Jump to content

Taiwo Kola-Ogunlade

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Taiwo Kola-Ogunlade
Taiwo Kola-Ogunlade

Taiwo Kola-Ogunlade jẹ́ akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí ó ní ìmọ̀ nípa ìbáraẹnisọ̀rọ̀. Lọ́wọ́lọ́wọ́, oun ni olùṣàkóso ti Ìbáraẹnisọ̀rọ̀ àti ọ̀rọ̀ ìlú fún ilé iṣẹ́ ayélujára Google ti ìla òòrùn Áfíríkà.[1]

Kọ́lá-Ògúnlàdé gba oyè láti ilé-ẹ̀kọ́ gíga Yunifásítì Ìpínlẹ̀ ÈkóNàìjíríà lórí i Biochemistry ní ọdún 2001. Ní ọdún 2013, ó gba oyè lórí ìṣàkóso ìṣòwò(MBA) láti ilé-ẹ̀kọ́ gíga Yunifásítì yìí kanna. Ó ti ṣiṣẹ́ bí aláàkóso olùṣirò owó, ọ̀gá àgbà aláàkóso olùṣirò owó àti ọ̀gá àgbà pátápátá gẹ́gẹ́ bí olùṣirò owó ní Insight Gray (ilé iṣẹ́ tí wọ́n ńpè ní Insight Publisis lọ́wọ́lọ́wọ́ bayi) èyí tí ó jẹ́ àwọn ilé-iṣẹ́ ìbáraẹnisọ̀rọ̀ tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ jáde kúrò ní Ìpínlẹ̀ Èkó, orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Ní oṣù kejìlá ọdún 2011, Kọ́lá-Ògúnlàdé bẹ̀rẹ̀ síní kó ipa kan ní ilé-iṣẹ́ Google gẹ́gẹ́ bíi olórí fún àwọn ètò nípa ìbáraẹnisọ̀rọ̀ àti àwọn ọ̀rọ̀ tí ó jẹmọ́ àwùjọ fún apá ìwọ̀-oorun Áfíríkà. Kọ́lá jẹ́ agbenusọ fún ilé-iṣẹ́ ẹ rẹ̀ lórí ìṣàkóso àwọn ohun ìbáraẹnisọ̀rọ̀ àti lílọ́wọ́sí onírúurú media ní ìta àti nípa ìkọ́ ẹ̀kọ́,[2][3][4][5] àti ṣíṣe àtìlẹ́yìn fún àwọn yàrá ìròyìn ní ilẹ̀ Áfíríkà láti ṣàfihàn àwọn media tuntun àti àwọn ìmọ̀ràn oríi ayélujára sínú àwọn ìròyìn.[6][7]

Kọ́lá-Ògúnlàdé jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ ti ìgbìmọ̀ ìwáìdí nípa ìròyìn àwùjọ ti media ní Nàìjíríà látipasẹ̀ ilé-iṣẹ́ àjùmọ̀sọ̀rọ̀ ti Alder ní ọdún 2013.[8] Ní ọdún 2017, òun ni olórí fún ìpèníjà ilẹ̀ Áfíríkà tuntun àti ṣíṣẹ àtìlẹ́yìn fún iṣẹ́ ìròyìn ti ìgbàlódé, ìjábọ̀ ìwáìdí àti lílo àwọn ẹ̀rọ ayárabíàsá ní àwọn yàrá ìròyìn àti ìgbóhùn sí afẹ́fẹ́ ní Áfíríkà.[9]

Ní ọdún 2016, wọ́n dìbò yan Kọ́lá-Ògúnlàdé gẹ́gẹ́ bíi ọ̀kan lára ọgọ́rùn ún àwọn gbajúmọ̀ ọ̀dọ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.[10]

Àwọn Ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. "Science geek goes to Google". Grocott's Mail. 2014-09-10. Retrieved 2021-08-02. 
  2. "Google WiFi: Computer Village traders lament low internet activities". Premium Times Nigeria. 2019-09-04. Retrieved 2021-08-02. 
  3. "Taiwo Kola-Ogunlade's schedule for Social Media Week Lagos 2019". Social Media Week Lagos 2019. 2013-12-17. Retrieved 2021-08-02. 
  4. Frank, Mercy; Frank/, Mercy (2017-03-27). "Google Visits TINK". TINK. Archived from the original on 2021-08-02. Retrieved 2021-08-02. 
  5. "Kola-ogunlade, Akpokabayen Headline O2 Academy Lagos Saturday Class". BrandArena. Retrieved 2021-08-02. 
  6. Gbonegun, Victor (2019-05-14). "Google trains practitioners on digital tools for reporting - Nigeria and World News". The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News. Archived from the original on 2021-08-02. Retrieved 2021-08-02. 
  7. "Google Nigeria Trains Practitioners On Google Tools For Data Journalism". BrandCrunch Nigeria. 2019-05-14. Retrieved 2021-08-02. 
  8. "AlderSMR Panel". Alder Consulting. 2019-05-07. Retrieved 2021-08-02. 
  9. "Judges". innovateAFRICA. Retrieved 2021-08-02. 
  10. "Most Influential Young Nigerians » Homepage". Most Influential Young Nigerians. 2015-01-16. Archived from the original on 2023-03-09. Retrieved 2021-08-02.