Thelma Okoduwa

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Thelma Okoduwa
Ọjọ́ìbí9 Osu Kẹta
Orílẹ̀-èdèNaijiria
Ẹ̀kọ́University of Port Harcourt
Iṣẹ́Oṣere
Ìgbà iṣẹ́2000 di iwoyi

Thelma Okoduwa Ojiji (tí a bí ní Oṣù Kẹẹ̀ta Ọjọ́ Kẹẹ̀sán[1]) jẹ́ òṣèré ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ó rí yíyàn gẹ́gẹ́bi amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ òṣèré tí ó dára jùlọ ní ọdún 2012 níbi ayẹyẹ Africa Movie Academy Award.

Íṣẹ ìṣe rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Nínu ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò pẹ̀lú Ìwé ìròhìn Encomium, Thelma fi hàn pé òun wá sí ìdi-iṣẹ́ fíìmù nípasẹ̀ Chico Ejiro.[2] Ní ọdún 2017, ó ṣiṣẹ́ lẹ́gbẹ̀ẹ́ Norbert Young nínu fíìmù Aggregator.[3] Ó ti ṣe ìfihàn nínu ọ̀pọ̀lọpọ̀ eré tẹlifísọ̀nù tó fi mọ́ Tinsel, Beautiful Liars, Treasures, Spider àti Family Ties.[4] Ní ọdún 2012, ó kó ipa "Linda" nínu eré ìfẹ́ kan, Mr and Mrs.[5] Lẹ́hìn tí ó ṣe ìgbeyàwó, ó sọ di mímọ̀ wípé nígbàgbogbo ní ọkọ òun maá n ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn ipa tí òún ní láti ṣe nínu fíìmù, bí kò bá sì ti fọwọ́si, òun yóó kọ ṣíṣe irú ipa bẹ́ẹ̀.[6] Nínu ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò pẹ̀lú The Punch, ó tọ́ka sí Jọkẹ́ Silva àti Richard Mofe-Damijo gẹ́gẹ́ bi àwọn tí wọ́n maá n fún òun ní ìwúrí ní Nollywood. Ó tún tọ́ka sí ipa rẹ̀ bi "Àrinọlá Cardoso" nínu eré Hush ti Africa Magic kan láti jẹ́ ipa ìpèníjà jùlọ nínu iṣẹ́ rẹ̀[7]

Ìgbé ayé rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ará ìlú Uromi ni Thelma ní Ìpínlẹ̀ Ẹdó. Ó kẹ́ẹ̀kọ́ Ìmọ̀-ìjìnlẹ̀ Kọ̀mpútà láti ilé-ẹ̀kọ́ gíga Yunifásítì ìlú Port Harcourt.[8] Ó tún gba oyè-ẹ̀kọ́ ní eré ìtàgé láti ilé-ẹ̀kọ́ gíga kan náà.[9] Ní oṣù kẹẹ̀rin ọdún 2009, ó ṣe ìgbeyàwó pẹ̀lú Onya Ojiji.[10]

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. Empty citation (help) 
  2. Empty citation (help) 
  3. "I’m fully back to Nollywood’ -THELMA OJIJI". Encomium Magazine. March 22, 2015. Retrieved 2017-11-12. 
  4. "I’m fully back to Nollywood’ -THELMA OJIJI". Encomium Magazine. March 22, 2015. Retrieved 2017-11-12. 
  5. "I’m fully back to Nollywood’ -THELMA OJIJI". Encomium Magazine. March 22, 2015. Retrieved 2017-11-12. 
  6. "MR. & MRS.". Nollywood Reinvented. Retrieved 2017-11-12. 
  7. "My husband edits my scripts before I accept roles – Thelma Okoduwa". Vanguard. October 7, 2010. Retrieved 2017-11-12. 
  8. Empty citation (help) 
  9. "I’m fully back to Nollywood’ -THELMA OJIJI". Encomium Magazine. March 22, 2015. Retrieved 2017-11-12. 
  10. admin (September 18, 2016). "I left Nollywood to make babies – Thelma Okoduwa". The Punch. Retrieved 2017-11-12.