Terence Stamp
Terence Stamp | |
---|---|
Stamp ní ọdún 2009 | |
Ọjọ́ìbí | Terence Henry Stamp 22 Oṣù Keje 1938 Stepney, London, England |
Iléẹ̀kọ́ gíga | Webber Douglas Academy of Dramatic Art |
Iṣẹ́ | Actor |
Ìgbà iṣẹ́ | 1960–present |
Olólùfẹ́ | Elizabeth O'Rourke (m. 2002; div. 2008) |
Àwọn olùbátan | Chris Stamp (brother) |
Terence Henry Stamp (tí a bí ní ọjọ́ kejìlélógún oṣù keje ọdún )[1][2] jẹ́ òṣèré ọmọ orílẹ̀ èdè Britain. Ó gbajúmọ̀ fún ipa rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi alátakò nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ eré. Ó gba àmì-ẹ̀yẹ Golden Globe Award,[3] Cannes Film Festival, àti Silver Bear wọ́n sì yán kún ara àwọn tí ó tó fún àmì-ẹ̀yẹ Academy Award àti BAFTA Awards méjì.
Lẹ́yìn ìgbà tí ó kó ẹ̀kọ́ gboyè ní ilé ẹ̀kọ́ eré Webber Douglas Academy of Dramatic Art ní London, ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òṣèré ní ọdún 1962. Fíìmù àkọ́kọ́ rẹ̀, mú kí ó gba àmì-ẹ̀yẹ Academy Award àti BAFTA fún Best Newcomer. Ó ṣeré pẹ̀lú òṣèré Christie nínú eré Far from the Madding Crowd (1967).
Ọ́ tún gbajúmọ̀ sí nígbà tí ó kó ipa General Zod nínú eré Superman (1978) àti Superman II (1980). Ipa rẹ̀ nínú eré The Adventures of Priscilla, Queen of the Desert (1994) mú kí ó gba àmì-ẹ̀yẹ BAFTA Award ó sì tún mú kí wọ́n yán mó ara àwọn tí ó tó sí àmì ẹyẹ Golden Globe Award. Lẹ́yìn èyí, ó ṣeré nínú eré The Limey (1999) èyí tí ó sì gba àmì-ẹ̀yẹ Independent Spirit Award fún. Àwọn fíìmù míràn tí ó ti ṣeré ni Star Wars: Episode I – The Phantom Menace (1999), The Haunted Mansion (2003), Elektra (2005), Wanted (2008), Get Smart (2008), Yes Man (2008), Valkyrie (2008), Big Eyes (2014) àti Last Night in Soho (2021).
Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "Index entry". FreeBMD. ONS. Retrieved 15 February 2011.
- ↑ "Terence Stamp Biography (1938?-)". FilmReference.com. Retrieved 30 September 2010.
- ↑ Terence Stamp: 2 Nominations, 1 Win. Golden Globe Awards.