Tom Hiddleston
Tom Hiddleston | |
---|---|
Hiddleston ní San Diego Comic-Con ọdún 2017 | |
Ọjọ́ìbí | Thomas William Hiddleston 9 Oṣù Kejì 1981 London, England |
Ẹ̀kọ́ | Eton College |
Iléẹ̀kọ́ gíga | Pembroke College, Cambridge Royal Academy of Dramatic Art |
Iṣẹ́ | Actor |
Ìgbà iṣẹ́ | 2001–present |
Works | Performances |
Alábàálòpọ̀ | Zawe Ashton (2019–present; engaged) |
Àwọn ọmọ | 1 |
Awards | Full list |
Signature | |
Thomas William Hiddleston (tí a bí ní ọjọ́ kẹsàn-án oṣù kejì ọdun 1981)[1] jẹ́ òṣèré ọmọ orílẹ̀ èdè Britain. Ó gbajúmọ̀ káàkiri orílẹ̀ èdè nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí ń kópa gẹ́gẹ́ bi Loki nínú àwọn eré Marvel Cinematic Universe (MCU), ó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú Thor ní ọdún 2011, ó sì ti farahàn nínú àwọn eré mìíràn bi Avengers, Ant-Man and the Wasp: Quantumania tí ó jáde ní ọdún 2023, àti Loki tí ó jáde ní ọdún 2021.
Ó bẹ̀rẹ̀ sí ń ṣeré nínú àwọn fíìmù ní ere Joanna Hogg tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Unrelated (2007) àti nínúArchipelago (2010). Ní ọdún 2011, Hiddleston kópa F. Scott Fitzgerald nínú fíìmù Woody Allen tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ Midnight in Paris, àti ere Steven Spielberg tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ War Horse. Ní ọdún kan náà, ó gba àmì-ẹ̀yẹ Empire Award for Best Male Newcomer. Àwọn eré míràn tí ó ti kópa ni m Terence Davies' The Deep Blue Sea (2012), Jim Jarmusch's romantic vampire film Only Lovers Left Alive (2013) àti Guillermo del Toro's Crimson Peak (2015).
Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "Tom Hiddleston - Flair Magazine" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 2022-05-27. Retrieved 2022-03-19.