Thérèse Sita-Bella
Thérèse Sita-Bella | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | Thérèse Bella Mbida 1933 |
Aláìsí | 27 February 2006 Yaoundé |
Orílẹ̀-èdè | Cameroonian |
Ọmọ orílẹ̀-èdè | Cameroonian |
Iṣẹ́ | Film director |
Thérèse Sita-Bella (tí wọ́n bí ọdún 1933, tó sì kú ní ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n oṣù kejì ọdún 2006), tí orúkọ àbísọ rẹ̀ ń jẹ́ Thérèse Bella Mbida, jẹ́ olùdarí fíìmù ilẹ̀ Cameroon, tó padà di aṣagbátẹrù fíìmù ilẹ̀ Áfíríkà.
Ìgbésí ayé àti ètò ẹ̀kọ́ rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Wọ́n bí i sí ẹ̀yà Beti ní ìhà Gúúsù ilẹ̀ Cameroon, ó sì gba ẹ̀kọ́ rẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ajíhìnrere ìjọ Catholic. Ní ọdún 1950 síwájú, lẹ́yìn tí ó gboyè ẹ̀kọ́ baccalaureate láti ilé-ìwé kan ní olú-ìlú Cameroon, ìyẹn Yaoundé, ó lọ sí Paris láti lè tẹ̀síwájú nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀. Ìlú Faranse ni ìfẹ́ rẹ̀ sí ìròyìn kíkọ àti fíìmù ṣíṣe ti bẹ̀rẹ̀.
Iṣẹ́ rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ní ọdún 1955, Sita-Bella bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí i akọ̀ròyìn.[1] Lẹ́yìn náà, ní 1963, Sita-Bella di obìnrin àkọ́kọ́ tí ó ṣe fíìmù ní Cameroon àti ní gbogbo ilẹ̀ Áfíríkà. [2] Láti ọdún 1964 wọ 1965, Sita-Bella ṣiṣẹ́ ní Faranse, ní ilé ìwé-ìròyìn La Vie Africane, tí òun náà jẹ́ ọ̀kan lára àwọn olùdásílẹ̀. Lẹ́yìn tó padà sí orílẹ̀-èdè Cameroon ní ọdún 1967, ó dara pọ̀ mọ́ ẹ̀ka tó ń bójú tó ìròyìn, ó sì di igbákejì ọ̀gá ìròyìn. [1]
Tam Tam à Paris
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ní ọdún 1963, Sita-Bella ṣe olùdarí fíìmù Tam-Tam à Paris, tó tẹ̀lé ẹgbẹ́ kan láti Cameroon National Ensemble lásìkò ìrìn-àjò ti Paris.[2] Ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn máa sọ pé Tam Tam à Paris jẹ́ fíìmù àkọ́kọ́ tí obìnrin ilẹ̀ Áfíríkà ṣe.[3] Ní ọdún 1969, Tam Tam à Paris ṣàfihàn nínú ọ̀sẹ̀ àkọ́kọ́ ti African Cinema, tó wá padà di FESPACO.[4]
Sita-Bella wà lára àwọn obìnrin tó ṣịṣẹ́ ní àwọn ilé-iṣẹ́ fíìmù tí ọkùnrin pọ̀.[5] Ó sọ̀rọ̀ nípa àwọn ilé-iṣẹ́ fíìmù ti ọdún 1970, tó sì sọ pé:
Ikú rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ní ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n ọdún 2006, Sita-Bella kú sí ilé-ìwòsàn kan ní Yaoundé látàri àìsàn jẹjẹrẹ.[6] Wọ́n sin ín sí ibi ìsìnkú Mvolye ní Yaoundé.[7]
Ìdálọ́lá
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Wọ́n fi orúkọ rẹ̀ sọ gbọ̀ngàn fíìmù Sita Bella ní Cameroon Cultural Centre.[8]
Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ 1.0 1.1 Pouya, André Marie (September 1989). "Interview with Thérèse Sita-Bella". Amina 233.
- ↑ 2.0 2.1 Tchouaffé, Olivier Jean (2012). "Women in Film in Cameroon: Thérèse Sita-Bella, Florence Ayisi, Oswalde Lewat and Josephine Ndagnou". Journal of African Cinemas 4 (2): 191–206. doi:10.1386/jac.4.2.191_1. Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid
<ref>
tag; name "africancinemas" defined multiple times with different content - ↑ "Recovering Lost African Film Classics". africa-in-motion.org.uk. Archived from the original on 17 October 2008. Retrieved 10 November 2016.
- ↑ African Women and the Documentary: Storytelling, Visualizing History, from the Personal to the Political. https://muse.jhu.edu/article/634992. Retrieved 10 November 2016.
- {{Closed access}} vs. {{Open access}} to display a symbol to indicate that a publication is or is not available under open access and is or is not behind a paywall
- {{Link note}}
- {{Subscription or libraries}} to add when a subscription may be required or content may be at a library
- {{Password-protected}}
- {{Registration required}} to flag an external link that requires free registration
- {{Subscription or membership required}} to flag an external link that requires subscription or UK library membership
- {{Subscription required}} to flag an external link that requires subscription
- ↑ Tande, Dibussi. "Sita Bella: The Final Journey of a Renaissance Woman". dibussi.com. Retrieved 10 November 2016.
- ↑ "Cameroon's first woman journalist dies". nation.com.pk. Archived from the original on 17 March 2008. Retrieved 10 November 2016.
- ↑ Tande, Dibussi. "Sita Bella: The Final Journey of a Renaissance Woman". dibussi.com. Retrieved 10 November 2016.
- ↑ Anchunda, Benly. "Cameroon Cultural Centre gets face lift". crtv.cm. Retrieved 24 November 2016.