts when people don’t understand me — Segilola Ogidan". Punch Newspapers (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 21 March 2020. Retrieved 16 July 2022. 
  3. "‘A Naija Christmas’ Review: Honoring a Mother’s Wish". https://www.nytimes.com/2021/12/16/movies/a-naija-christmas-review.html. 
  4. "Segilola Ogidan: I’ve Always Been an Entertainer… – THISDAYLIVE". www.thisdaylive.com. Retrieved 16 July 2022. 
  5. The Men's Club (TV Series 2018–2019) - IMDb 
  6. "Segilola Ogidan". IMDb. Retrieved 16 July 2022. 
  7. "NET Honours 2022: Genoveva Umeh, Teniola Aladese and more Nominated for First-Ever Breakout Actress of the Year Category". Nigerian Entertainment Today (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 24 June 2022. Retrieved 16 July 2022.