Jump to content

Tosin Oshinowo

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Tosin Oshinowo jẹ́ oníṣòwò, òṣèré, ayàwòrán-ilé orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.[1][2]

Àwòrán ilé-ìtajà ńlá ti Maryland to yà ni ó sọ ọ́ di ìlúmọ̀ọ́ká. Akẹ́kọ̀ọ́ gboyè ilé-ìwé Kingston College, ìlú London ni Tosin. Ó sì tẹ̀síwájú nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀ ni Bartlett School of Architecture. Ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ni Tosin ti ṣe ni ilẹ̀ yìí àti ní òkè-òkun ni ọdún 2012.[3][1]

Ní ọdún 2012, Tosin dá ilé-isẹ́ rẹ̀ CmDesign Atelier sílẹ̀.[4] Bẹ́è náà ni Tosin Oshinowo jẹ aláṣẹ àti olùdásílẹ̀ ilé-iṣẹ́ Ile ila (House of Lines).[5][6] Ní ọdún 2019, Oshinowo jẹyọ nínú ìwé orúkọ Polaris Visual Collaborative ṣe.

Ìfẹ́ Tosin sí ìyàwònrán-ilé kíkọ́ jẹyọ láti ara ohun ti o fẹran láti ìgbà èwe rẹ. Nínú ìfọ̀rọ̀-wáni-lẹ́nuwò pèlú Omenkaonline.com, Tosin ni àṣeyọrí òun nínú iṣẹ́ yíya àwòrán àti ìmọ̀ nípa yíya àwònrá ni ọmọ ọdún méjìlá, pẹ̀lú ìmọ̀ nípa ilé kíkọ́ ló mú òun yan iṣẹ́ ti òun n ṣe láàyò.[7]

Iṣẹ́ tó yàn láàyò

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Yíyàn tí Tosin yan iṣẹ́ àwòrán yíyà tí wà nínú rè láti ìgbà èwe rẹ̀. Nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan tí ó ṣe pẹ̀lú Omenkaonline.com, ó sọ ọ́ di mímọ̀ pé iṣẹ́ tí òun yàn láàyò wáyé nípa ṣíṣe àwárí ohun àtinúdá ara rẹ̀, àṣeyọrí rẹ̀ nínú isẹ́ technical drawing tí wọ́n ṣe ní ilé-ìwé girama, àti òye láti mọ̀ nípa yíya àwòrán nígbà tí ó sì kéré. Ó tún ní àǹfààní láti rí àwọn iṣẹ́ lọ́lọ́kan-ò-jọ̀kan, bíi ilé bàbá rẹ̀ tí wọ́n ń kọ́ nígbà kan.[8]

Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìgbáradì rẹ̀: London sí Rotterdam (2007–2009)

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ní kété tí ó parí ilé-ìwé girama, kí ó tó kúrò ní ìlú London, Tosin ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Skidmore Owning àti Merril's LLP ní London láàárín oṣù kẹfà sí oṣụ̀ kẹwàá, ọdún 2007, lẹ́yìn náà, ó lọ sí Metropolitan Architecture ní Rotterdam láti oṣù kìíní, ọdún 2008 sí oṣụ́ kìíní, ọdún 2009, níbẹ̀ ni ó ti wà lára ọ̀wọ́-ẹléni-mẹ́fà tó ń ṣe dìsáìnì afárá kẹrin ti Mainland, tí ó yẹ kí ó ṣe ìsopọ̀ Ajah àti Ikorodu, ní Ìpínlẹ̀ Èkó.[9][10]

James Cubitt Architects ní ìlú Nàìjíríà

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ní oṣù kìíní, ọdún 2009, lẹ́yìn ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tí ó gbà ní ìlú Europe àti ìgbáradì ọdún díẹ̀, Tosin padà sí ìlú Nàìjíríà, ó sì dara pọ̀ mọ́ James Cubitt Architects, níbi tí ó ti ṣiṣẹ́ lórí iṣẹ́ Nigerian Liquefied Natural Gas (NLNG) gẹ́gẹ́ bíi adarí ayàwòrán. Nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò tí ó ṣe pẹ̀lú Future Lagos' Ayo Denton, ó sọ ọ́ di mímọ̀ pé iṣẹ́ náà kọ́ òun, ó sì la ojú òun sí ìlọ́wọ́sí àwọn stakeholders nínú iṣẹ́ náà.[9] Tosin ṣiṣẹ́ pẹ̀lú James Cubitt fún ọdún mẹ́rin. Ní kété tí ó kúrò ní James Cubitt Architects, Tosin bẹ̀rẹ̀ ilé-iṣẹ́ tirẹ̀, CmDesign Atelier (cmD+A) ní ọdún 2012, ìṣẹ̀dálè yìí ló mú àbáwáyé dìsáìnì tí wọ́n ṣe fún Maryland Mall, ní Ìpínlẹ̀ Èkó [11] pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ mìírán ti ilé-iṣẹ́ náà ti ṣiṣé lórí.

