Tejitu Daba
Tejitu Daba Chalchissa ni a bini ọjọ ogun, óṣu August, ọdun 1991 jẹ elere sisa lobinrin to ṣoju fun Bahrain[1][2][3]. Daba gba ami ẹyẹ ti ọla ti wura ninu idije ti ilẹ asia ere sisa ni ọdun 2011.
Àṣèyọri
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Tejitu kopa ninu idije agbaye ti IAAF ni ọdun 2009. Ni óṣu October, ọdun 2009, Daba yege ninu ere inu ile ti ilẹ Asia to si gba ami ẹyẹ ti wura metres ti ẹ̀gbẹrun mẹta. Tejitu kopa ninu idije to si ṣoju fun Bahrain ni metres ni ẹgbẹrun mẹwa to si gbe ipo kẹrin[4]. Ni ọdun 2010, Tejitu kopa ninu idije agbaye to si jẹ ọkan lara awọn mẹwa to pegede ninu ere ti junior. Ni ọdun 2011, Daba kopa ninu idije agbaye ninu ere sisa pẹlu ipo kẹsan ni wakati 15:14.62. Ni ọdun 2011, Tejitu yege ninu ere ilẹ Arab ni metres ti ẹgbẹrun mẹwa[5]. Tejitu gba ami ẹyẹ ti idẹ ninu idije ere sisa ti inu ile ti ilẹ Asia ni ọdun 2012 lori metres ti ẹgbẹrun mẹta.