Tam David-West

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Tamunoemi Sokari David-West tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Tam David-West (ni a bí ní Ọjọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n oṣù kẹjọ ọdún 1936 tí ó sì kú ní ọjọ́ kọkànlá oṣù kọkànlá ọdún 2019) jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n àti mínísítà-ana. Ọ̀jọ̀gbọ́n yìí ṣaláìsí ní ọjọ́ kọkànlá oṣù kọkànlá ọdún 2019.[1] Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ló dárò ikú rẹ̀, pàápàá jùlọ Ààre Muhammadu Buhari

Ibi Tí A Bí í Sí Àti Ìlàkàkà Ẹ̀kọ́ Kíkà Rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

A bí Ọ̀jọ̀gbọ́n Tam David-West ní Buguma, Kalabari ní ìpínlè Rivers lórílẹ̀ - èdè Nàìjíríà. Ó kàwé gboyè ní Ifáfitì ìlú Ìbàdàn (University of Ibadan) lọ́dún 1956 sí 1958, Ifáfitì Michigan State University lókè-òkun lọ́dún 1958–1960, ó kàwé gboyè MSc degree ní Yale University lọ́dún 1960–1962, lọ́dún 1964 sì 1966, ó kàwé gboyè Ọ̀mọ́wé (PhD degree) ní McGill University.[2]

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]