Seyi Adebanjo

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Seyi Adebanjo ni ó jẹ́ genderfluid, queer MFA media artist, tí ó jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí ó sì ti fi ìlú New York City ṣe ibùgbé báyí ni ó ni lọ́kàn láti ma ṣe ipò lòó fún àwọn ìpèníjà tí ó ń dojú ke ẹ̀yà, adámọ́ àjọ ati abo tàbí ìbálòpọ̀ nípa yíya àwòrán, ṣíṣe fọ́nrá, tabí eré àgbéléwò àti àwọn àpilẹ̀kọ oríṣiríṣi nípa lílo àwọn ìkanì ìbáni-dọ́rẹ́.[1]

Àwọn iṣẹ́ rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Adébánjọ ti ṣe àfihàn àwọn iṣẹ́ ọláọ́kan-ò-jọkan rẹ̀ ní àwọn ilé ìṣe nkan ìṣẹ̀mbáyé lọ́jọ̀ sí pàá pàá jùlọ ní Museum of the City of New York, Bronx Academy of Arts and Dance (BAAD!), Longwood Art Gallery and Skylight Gallery-Restoration Plaza Corporation, Leslie-Lohman Museum of Gay and Lesbian Art àti Waterloo Arts Gallery. Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyí, àwọn iṣẹ́ rẹ̀ wà lábẹ́ Bronx Museum. Bákan náà ni wọ́n tún wà pẹ́lú Fellow The Laundromat Project, Queer/Art/Mentorship, Maysles Institute, Independent Filmmaker Project, àti City Lore.[1]

Ìwé ìròyìn olóṣooṣù ti African Voices magazine, Osun State University, Q-Zine, àti Mott Haven Herald ti gbé orísiríṣi iṣẹ́ tí Adébánjọ ti gbé háde. Adébánjọ ti tún ṣe àfihàn iṣẹ́ rẹ̀ ní ilé-ẹ̀kọ́ New York University, ati Lambda Literary Foundation, àti níbi àpérò University Film and Video Association, pẹ́lú ibi àpérò Brazilian Queering Paradigms Conference.[1]

Àwọn eré agbéléwò rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Lára àwọn iṣẹ́ rẹ̀ ni:

  1. Trans Lives Matter!: Justice for Islan Nettles. Eré tí ó jẹ́ òní ìṣẹ́jú keje péré tí ó da lórí ìṣekúpa obìnrin tí ó jẹ́ transgender tí wọ́n ń pè ní Islan Nettles ni ó gbé jáde ní inú osù keje ọdún 2013.[2] Ilé-iṣẹ́ PBS tí wà lórí ìkànì kẹtàlá (13) ṣe àfihàn eré náà, pẹ̀lú Brooklyn Museum. Bá kan náà ni wọ́n ṣe àfihàn rẹ̀ káàkiri agbáyé, tí ó fi mọ́ BFI Flare ní London, wọ́n tún ṣe àfihàn rẹ̀ lórí LGBT Film Festival, Gender Reel Film Festival, Al Jazeera America, ati Black Star Film Festival.

Oya! Something Happened on the Way to West Africa! ni ó jẹ́ eré ọláọ́gbọ̀n ìṣẹ́jú tí ó wà ṣàkun ẹ̀yà àti ìbálòpọ̀. Eré yí ni ó ṣe àgbéyẹwò ìrírí ẹ̀yà ọmọ Nàìjíríà tí ó wà ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ati ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà míràn tí ó wà ní ìlú New York[3]

Àwọn amì-ẹ̀yẹ rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Adébánjọ ti gba àwọn amì-ẹ̀yẹ ti onkọ̀tàn tó peregedé jùlọ ní orí Short award ní ibi ayẹyẹ Drama Baltimore International Black Film Festival, Reel 13 Short Film Award,[1] Fish Parade 2015 Grand Marshal,[3]. Ó tún gba amì-ẹ̀yẹ ti Best International Short Film ní Sydney Transgender International Film Festival ,[1] ati Pride of the Ocean LGBT Film Festival Award [4] àti Hunter College's Dean of Arts & Science Master's Thesis Support Grant.

Àwọn ìtọ́ka sí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àdàkọ:Authority control