Tíátà

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Lọ sí: atọ́ka, àwárí
Gbangan Tiata

Tíátà jé òrò tí ó wáyé lati inú èdè Gíríìkì tí o túmò sí ibì ìwòran ó sì tún ní èka bí eré ìtàgé tí ó túnmò sí pé, nígbàtí ènìyàn kan tàbí jù béè bá kó ara won jo ní àkókò kan tábì sí ìbìkan láti dá àwon ènìyàn lárayá. Nípa ìtúmò tí ó gbòòrò yí, lati ìgbà tí ènìyàn ti wà láyé ni tíátà ti wà to béè ge ti ó se sajejuwe ìgbé ayé ènìyàn nítorí Ìfé àwon ènìyàn si ìtàn síso. Lati ipinlèsè tíátà, ni ó ti n mú orísiirísi àrà dání. A sì máa n ló àwon èròjà bi òrò, ìsesí, orin, ijó àti ìwòran papò mó eré ìtàgé sínú tíátà. Tíátà ayé ìsinsìnyí ni ó tún kún fún òtíto bí ó tilé jé pé ó pín sí orísiirísi ònà.

Tíátà àkókó ní a se ní ègberún odún méjì sájú ikú Olúwa wa séyìn, ni ó jé eré ìtara nípa ilè Ígíbítì ìgbanì. Ìtàn nípa Olórun órísírì ni wón fi n se tíátà ni ododún lati sin Olórun ósírísì won yi títi di ìgbà yé òlàjú, èyí wá fi hàn nípa ìbásepò tí ó wa láàrín tíátà àti èsin.

Àwon ará Gíríkì ìgbanì ni ó kókó se àgbékalè tíátà gégé bí ìse, wón sì túnmò tíátà sí orísirí ònà bí eré ti adùn kéyìn rè, eré ti ìbànújé kéyìn rè àti eré tí ó se àpèjúwe àwùjo.

Sùgbón láyé òde òní, tíátà síse ti gba ìgbà òtun, tí à n se sínú fánrán fún àgbéléwò àwon ènìyàn fún ìgbádùn. Tíátà síse ti wá da isé òòjó àwon kan lóde òní. Tíátà àsà àti ise tí àwon òsèrè máa n lò latí se ìgbélékè àsà àti ìse tí ó ti dòkú, pàápàá ní ilè Áfíríkà. Nípa tíátà ni a ti mò pàápàá ni ilè Yorùbá àwon àsà ati ise wa, tí ó ti sonù nítorí àsà àti ìwà àwon òyìnbó ti gba àsà àti ìse wa lówó wa.

Òkan nínú ìsòrí tíátà ni, tíátà nípa àwùjo àti òsèlú. Tíátà nípa àwùjo nì àwon eléré ìtàgé fi n se òpòlópò àyípadà sí àwon àlébù àti kùdìè-kudie tó kù nínú àwùjo wa lónìí. Nípà tíátà síse yálà nípa eré ìtàgé tàbí ti àgbéléwò ni àtúnse ti n bá òpòlopò ayé tí ó wà ní ìkòríta ìríjú, tí won kó si mo ohun tó ye lati se. Òpòlopò olósèlú ni bá tí so ayé di tàwon nìkan, bí kò bá sí ti àwon aléré ìtàgé tábì ti àgbéléwò tí óun pi ìwà ìbàjé won léde.

Tíátà tí ó ti wà lati bí òpò odún séyìn, ló ti gbá àtúnse nípa ìdàgbàsókè tí ó ti dé báa ní ayé òde òní. Tíátà sise yálà ti eré ìtàgé tàbí ti àgbéléwò ló wà fún èkó, ìtósónà ati fún ìsàtúnse àwùjo tí a wà lónìí.


Itokasi[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]