Taha Karaan
Taha Karaan (2 June 1969 – 11 June 2021) jẹ́ onímọ̀ Mùsùlùmí ti orílẹ̀-èdè South Africa àti amòfin. Òun ni olórí Muslim Judicial Council, ti ilẹ̀ South Africa nígbà náà. Òun ni olùdásílè Mahajjah Research Institute àti Dar al-Uloom al-Arabiyyah al-Islamiyyah ní Strand, Western Cape.
Ìtàn ìgbésíayé rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ọjọ́ kejì, oṣù kẹfà, ọdún 1969 ni a bí Taha Karaan, ní Cape Town.[1][2] Òun ni ọmọ Yusuf Karaan.[3]Ó ṣe àkàsórí ìwé Kùráànì ní Waterfall Islamic Institute, ó sì lọ kẹ́kọ̀ọ́ ní Darul Uloom Deoband, níbi tí ó ti kẹ́kọ̀ọ́ gboyè ní ọdún 1991 pẹ̀lú èsì ìdánwò tó dára jù lọ. Ó padà lọ kàwé ní Cairo University fún ọdún méjì.[1][4] Díẹ̀ nínú àwọn olùkọ́ rẹ̀ ni: Saeed Ahmad Palanpuri.[1]
Wọ́n rí Taha gẹ́gẹ́ bíi onímọ̀ gbajúgbajà ní ilẹ̀ South Africa.[5] Wọ́n fi oyè "ash-Shāfi‘ī as–Sagīr" dá a lọ́lá (Al-Shafi'i kékeré) láti ọwọ́ Khalil Ibrahim Mula Khatir.[1] Ní ọdún 1996, Taha ṣe ìdásílẹ̀ Dar al-Uloom al-Arabiyyah al-Islamiyyah (DUAI) ní Strand, Western Cape.[2][6] Lábé ìṣàkóso rẹ̀,wọ́n ṣe ìdásílẹ̀ DUAI ti àwọn obìnrin ní ọdún 2016, ibẹ̀ sì ni Taha ti ṣe onímọ̀ràn fún àyàn iṣẹ́.[7] Taha rọ́pọ̀ bàbá rẹ̀, Yusuf Karaan gẹ́gẹ́ bíi olórí-mufti ti Muslim Judicial Council ní ọdún 2015.[3] Òun ni olùdásílè àti olùdarí Mahajjah Research Institute tí ó bẹ̀rẹ̀ láti gbèjà "Companions of the Prophet".[1] Ó kọ Fleeing from Fate to Fate: 40 Ahadith on Contagion and Pandemics.[1]
Ó kú ní ọjọ́ kọkànlá, oṣù kẹfà, ọdún 2021, látàri ìnira àjàkálẹ̀ àrùn COVID-19.[3] Àwọn onímọ̀-ìjìnlẹ̀ àti àwọn onímọ̀ òye ti Islam Abdur Rahman ibn Yusuf Mangera, Faraz Rabbani, Ismail ibn Musa Menk, Omar Suleiman àti Yasir Qadhi fi ìbanújẹ́ hàn lórí ikú rẹ̀ .[1]
Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ 1.0 1.1 1.2 1.3 1.4 1.5 1.6 "Muslim world at loss, Mufti Taha Karaan passes away". The Chenab Times. 12 June 2021. https://thechenabtimes.com/2021/06/12/muslim-world-at-loss-mufti-taha-karan-passes-away/.
- ↑ 2.0 2.1 "If Only Someone Else Said it, Mufti Taha Karaan of South Africa". Seekers Guidance. 11 August 2020. Retrieved 11 June 2021.
- ↑ 3.0 3.1 3.2 "MJC mufti Moulana Taha Karaan has died". News24. 11 June 2021. https://www.news24.com/news24/southafrica/news/mjc-mufti-moulana-taha-karaan-dies-20210611.
- ↑ "SA & Global Muslim Ummah Shattered by Passing of Great Islamic Scholar Mufti Taha Karaan". Radio Islam. 11 June 2021. https://www.radioislam.org.za/a/listen-global-muslim-ummah-shattered-by-passing-of-great-islamic-scholar-mufti-taha-karaan/.
- ↑ "Güney Afrikalı Müslüman Yargı Konseyi Müftüsü Karaan vefat etti" (in Turkish). Haberler. https://www.haberler.com/guney-afrikali-musluman-yargi-konseyi-muftusu-14194412-haberi/.
- ↑ Lo, Mbaye; Haron, Muhammed (26 January 2016). Muslim Institutions of Higher Education in Postcolonial Africa. ISBN 978-1-137-55231-0. https://books.google.com/books?id=8kLvCgAAQBAJ&q=taha+karaan&pg=PT83. Retrieved 11 June 2021.
- ↑ Database of Sanad holders in the Quran 2019-2020 (8 ed.). Western Cape: Al-Tanzīl Institute of Quranic Sciences. 2019. pp. 381, 705. https://al-tanzil.co.za/al-tanzil-database-2019-2020/. Retrieved 2 July 2021.