Tariro Mnangagwa
Tariro Mnangagwa | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | Tariro Washe Mnangagwa 1986 Zambia |
Orílẹ̀-èdè | Zimbabwean |
Iléẹ̀kọ́ gíga | Cape Peninsula University of Technology |
Iṣẹ́ | Actress, film producer, social activist |
Ìgbà iṣẹ́ | 2018–present |
Parents |
|
Tariro Washe Mnangagwa (tí wọ́n bí ní ọdún 1986) jẹ́ òṣèrébìnrin ọmọ orílẹ̀-èdè Sìmbábúè.[1] Ó gbajúmọ̀ jùlọ fún ipa rẹ̀ tí ó kó nínu eré kan ti ọdún 2020 tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Gonarezhou. Ó jẹ́ ọ̀kan nínu àwọn ọmọ obìnrin Ààrẹ orílẹ̀-èdè Sìmbábúè lọ́wọ́lọ́wọ́ ti orúkọ rẹ̀ n ṣe Emmerson Mnangagwa.
Ọ̀rọ̀ ayé rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Wọ́n bí Tariro ní ọdún 1986 ní orílẹ̀-èdè Sámbíà. Òun ni ọmọ obìnrin àbígbẹ̀yìn nínu àwọn ọmọ mẹ́fà ti àwọn òbí rẹ̀. Bàbá rẹ̀ ni Ààrẹ orílẹ̀-èdè Sìmbábúè lọ́wọ́lọ́wọ́. Ìyá rẹ̀ tí orúkọ rẹ̀ n ṣe Jayne Matarise di olóògbè ní 31 Oṣù Kínní, Ọdún 2002 látàrí ààrùn jẹjẹrẹ kan. Tariro ní àwọn ọmọìyá márùn-ún tí wọ́n ṣe: Farai, Tasiwa, Vimbayi, Tapiwa, àti Emmerson Tanaka. Lẹ́hìnwá ikú ìyá rẹ̀, bàbá rẹ̀ fẹ́ Auxillia Kutyauripo tí òun náà síì ti ní ọmọ mẹ́ta: Emmerson Jr. àti àwọn ìbejì tí wọ́n ṣe Sean àti Collins.[2]
Iṣẹ́ ìṣe rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Tariro gba oyè-ẹ̀kọ́ nínu ìmọ̀ fọ́tòyíyà láti ilé-ẹ̀kọ́ gíga kan tí ó wà ní ìlú Cape Town. Ó tún gba oyè-ẹ̀kọ́ míràn nínu ìmọ̀ ìṣàkóṣo eré ìdárayá láti ilé-ẹ̀kọ́ gígaCape Peninsula University of Technology. Lẹ́hìn tí ó padà sí orílẹ̀-èdè Sìmbábúè, Tariro darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ Akashinga, ẹgbẹ́ kan tí ó n rí sí dídáàbò bo àwọn ẹranko orí-ilẹ̀ àti inú-omi àti láti tako dídẹdẹ àwọn ẹranko náà lọ́nà àìtọ́. Ó padà tún darapọ̀ mọ́ irúfẹ̀ ẹgbẹ́ náà ti àgbáyé, èyí tí wọ́n pè ní International Anti-Poaching Foundation.[3][4]
Láìpẹ́ jọjọ sí dídarapọ̀ rẹ̀ mọ́ ẹgbẹ́ àgbáyẹ́ náà, wọ́n pèé láti wá kópa nínu eré tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Gonarezhou, èyí tí olùdarí eré Sydney Taivavashe ṣe,[5] tí Ààjọ Zimbabwe Parks and Wildlife Management Authority síì ṣe onígbọ̀wọ́ rẹ̀.[6] Tariro kópa gẹ́gẹ́ bi 'Sergeant Onai' nínu eré náà.[7]
Àṣàyàn àwọn eré rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]ọdún | Àkọ́lé eré | Ipa | Irúfẹ̀ | Ìtọ́kasí |
---|---|---|---|---|
2020 | Gonarezhou | Sergeant Onai | Fiimu |
Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "Like Father Like Daughter……Meet ED's Youngest Daughter". iharare. Retrieved 19 October 2020.
- ↑ Phiri, Gift (2018-03-23). "Mnangagwa family disclosures raise eyebrows". Nehanda Radio (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2020-04-03.
- ↑ "All female anti-poaching combat unit". theguardian. Retrieved 19 October 2020.
- ↑ "Zimbabwe: Mnangagwa Daughter Joins Elite Anti-Poaching Unit". allafrica. Retrieved 19 October 2020.
- ↑ "President Emmerson Mnangagwa's Daughter Tariro To Feature In An Anti-Poaching Film". pindula. Retrieved 19 October 2020.
- ↑ comments, Blessing Masakadza • 2 October 2018 1:59PM • 0. "ED's daughter in anti-poaching film". DailyNews Live. Archived from the original on 2020-10-20. Retrieved 2019-03-27.
- ↑ "Mnangagwa's daughter in anti-poaching film". Bulawayo24 News. Archived from the original on 2020-11-01. Retrieved 2019-03-27.