Jump to content

Tehzeeb-e-Niswan

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Tehzeeb-e-Niswan (Ni Èdè Urdu: تہذیبِ نسواں) jẹ iwe irohin ti ẹsin musulumi ọsọsẹ fun awọn óbinrin ti Sayyid Mumtaz Ali ati iyawoó rẹ Muhammadi Begum da kalẹ ni ọdun 1898. Èyi jẹ iṣẹ akọkọ to da lori ẹtọ awọn óbinrin ni islam[1]. Wọn tẹ jade lati ilẹ Lahore ni aarin ọdun 1898 ati 1949.

Ìtan Tehzeeb-e-Niswan

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Syed Ahmad Khan sọ Tehzeeb-e-Niswan lórukọ. Iwè iroyin nipa ẹtọ awọn óbinrin bẹrẹ lati ọdọ Sayyid Mumtaz Ali ati iyawó rẹ Muhammadi Begum ni ọdun 1898[2]. Issue rẹ akọkọ ni wọn tẹ jade ni ọjọ akọkọ, óṣu july, ọdun 1898, o bẹrẹ pẹlu awẹ mẹjọ, mẹwa lẹyin naa ni awẹ mẹ̀rin dinlogun[3][4].

Iyawò Mumtaz Ali jẹ akọkọ alatunkọ fun Tehzeeb-e-Niswan, lẹyin iku rẹ ọmọbirin rẹ, Waheeda Begum ṣatunkọ iwè iroyin naa[2]. Ọmọkunrin Mumtaz, Imtiaz Ali Taj ati awọn ónimimọ bi Majeed Salik ati Ahmad Nadeem Qasmi ṣatunkọ iwè iroyin naa[5].

Iwè royin naa ti ṣè iranlọwọ fun ọpọlọpọ awọn akọwè lóbinrin lati lokiki. Ninu iwadi akọle Ijagbara fun óbinrin ninu Akèwi Urdu Igbalódè, Ambreen Salahuddin kọ pe lati ibẹrẹ iwè iroyin naa ni awọn óbinrin ti kọ ayọka lori inakuna ati óhun àsan nipa ówó ori[6].

Gẹgẹbi Gail Minault, Tehzeeb-e-Niswan ni alabapin bi ọgọta si ààdọrin lẹyin óṣu Mẹta si mẹrin. Lẹyin ọdun mẹrin, awọn alabapin naa lẹkun pẹ̀lu ọ́ọ̀dúnrún si irinwó[7]. Ni ọdun 1949, iwè royin naa ṣiwọ iṣẹ[5].

Ónimọ itan ilẹ Pakistan, Ghulam Rasool yin Mumtaz Ali fun Tehzeeb-e-Niswan;

Awọn ọmọbinrin idilè musulumi lati Peshawar de Kanyakumari ti wọn nimọ nipa kika ati kikọ dupẹ gidi gan lọwọ Shams al-Ulama Mawlāna Mumtaz Ali fun iṣẹ takun takun lori fifi ẹ̀mi rẹ lelẹ̀ lori ẹkọ awọn óbinrin. Ti arakunrin naa ba gbayinju lati ṣiṣẹ ninu ẹ̀sin abi óṣèlu, yoo jẹ̀ ólóri to ṣè muyangan ni órilẹ ede ṣugbon eyi o bà ti mu ifàsẹyin ba ètó ẹkọ to ri ko si ẹni to tun dara ni ilana na ju Mawlāna lọ[5].

  1. Moaddel, Mansoor (1998). "Religion and Women: Islamic Modernism versus Fundamentalism". Journal for the Scientific Study of Religion 37 (1): 116. doi:10.2307/1388032. JSTOR 1388032. 
  2. 2.0 2.1 Kamran, Tahir (2018-07-08). "Re-imagining of Muslim Women - II". thenews.com.pk. Retrieved 2023-09-14. 
  3. Joseph, S.; Najmabadi, A. (2003). Encyclopedia of Women & Islamic Cultures. Encyclopedia of Women & Islamic Cultures. Brill. ISBN 978-90-04-13247-4. https://books.google.com.ng/books?id=rv0iAQAAIAAJ. Retrieved 2023-09-14. 
  4. Jones, K.W. (1992). Religious Controversy in British India: Dialogues in South Asian Languages. SUNY series in religious studies. State University of New York Press. p. 183. ISBN 978-0-7914-0827-8. https://books.google.com.ng/books?id=EmY9fsUTjwYC&pg=PA183. Retrieved 2023-09-14. 
  5. 5.0 5.1 5.2 Nayab Hasan Qasmi. "Mawlāna Sayyid Mumtaz Ali Deobandi". Darul Uloom Deoband Ka Sahafati ManzarNama. Idara Tehqeeq-e-Islami, Deoband. pp. 147–151. 
  6. "The Role of Female Writers in the Promotion of Popular Literature in Urdu". PUTAJ – Humanities and Social Sciences (Peshawar University Teachers’ Association) 23 (2). http://journals.uop.edu.pk/papers/55-61.%20Faiza%20Bashir-The%20Role%20of%20Female%20Writers%20in%20the%20Promotion%20of%20Popular.pdf. 
  7. Kenneth W. Jones (1992). Religious Controversy in British India Dialogues in South Asian Languages. State University of New York Press. p. 191. ISBN 9780791408278. https://books.google.com/books?id=EmY9fsUTjwYC&dq=mumtaz+ali+deobandi&pg=PA183. Retrieved 22 August 2020.