Tosin Oshinowo ni olùdarí ètò Sho-n-Tell, èyí tó jẹ́ ètò alákànṣe ọlọ́dọọdún, tó máa ń fàyè sílè fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ University of Lagos, yàlá èyí tó ṣì ń kàwé lọ́wọ́ àti èyí tó ti kàwé tán, láti pín yàrá-ìyàwòrán pẹ̀lú àwọn ayàwòrán tó gbòógì. Èyí wà láti mú ìmọ̀ wọn gbòòrò si nípa ìṣínilójú sí iṣẹ́ àwọn àmọ̀dájú àárín wọn. Ètò náà wáyé láti ọdún 2009 títí wọ 2014[12]

Tosin Oshinowo ṣe ìdásílẹ̀ Ilé Ìlà (House of Lines) ní ọdún 2017, èyí tó jẹ́ ilé-iṣẹ́ tó ń rí sí ṣíṣẹ àwọn ẹ̀ṣọ́-ilé lóríṣiríṣi.[13][14]

Àwọn ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. 1.0 1.1 Daniel Azania (September 23, 2018). "Tosin Oshinowo: A Damsel In Men’s Structural World". The Guardian. Archived from the original on March 16, 2022. https://web.archive.org/web/20220316194945/https://guardian.ng/life/tosin-oshinowo-a-damsel-in-mens-structural-world/. Retrieved October 27, 2018. 
  2. "Tosin Oshinowo: Inspired to break the glass ceiling". Guardian Woman (The Guardian). June 4, 2016. 
  3. "Why MARYLAND Mall Was Painted Black, LAGOS Architect, TOSIN OSHINOWO Reveals | City People Magazine" (in en-US). City People Magazine. 2017-06-19. http://www.citypeopleonline.com/maryland-mall-painted-black-lagos-architect-tosin-oshinowo-reveals/. 
  4. "Why MARYLAND Mall Was Painted Black, LAGOS Architect, TOSIN OSHINOWO Reveals | City People Magazine" (in en-US). City People Magazine. 2017-06-19. http://www.citypeopleonline.com/maryland-mall-painted-black-lagos-architect-tosin-oshinowo-reveals/. 
  5. "WOMEN WE LOVE WEDNESDAYS: TOSIN OSHINOWO – TW Magazine Website" (in en-US). TW Magazine Website. 2016-10-05. Archived from the original on 2021-05-21. https://web.archive.org/web/20210521081701/https://twmagazine.net/tw-exclusive-interviews/women-we-love-wednesdays-tosin-oshinowo/. 
  6. "Adekunle Gold afrocentric for ilé Ilà Campaign – PM NEWS Nigeria" (in en-US). PM NEWS Nigeria. 2017-04-21. https://www.pmnewsnigeria.com/2017/04/21/adekunle-gold-afrocentric-ile-ila-campaign/. 
  7. "Here Are The Colorful Designs From 'Àdùnní Chair' Collection By Nigerian Furniture Brand, Ilé-Ilà With Chidinma Ekile – Glam Africa". www.glamafrica.com (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2018-03-30. Archived from the original on 2018-11-17. Retrieved 2018-05-28. 
  8. Enwonwu, Oliver (December 2016). "Breaking the Mould with Tosin Oshinowo-Omenka Online". www.omenkaonline.com (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 2021-05-16. Retrieved 2018-05-03. 
  9. 9.0 9.1 "FUTURE LAGOS | Interview with young architect Tosin Oshinowo | Future Cape Town". futurecapetown.com (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2018-05-16. 
  10. "Tosin Oshinowo: The architect through whose eyes Lagos is reinventing itself" (in en-US). The Nerve Africa. 2017-08-13. Archived from the original on 2019-07-26. https://web.archive.org/web/20190726174219/https://thenerveafrica.com/12289/tosin-oshinowo-the-architect-through-whose-eyes-lagos-is-reinventing-itself/. 
  11. "BUILT: THE MARYLAND MALL (A.K.A. THE BIG BLACK BOX) IN LAGOS BY CMD+A | livin spaces" (in en-US). livin spaces. 2016-07-01. https://www.livinspaces.net/projects/architecture/built-the-maryland-shopping-mall-in-ikeja-by-cmda/. 
  12. "WOMEN WE LOVE WEDNESDAYS: TOSIN OSHINOWO – TW Magazine Website" (in en-US). TW Magazine Website. 2016-10-05. Archived from the original on 2021-05-21. https://web.archive.org/web/20210521081701/https://twmagazine.net/tw-exclusive-interviews/women-we-love-wednesdays-tosin-oshinowo/. 
  13. "Adekunle Gold afrocentric for ilé Ilà Campaign – PM NEWS Nigeria" (in en-US). PM NEWS Nigeria. 2017-04-21. https://www.pmnewsnigeria.com/2017/04/21/adekunle-gold-afrocentric-ile-ila-campaign/. 
  14. "Here Are The Colorful Designs From 'Àdùnní Chair' Collection By Nigerian Furniture Brand, Ilé-Ilà With Chidinma Ekile – Glam Africa". www.glamafrica.com (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2018-03-30. Archived from the original on 2018-11-17. Retrieved 2018-05-28.