The AP 42 Compilation of Air Pollutants emission factors
(The AP 42 Compilation of Air Pollutant Emission) Factorsàtòpọ̀ àwọn ohun ìṣokùnfà ìtúsóde afẹ́fẹ́ ìdọ̀tí náà jẹ́ àwọn àjọ tó ń dáàbò àti mójútó àgbègbè ti orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà (EPA). Ìròyìn Ohun Ìtúsóde lórí ìdọ̀tí afẹ́fẹ́, àtẹ̀jáde àkọ́kọ́ ní ọdún 1968. Títí di 2018[update], apá tó kẹ́yìn ni apá karùn-ún láti ọdún 2010.
Ìtàn
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]AP 42 àtòpọ̀ àwọn ohun ìṣokùnfà ìtúsóde afẹ́fẹ́ ìdọ̀tí náà (The AP 42 Compilation of Air Pollutant Emission Factors) jẹ́ àtòpọ̀ àwọn ohun ìṣokùnfà ìtúsóde àwọn afẹ́fẹ́ ìdọ̀tí, ní iye àwọn ọ̀rọ̀ tí ó ṣàfihàn iye ìdọ̀tí tí wọ́n tú sáfẹ́fẹ́ pẹ̀lú ìṣe nǹkan kan ní pàtó. Àtòpọ̀ yìí ni wọ́n kọ́kọ́ ṣe tí àwọn elétò ìlera ti orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà sì tẹ̀jáde ní ọdún 1968. Ní ọdún 1972, wọ́n dáa padà wọ́n sì tun gbé jáde gẹ́gẹ́ bí apá kejì látọwọ́ àwọn àjọ tó ń dáàbò àti mójútó àgbègbè ti orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà (EPA). Ní ọdún 1985, apá kẹrin tí wọ́n ṣe lẹ́yìn èyí pín sí fọ́lúmù méjì: fọ́lúmù Kínní ní wọ́n ti ṣàfikún ọ̀gangan àti agbègbè ojú àwọn ohun ìtúsóde, àti fọ́lúmù kejì ṣàfikún ojú àwọn ohun ìtúsóde alágbèéká. Fọ́lúmù Kínní lọ́wọ́ lọ́wọ́ báyìí wà nínú apá karùn-ún àtẹ̀jáde ó sì wà lórí ẹ̀rọ ayélujára.[1] Wọn ò mójútó fọ́lúmù kejì báyẹn mọ́, àmọ́ lílo ẹ̀bá-ọ̀nà láti fi ṣègbéléwọ̀n fún ìtúsóde àwọn ọkọ̀ lópòpónà àti láti arar àwọn ọkọ̀ tí wọn ò sí lópòpónà àti àwọn ohun èlò alágbèéká wà ní orí ẹ̀rọ ayélujára.[2]
Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ EPA AP 42, Volume I Archived September 24, 2010, at the Wayback Machine.
- ↑ EPA Mobile source emission models Archived May 13, 2016, at the Wayback Machine.