Jump to content

T.M. Ilésanmí

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Ọ̀jọ̀gbọ́n Thomas Makanjuola Ilésanmí ni ẹni àkọ́kọ́ tí ó gba oyè B. A ní ẹ̀ka-ẹ̀kọ́ èdè àti Lítíréṣọ̀ Áfíríkà ní Yunifásítì Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀. Ó jẹ́ Àlùfáà ti ijọ́ Páàdì (ìjọ Kátólíìkì mímọ́). Ó ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka ẹ̀kọ́ yìí láti ọdún 1975 tí ó sì fẹ̀hìntì ní ọdún 2005 .  Ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ ni Ọ̀jọ̀gbọ́n yìí  ṣe lórí èdè àti àṣà Yorùbá. Díẹ̀ lára àwọn iṣẹ́ rẹ̀ ni "Iṣẹ́ ìṣẹ̀ǹbáyé, Yorùbá Orature and Literature: A Cultural Analysis, Àwọn nǹkan abàmì ilẹ̀ Yorùbá, Obìnrin:A Cultural Analysis of Yorùbá women, Ọkùnrin làdá obìnrin làgbà, Àdúrà onígbàgbọ̀, Language of African Traditional Religion àti àwọn mìíràn.

Ojogbon T. M. Ilésanmí gba iṣẹ́ olùkọ́ ni Yunifásítì ti Ifẹ̀ (Yunifásítì Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ nísinsìnyí ), Ilé-Ifè, Nàìjíríà , gẹgẹ bii Graduate Assistant ní Ẹ̀ka-ẹ̀kọ́ Èdè Áfíríkà àti Lítíréṣọ̀ ní ọjọ́ kẹẹ̀dọ́gbọ̀ oṣù Bélú, Ọdún 1975 lẹ́yìn ìgbà tó ti gboyè méjì láti Yunifásítì Pontifical, ìlú Róòmù àti Yunifásítì ti Ifẹ̀ .

Ó gba ìgbéga lẹ́nu ìṣe tó fi dé ipò Ọ̀jọ̀gbọ́n ni Oṣù Òwàrà, ní ọdún 1997. Ipò yìí ni o wà títí tí ó fi fẹ̀hìntì lẹ́nu iṣẹ́ ní ìbámu pẹ̀lú òfin àlàkalẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìjọba ní ọdún 2005.

Bí a bá wo àkójọpọ̀ àwọn iṣẹ́ Ọ̀jọ̀gbọ́n yìí, a ó rí pé ẹni tí ó fẹ́ràn ìwádìí ṣíṣe lórí àwọn àkóónú nílẹ̀ Yorùbá, àṣà, ìṣe, èdè, lítíréṣọ̀ alohùn àti àwọn nǹkan yòókù tí ó sódo sínú àmù èrò ìjìnlẹ̀ ní àwùjọ Yorùbá. Ó fẹ́ràn láti máa ṣe iṣẹ́ àṣekára, ó sì jẹ́ ẹni tí ó ṣe é fọkàntán. Àràbà ni láwùjọ akadá, ẹ̀ká Yorùbá kò lè gbàgbé iṣẹ́ ribiribi tí ó ti ṣe láti mú ìdàgbàsókè bá àwùjọ wa.

Onimọ̀ tó gbòòrò ni Ọ̀jọ̀gbọ́n Ilésanmí torí pé àwọn iṣẹ́ ìwádìí lórí àwọn ayẹyẹ ìrúbọ àti ìtàn Ìbílẹ̀ múnádóko, wọ́n sì wúlò púpọ̀ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ èdè Yorùbá fún iṣẹ́ ìwádìí. Ó máa n kó àwọn èèyàn mọ́ra, oníwà ìrẹ̀lẹ̀ sì ni.

Láàárín àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀, Ọ̀jọ̀gbọ́n Ilésanmí ti bójútó ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lórí iṣẹ́ àpilẹ̀kọ fún àsekàgbá láti gboyè ní ọ̀kan-ò-jọ̀kan ipele ìkẹ́kọ̀ọ́-gboyè.

Onimọ̀ tó làmìlaka ni Ọ̀jọ̀gbọ́n Ilésanmí, ó mú ìmúgbòòrò bá èdè àti àṣà Yorùbá. Ó jẹ́ ìpè Ọlọ́run ní ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n, Oṣù Èbìbí, Ọdún 2016.


  • PROFESSOR T.M. ILESAMI AND YORUBA STUDIES