Táíwò Oyèbọ́lá Agbóná
Ìrísí
Táíwò Oyèbọ́lá Agbóná jẹ́ ọ̀dọ́mọbìnrin ọmọ ọdún mẹ́rìnlélógún tí ó jọba nípò Adelé ní ìlú Ààyè ní ìpínlẹ̀ Oǹdó lorílẹ̀-èdè Nàìjíríà.[1] Ó wà lọ́mọ ọdún méjìlélógún, ọmọ Ilé ẹ̀kọ́ gíga ifáfitì, Achievers University, ní ìlú Ọ̀wọ̀ ní ìpínlẹ̀ Oǹdó, tí ó ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìṣègùn òyìnbó lọ́dún 2017 tí ifá fi yàn án lẹ́yìn tí bàbá rẹ̀, tí ó jẹ́ Ọ̀ba, Kábíyèsí Aláàyè tí ìlú Aàyè, Ọba J. B. Agbóná wàjà lọ́jọ́ kẹrin oṣù karùn-ún ọdún 2017.[2]. Táíwò Oyèbọ́lá Agbóná ní ó wà nípò Ọba ìlú Aàyè, gẹ́gẹ́ bí Adelé, tí ó sìn ń pàṣẹ ìlú náà lọ́wọ́lọ́wọ́. [3]
Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "Why Princess Taiwo 'wants to rule Nigeria'". BBC News. 2019-05-05. Retrieved 2020-02-22.
- ↑ "Meet Taiwo Agbona, Nigerian king 'chosen by oracle' but can’t get married, pregnant on the throne". TheCable Lifestyle. 2019-12-22. Retrieved 2020-02-22.
- ↑ "Her Royal Majesty Taiwo Oyebola Agbona Tells Us What It Feels Like To Be The Regent Of Aaye Town In Ondo State". Woman.NG. 2019-06-11. Archived from the original on 2020-02-27. Retrieved 2020-02-22.