Jump to content

Souhir Ben Amara

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Souhir Ben Amara
Ọjọ́ìbí27 Oṣù Kọkànlá 1985 (1985-11-27) (ọmọ ọdún 39)
Orílẹ̀-èdèTunisian
Iṣẹ́Actress
Ìgbà iṣẹ́2008-present

Souhir Ben Amara (tí wọ́n bí ní 27 Oṣù Kọkànlá, Ọdún 1985) jẹ́ òṣèrébìnrin ọmọ orílẹ̀-èdè Tùnísíà.

Ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú kíkópa nínu àwọn eré tẹlifíṣọ̀nù bíi Maktoub àti Choufli Hal ní ọdún 2008. Ó kópa gẹ́gẹ́ bi Maliha nínu eré Min Ayam Mliha ní ọdún 2010. Ben Amara kó àkọ́kọ́ ipa sinimá àgbéléwò rẹ̀ nínu eré tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Always Brando (2011), èyí tí olùdarí rẹ̀ n ṣe Ridha Béhi. Ó kó ipa Zena nínu eré náà, èyí tí ó rí ànfààní rẹ̀ lẹ́hìn tí olùdarí eré náà kò faramọ́ òṣèrébìnrin tí wọ́n kọ́kọ́ yàn fún ipa náà.[1] Ní ọdún 2012, Ben Amara kó ipa Aicha nínu eré Millefeuille, èyí tí olùdarí rẹ̀ n ṣe Nouri Bouzid, tó síì n dá lóri àwọn awuye tí ó rọ̀ mọ́ ìbòrí àwọn obìnrin mùsùlùmí.[2]

Ní ọdún 2013, ó kó ipa Donia nínu eré Yawmiyat Imraa.[3] Ní ọdún 2019, ó kópa nínu eré tẹlifíṣọ̀nù tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Kingdoms of Fire.[4] Ó tún kó ipa olú-ẹ̀dá-ìtàn nínu eré Sortilège (2019), èyí tí Ala Eddine Slim ṣe adarí rẹ̀.[5] Eré náà kọ́kọ́ jẹ́ gbígbé jáde níbi ayẹyẹ Cannes Film Festival.[6]

Ben Amara darapọ̀ mọ́ àwọn ẹgbẹ́ afẹ̀họ́nú kan tí wọ́n pè ní Arab Spring.[7]

Àṣàyàn àwọn eré rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
Àwọn sinimá àgbéléwò
  • 2011 : Always Brando : Zena
  • 2012 : Millefeuille : Aïcha
  • 2014 : Tafkik
  • 2017 : El Jaida
  • 2018 : The Crow's Siesta
  • 2019 : Sortilège
Àwọn eré tẹlifíṣọ̀nù
  • 2008 : Maktoub : Lili
  • 2008 : Choufli Hal
  • 2009 : Achek Assarab : Fatma
  • 2010 : Min Ayam Mliha : Maliha
  • 2012 : Dipanini
  • 2013 : Yawmiyat Imraa : Donia
  • 2014 : Dragunov
  • 2015 : Anna e Yusuf
  • 2015 : Lilet Chak : Linda
  • 2015 : Histoires tunisiennes : Sandra
  • 2016 : Le Président
  • 2016-2017 : Flashback
  • 2016 : Bolice 2.0
  • 2017 : La Coiffeuse
  • 2019 : Kingdoms of Fire : Hafsa Sultan

Àwọn ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. "Souhir Ben Amara (album photos)". Tunivisions (in French). 12 April 2013. Archived from the original on 18 May 2013. Retrieved 11 November 2020. 
  2. ""Millefeuille" : le voile, sans trop de débat" (in French). 4 June 2013. https://www.lemonde.fr/culture/article/2013/06/04/millefeuille-le-voile-sans-trop-de-debat_3422853_3246.html. Retrieved 11 November 2020. 
  3. "Souhir Ben Amara: La femme et l'actrice se livre au HuffPost Tunisie" (in French). TN24. 20 August 2018. https://tn24.tn/ar/article/souhir-ben-amara-la-femme-et-l-actrice-se-livre-au-huffpost-tunisie-8283. Retrieved 11 November 2020. 
  4. "Le feuilleton "Kingdoms of fire" en tournage en Tunisie". Kapitalis (in French). 13 February 2013. Retrieved 11 November 2020. 
  5. "Ala Eddine Slim, Souhir Ben Amara présentent " Sortilège " : un voyage hypnotique au coeur du désert tunisien" (in French). TV5Monde. 15 February 2020. https://culture.tv5monde.com/cinema/l-invite/ala-eddine-slim-souhir-ben-amara-presentent-sortilege-un-voyage-hypnotique-au-coeur. Retrieved 11 November 2020. 
  6. Kheder, Raouia (22 November 2019). "Femme du mois: Souhir Ben Amara : " Je suis réalisatrice de formation, mais l’actrice en moi s’est imposée d’elle-même"" (in French). Femmes de Tunisie. Archived from the original on 19 October 2021. https://web.archive.org/web/20211019043033/https://femmesdetunisie.com/femme-du-mois-souhir-ben-amara-je-suis-realisatrice-de-formation-mais-lactrice-en-moi-sest-imposee-delle-meme/. Retrieved 11 November 2020. 
  7. "Souhir Ben Amara : " Les politiques ont volé le rêve des Tunisiens "". Elle (in French). Retrieved 11 November 2020. 

Àwọn ìtakùn Ìjásóde

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]