Jump to content

Tíátà

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
(Àtúnjúwe láti Theatre)
Tíátà
Gbangan Tiata

Tíátà jẹ́ ọ̀rọ̀ tí ó wáyé lati inú èdè Gíríìkì tí o túmọ̀ sí ibì ìwòran ó sì tún ní ẹ̀ka bí eré ìtàgé tí ó túnmọ̀ sí pé, nígbàtí ènìyàn kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ bá kó ara wọn jọ ní àkókò kan tábì sí ìbìkan láti dá àwọn ènìyàn lárayá. Nípa ìtúmọ̀ tí ó gbòòrò yí, lati ìgbà tí ènìyàn ti wà láyé ni tíátà ti wà to bẹ́ẹ̀ gẹ ti ó se sajejuwe ìgbé ayé ènìyàn nítorí Ìfé àwọn ènìyàn si ìtàn sísọ. Lati ipinlẹ̀ṣẹ̀ tíátà, ni ó ti ń mú orísiirísi àrà dání. A sì máa ń ló àwọn èròjà bi ọ̀rọ̀, ìṣesí, orin, ijọ́ àti ìwòran papọ̀ mọ́ eré ìtàgé sínú tíátà. Tíátà ayé ìsinsìnyí ni ó tún kún fún òtítọ bí ó tilẹ́ jẹ́ pé ó pín sí oríṣiiríṣi ọ̀nà.

Tíátà àkọ́kọ́ ní a se ní ẹ̀gbẹrún ọdún méjì sájú ikú Olúwa wa sẹ́yìn, ni ó jẹ́ eré ìtara nípa ilẹ̀ Ígíbítì ìgbanì. Ìtàn nípa Ọlọ́run órísírì ni wọ́n fi ń se tíátà ni ọdọdún lati sin Ọlọ́run ósírísì wọn yi títi di ìgbà yé ọ̀làjú, èyí wá fi hàn nípa ìbásepọ̀ tí ó wa láàrín tíátà àti ẹ̀sin.

Àwọn ará Gíríkì ìgbanì ni ó kókó ṣe àgbékalẹ̀ tíátà gẹ́gẹ́ bí ìṣe, wọ́n sì túnmọ̀ tíátà sí oríṣirí ọ̀nà bí eré ti adùn kẹ́yìn rẹ̀, eré ti ìbànújẹ́ kẹ́yìn rẹ̀ àti eré tí ó se àpèjúwe àwùjọ.

Ṣùgbọ́n láyé òde òní, tíátà ṣíṣe ti gba ìgbà ọ̀tun, tí à ń se sínú fánrán fún àgbéléwò àwọn ènìyàn fún ìgbádùn. Tíátà ṣíṣe ti wá da iṣẹ́ òòjọ́ àwọn kan lóde òní. Tíátà àṣà àti iṣe tí àwọn òsèrè máa ń lò latí ṣe ìgbélékè àṣà àti ìṣe tí ó ti dòkú, pàápàá ní ilẹ̀ Áfíríkà. Nípa tíátà ni a ti mọ̀ pàápàá ni ilẹ̀ Yorùbá àwọn àṣà ati iṣe wa, tí ó ti sọnù nítorí àṣà àti ìwà àwọn òyìnbó ti gba àṣà àti ìṣe wa lọ́wọ́ wa.

Ọ̀kan nínú ìṣọ̀rí tíátà ni, tíátà nípa àwùjọ àti òsèlú. Tíátà nípa àwùjọ nì àwọn eléré ìtàgé fi ń se ọ̀pọ̀lópọ̀ àyípadà sí àwọn àlébù àti kùdìẹ̀-kudiẹ tó kù nínú àwùjọ wa lónìí. Nípà tíátà ṣíṣe yálà nípa eré ìtàgé tàbí ti àgbéléwò ni àtúnṣe ti ń bá ọ̀pọ̀lọpọ̀ ayé tí ó wà ní ìkòríta ìríjú, tí wọn kó si mọ ohun tó yẹ lati ṣe. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ olósèlú ni bá tí sọ ayé di tàwọn nìkan, bí kò bá sí ti àwọn aléré ìtàgé tábì ti àgbéléwò tí óun pi ìwà ìbàjẹ́ wọn léde.

Tíátà tí ó ti wà lati bí ọ̀pọ̀ ọdún ṣẹ́yìn, ló ti gbá àtúnṣe nípa ìdàgbàsókè tí ó ti dé báa ní ayé òde òní. Tíátà ṣ̣iṣe yálà ti eré ìtàgé tàbí ti àgbéléwò ló wà fún ẹ̀kọ́, ìtọ́sọ́nà ati fún ìṣàtúnṣe àwùjọ tí a wà lónìí.Àwọn Ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]