Jump to content

Shaibu Husseini

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Shaibu Husseini
Ọjọ́ìbí4 Oṣù Kejìlá 1970 (1970-12-04) (ọmọ ọdún 54)
Iṣẹ́Film critic, journalist, performing artist, lecturer

Shaibu Husseini (tí a bí ní ọjọ́ 4 oṣù kejìlá, ọdún 1970 [1] ) jẹ́ akọ̀ròyìn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, tó tún jẹ́ olórin, alábòójútó àṣà, PR àti agbaninímọ̀ràn lórí ẹ̀rọ ayélujára àti olùtọ́jú fíìmù..[2][3][4] Ó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè nínú ẹ̀kọ́ Mass Communication ní University of Lagos, ó sì ti kàwé ní Lagos State University School of Communication àti ní University of Lagos níbi tí ó ti gba BSc (First Class) ní Mass Communication àti MSc (Distinction) bákan náà. Wọ́n ṣe àpejúwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi “akọ̀wé ìwé-ìpamọ́ tó ṣe déédé jù lọ” lórí àwọn àkọ́lé tí ó jọ mọ́ Nollywood.[5] Ní ọdún 2010, ó ṣàtèjáde ìwé rẹ̀, tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ Moviedom, tí ó sọ àwọn ìpele ìdàgbàsókè ti Nollywood.[6] Ó jẹ́ olórí ìgbìmọ̀ ti àwọn olùṣàkóso ti ọdún 2017 ní Africa Movie Academy Awards.

Àwọn ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]