Simon Kolawole

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Simon Kolawole
Orílẹ̀-èdèNigerian
Ẹ̀kọ́University of Lagos
University of Sussex
SOAS University of London
Iṣẹ́Nigerian journalist and media entrepreneur
Gbajúmọ̀ fúnFounder, CEO at TheCable

Simon Kolawole jẹ́ akọ̀ròyìn, aṣọ̀rọ̀-lórí-ìtàgé, àti onímídíà aládàáni ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.[1][2][3][4] Ó jẹ́ olùdásílẹ̀ àti olùdarí ní Cable Newspaper Limited,[5] lábẹ́ The Cable, iléeṣẹ́ ìwé ìròyìn orí afẹ́fẹ́ aládàáni.[6] Ní ọdún 2012, àjọ ètò ọrọ̀-ajé lágbàáyé "the World Economic Forum" pe Simon Kolawole ní ọ̀kan lára àwọn ọ̀dọ́darí lágbàáyé, èyiun Young Global Leaders gẹ́gẹ́ bíi ẹ̀yẹ ìdánimọ̀ fún iṣẹ́ rẹ̀ àti ìfọkànjìn rẹ̀ sí àwùjọ.[7][8]

Gẹ́gẹ́ bí Daily Trust se ṣe àfihàn rẹ̀, nígbà tí Kolawole wà ní ọmọ ọdún mọ́kàndínlọ́gbọ̀n, ó di ẹni tó kéré jù lọ lọ́jọ́ orí tó jẹ́ aṣàtúnṣe sí ìwé ìròyìn àpapọ̀ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.[9] Ní ọdún 2007, ẹ̀wẹ̀, nígbà tí ó di yíyàn gẹ́gẹ́ bíi aṣàtúnṣe fún ìwé ìròyìn This Day, ó tún jẹ́ ọmọ Nàìjíríà tó kéré jù lọ tí ó ní irú àṣeyọrí yìí.[10]

Ìbẹ̀rẹ̀ ìgbé-ayé àti ẹ̀kọ́ rẹ̀.[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ìlú Ilorinìpínlè Kwara, orílè-èdè Nàìjíríà ni wọ́n gbé bí Kolawole Simon, ṣùgbọ́n ó ṣí lọ sí ìlú Mopa ní ìpínlẹ̀ Kogi láti gbé pẹ̀lú arúgbóbìnrin rẹ̀ lẹ́yìn tí bàbá rẹ̀ kú ní inú ìjàmbá ọkọ̀ ojú ọ̀nà ní ọdún 1976. Ní ọdún 1989, ó padà sí ìlú Èkó láti lọ kẹ́kọ̀ọ́ gbọyè ní inú Mass Communication ní ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì tí ìlú Èkó èyiun University of Lagos.[11][12][13]

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. Agoro, Adegbenga. "Simon Kolawole | The Platform Nigeria .::. The Platform 11.0, The October Event". www.theplatformnigeria.com. Retrieved 2018-05-06. 
  2. Editor. "Simon Kolawole, Publisher of The Cable | Africainterviews". www.africainterviews.com. Retrieved 2018-05-06. 
  3. Adebanwi, Wale (1 January 2008). Trials and Triumphs: The Story of TheNEWS. African Books Collective. ISBN 9789781532320. https://books.google.com/books?id=hyTvg2pWJ_EC&dq=%22Simon+Kolawole%22&pg=PA54. 
  4. "simon kolawole (@simonkolawole) | Twitter". twitter.com. Retrieved 2018-04-26. 
  5. "Simon Kolawole - SMWLagos". SMWLagos. http://smwlagos.com/?team=simon-kolawole. 
  6. "Simon Kolawole - World Economic Forum". World Economic Forum. 
  7. "Community". The Forum of Young Global Leaders. Retrieved 2020-03-09. 
  8. "Nigeria: Kolawole, Thisday Editor, Named Young Global Leader". 7 March 2012 – via AllAfrica. 
  9. "16783 When ex thisday editor unveiled the cable newspaper". Daily Trust Nigeria. Archived from the original on 15 June 2018. https://web.archive.org/web/20180615111726/https://www.dailytrust.com.ng/sunday/index.php/media-media/16783-when-ex-thisday-editor-unveiled-the-cable-newspaper. 
  10. Banker, The. "Search -". www.thebanker.com. 
  11. Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid <ref> tag; no text was provided for refs named auto2
  12. "How I Gave My Life To Christ Jesus – Simon Kolawole, Cable News CEO". PRAYERS FIRE. 2016-07-29. Archived from the original on 2018-05-08. https://web.archive.org/web/20180508185738/http://www.prayersfire.com/2016/07/29/how-i-gave-my-life-to-christ-jesus-simon-kolawole-cable-news-ceo/. 
  13. "Advisory Board". risenetworks.org. Archived from the original on 2018-05-08. Retrieved 2018-05-06.