Jump to content

Tosyn Bucknor

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Tosyn Bucknor
Ọjọ́ìbíOlúwatósìn Bucknor
(1981-08-15)15 Oṣù Kẹjọ 1981
Ìpínlẹ̀ Èkó, Nigeria
Aláìsí19 November 2018(2018-11-19) (ọmọ ọdún 37)
Orúkọ mírànTosyn Bucknor
Iṣẹ́Agbòhùnsáfẹ́fẹ́
Òṣèrébìnrin
Ìgbà iṣẹ́2009–2018
Olólùfẹ́
Aurélien Boyer
(m. 2015–2018)

Olúwatósìn Bucknor tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Tosyn Bucknor tí wọ́n bí lọ́jọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún oṣù kẹjọ ọdún 1981,ó sìn ta téru nípàá lọ́jọ́ kọkàndínlógún oṣù kọkànlá ọdún 2018 (15 August 1981 – 19 November 2018), jẹ́ agbóhùnsáfẹ́fẹ́, Òṣèrébìnrin àti gbajúmọ̀ sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ lórí ìtàkùn abánidọ́rẹ̀ẹ́ ọmọ bíbí Ìpínlẹ̀ Èkó lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà .[1][2]

Ayé rẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n bí Tosyn sí ìdílé gbajúmọ̀ olórin, Ọ̀gbẹ́ni ṣẹ́gun Bucknor àti Ìyáàfin ṣọlá Bucknor. Inú ọkọ̀ ni wọ́n bí i sí lọ́jọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún oṣù kẹjọ ọdún 1981.[3] Ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ni gbajúgbajà abániṣètò ètò, Fúnkẹ́ Bucknor-Obruthe, Aláṣẹ àti olùdásílẹ̀ Zapphaire Events.

Tosyn kàwé ní Fountain Nursery and Primary School, Queens' College, Yaba, University of Lagos (LLB) àti the Nigerian Law School, ní ìpínlè Èkó. Ó sin ilẹ̀ baba rẹ̀, National Youth Service CorpsPort Harcourt, níbi tí ó ti kọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní Lítírésọ̀ èdè òyìnbó àti èdè Òyìnbó ní Archdeacon Crowther Memorial Girls' School, Elelenwo.

Ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rédíò pẹ̀lú Tee-A lórí ìkànnì Èkó 89.7fm, lẹ́yìn èyí, ó ṣiṣẹ́-kọ́ṣẹ́ (internship) ní Cool 96.9fm níbi tí ó ti ṣe atọ́kùn ètò Fun Hour Show on Saturdays. Nígbà ìsìnlù rẹ̀ lọ́dún 2009, Tosyn ni atọ́kùn ètò ààrọ̀ lórí ìkànnì rédíò 90.9fm. Òun nìkan ni atọ́kùn lórí ètò náà.

Ó ti gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ àmìn-ẹ̀yẹ, tí wọ́n sìn tún ti yàn án fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn mìíràn, lára wọn ni: Future Awards, ELOY Awards, Best of Nollywood awards àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Tosyn, nígbà ayé rẹ̀ jẹ́ olórin àti akọ̀wé orin ìgbàlódé. Àwo orin kan péré Pop Rock Soul and Jara ló gbé jáde.

Méjì nínú àwọn orin rẹ̀ ni wọn lò fún sinimá àgbéléwò kúkúrú Ìrètí. Ó kọrin, kọ̀wé orin àti ṣe akálẹ̀ orin gẹ́gẹ́ bí CON.tra.diction.

Tosyn ti bá àwọn gbajúmọ̀ olórin bíi Skales, Rooftop MCs àti Eva, Sess, Tintin, Coldflames, Dj Klem, Knighthouse, Micworx àti Cobhams ṣíṣe.

Tosyn tí ṣe atọ́kùn ètò tí ó pè ní Tosyns Buzz Live lórí ìkànnì Pulse TV ní gbogbo ọjọ́ Ẹ̀tì. Lára àwọn eré àti àwọn ètò tí ó ti kópa nínú Tẹlifíṣọ̀n ni:

  • Co-host 3Live Chicks
  • Television Correspondent for EbonyLife Television
  • Guest judge on Naija Sings Season 1
  • Guest judge on Project Fame West Africa Season 5
  • Judge on Boost Freestyle Reality Show Season 2
  • Mentor on Project Fame West Africa Season 2
  • Mentor on Project Fame West Africa Season 5
  • Judge on God's Kids Great Talent, City Of David, Redeemed Christian Church of God. 2012
  • Judge on Greensprings Pastoral Centre Talent Show (PC's Got Talent), Greensprings School, Lekki. 2012
  • Plays "Osa" on TINSEL, an MNET soap opera
  • Plays 'Jola' on 'Plus 234', a television drama series.

Tosyn tí kọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwé àti ìròyìn ìtakùrọ̀ lórí ìkànnì òníròyin àti Tẹlifíṣọ̀n ; lára wọn ni:

  • Series writer, '5ve' television series
  • Series writer, 'Apprentice Africa'
  • Series writer, 'Xtraconnect Gameshow'
  • Columnist for the Guardian on Sundays for the column, 'Strictly for the Young'
  • Columnist for Wedding Planner Magazine
  • Columnist for Exquisite Magazine
  • Series writer and Content Producer, 'Nigeria's Got Talent' Season 1
  • Columnist for www.thenetng.net (tosyns ten 10s)
  • Series contributor, "My Mum and I"
  • Series contributor, "Citi Sistas"
  • Series contributor, "About to Wed"
  • Writer Amstel Malta Box Office (seasons 2 to 5) and Voice Over narrator for Season 5
  • Website writer for Gulder Ultimate Search Season 3

Àwọn orin rẹ̀ tó gbajúmọ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  • ó kópa nínú Naijazz, Laff and Jamz, Swe Hip hop Valentine, Muson Jazz Festival, Trip City and Friends, My Groovy Valentine, Wax Lyrical, Inspiration Fm Family Festival, Fashion Show at Rehab, One Soul's Album Launch, Music For Soul at Ember Creek, Koffi's Green Zone ní Unilag, ONE MIC NAIJA August edition (Aug 28th)
  • Ó ti bá àwọn gbajúmọ̀ akọrin àti olóòtú orin bíi Rooftop MCs, Plumbline, Tintin, Ese Peters, Tee-Y Mix, Cobhams, Dj Klem, Coldflames, Eva, Sista Soul ṣíṣe pọ̀.
  • Kópa nínú orin Micworx Music E-mixes mixtape pẹ̀lú Darey, Ásà, Goldie àti àwọn mìíràn.

Àwọn ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]