Jump to content

Toyosi Akerele-Ogunsiji

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Toyosi Akerele-Ogunsiji
Ọjọ́ìbíToyosi Akerele
8 Oṣù Kọkànlá 1983 (1983-11-08) (ọmọ ọdún 41)
Lagos State, Nigeria
Iṣẹ́onisowo iṣowo
Websitetoyosi.ng

Toyosi Akerele-Ogunsiji (wọ́n bí Oluwatoyosi Akerele, ní ọjọ́ kẹ́jo oṣù kọkànlá ọdún 1983) Ó jẹ́ alákòóso àwọn olókoòwò-aládáni ti ìlu Nàìjíríà àti ọnímọ̀ nípa ìdàgbàsóke àwọn ènìyàn tí ọwọ́ ìja rẹ̀ lọ jákèjádò okoòwò-aládáni, ètò-ẹ̀kọ́, ìdàgbàsókè àwọn ọ̀dọ́ àti ìdarí ìlú. Ó jẹ́ olùdásílẹ̀ àti alákòóso àgbà ti Rise Networks, tí ó jẹ́ ilé-iṣẹ́ aládàáni àti tìjọba tí ó ń ṣètò ìrànlọ́wọ́ owó fún àwọn ọ̀dọ́ ní orílẹ̀-èdè Nàìjírííà.[1]

Ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ayé àti ètò-ẹ̀kọ́

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n bí Akerele-Ogunsiji sínú ẹbí James Ayodele àti Felicia Mopelola Akerele ní ìpínlẹ̀ Èkó, orílẹ̀-èdè Nàìjírííà. Ó lọ si ilé-ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ Ebun Oluwa Nursery and Primary School, ní Ọrẹgun ní ìpínlẹ̀ Èkó láti bẹ̀ ni ó ti darí sí Lagos State Model College Kankon ní Badagry, ní ìpínlẹ̀ Èkó fún abala kínní ẹ̀kọ́ oníwèé mẹ́wàa láti ọdún 1994 sí 1996 kí ó tó tẹ̀síwájú fún abala kejì ẹ̀kọ́ oníwèé mẹ́wàa ní Egbado College (tí ó ti di Yewa College) láti ọdún 1998 títí di oṣù kẹfà ọdún 2000 níbi tí ó ti ṣe ayẹyẹ ìkẹ́kọ̀ọ́ jáde gẹ́gẹ́ bí akẹ́kọ̀ọ́ tí ó peregedé jùlọ nínú ìdíje àròkọ tí àwọn ọwọ àwọn ilé-ẹ̀kọ́ Aionian ní ìpínlẹ̀ Ogun gbé kalẹ̀.[2]

Ó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè àmì-ẹ̀yẹ Second Class Upper Degree nínú ẹ̀kọ́-ìmọ Òfin ìlú ní Fáfitì Jos ní oṣù kẹ́rin ọdún 2007. Akerele-Ogunsiji jẹ́ Mason Fed Mid Career Master nínú ẹ̀kọ́ ìṣàkóso ìlú ọ̀wọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ jáde ti Fáfitì Harvard ilé-ẹ̀kó ìjọba Kennedy.[3]

Ní ọdún 2017, Akerele-Ogunsiji darí àjọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àgbáyé ti ilé-ẹ̀kó ìjọba Harvard Kennedy àti ilé-ẹ̀kọ́ gíga ti ìmọ̀-ẹ̀kọ́ Massachusetts (MIT) fún ìrìnàjò-ìmọ̀ ọlọ́sẹ̀ kan fún ìmọ̀-ọ̀tun àti sí àwọn ilé-iṣẹ́ ìjọba ní ìpínlẹ̀ Èkó, orílẹ̀-èdè Nàìjírííà. Ìrìnàjò náà ni wọ́n ṣe lálàyé wí pé ó jẹ́ ọ̀nà tòótọ́ láti fi àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àti gbogbo ẹ̀ka ìmọ̀ èkọ́ Harvard lápapọ̀ sójú-iṣé láti kẹ́kọ̀ọ́ síi nípa ìdàgbàsóke ìgbèríko àti ìmọ̀-tuntun, ìdíje nínú ètò ọrọ̀-ajé, ìjọba tiwantiwa àti àwọn ohun ìgbàlódé tó ń lọ nínú ètò ìṣèjọba ní ìpínlẹ̀ Èkó àti orílẹ̀-èdè Nàìjírííà."

Akerele-Ogunsiji dá Passnownow sílẹ̀ ní ọdún 2012 pẹ̀lú èròǹgbà láti máa ran àwọn aláìní lọ́wọ́ àti àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí wọn ò láàǹfàní sí lílo àwọn ohun èlò ẹ̀kọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ gíga, látoríi àwọn ẹ̀rọ alágbèéká. Òun náà ló dá Printmagicng sílẹ̀, iléeṣẹ́ tí ń tẹ nǹkan jáde tí wọ́n sì ń ṣiṣẹ́ fún wákàtí mẹ́rìnlélógún lówó tí ò ga ni lára lórí ẹ̀rọ ayélujára.[4][5]

Ní ọdún 2014, ó fẹ́ Adekunle Ogunsiji, onímọ̀ ẹ̀rọ, nínú ìgbeyàwó bòńkẹ́lẹ́ ní ilé ẹbí tí ó wà ní Ikeja, ní ìpínlẹ̀ Èkó.[6]

Àwọn àtẹ̀jáde[edit]

Akerele-Ogunsiji ti ní àtẹ̀jáde àwọn ìwé àti pépà lóríṣiríṣi tí ó ti kọ lórí ètò ìdarí, àwọn ọ̀dọ́ àti ìdàgbàsókè okoòwò, pẹ̀lú àtẹ̀jáde àwọn ìwé wọ̀nyí:

  • Strate-Tricks: strategies and tricks, the winning formula for emerging businesses[7]
  • We Have to Belong: Why the Poor Majority of my Rich Country cannot wait anymore tí wọ́n gbé jáde ní gbọ̀ngán àwọn adarí-ìlú, ní Harvard Kennedy School ní oṣù karùn-ún ọdún 2017.[8]

Wọ́n ṣàtẹ̀jáde àwọn àkọsílẹ̀ àti ìfọ̀rọ̀-wánilẹ́nuwò rẹ̀ nínú ìwé-ìròyìn The Nation, àti the Nigerian Guardian, The Punch àti This Day newspapers..

  1. Nsehe, Mfonobong. "The 20 Youngest Power Women In Africa 2014". Forbes. 
  2. "Meet Toyosi Rise-Akerele, The Nigerian Entrepreneur Endorsed By Michelle Obama". 4 May 2017. 
  3. Ayoola, Simbiat (3 May 2017). "Meet Nigerian lady Toyosi Akerele-Ogunsiji who graduated from Harvard Kennedy School alongside 40 exceptional women (photos)". 
  4. "Print Everything For Less With Print Magic • Connect Nigeria". www.connectnigeria.com. Archived from the original on 2019-07-24. Retrieved 2022-08-21. 
  5. "Inside PRINTMAGICNG.COM - Africa's Fast, Affordable, High Quality Online Printing Service - PRINTMAGIC". www.printmagicng.com. 31 May 2021. Archived from the original on 12 June 2018. Retrieved 21 August 2022. 
  6. Dede, Steve. "Toyosi Akerele: Inspirational Speaker Ties Knot In Secret Wedding" (in en-US). https://www.pulse.ng/entertainment/celebrities/toyosi-akerele-inspirational-speaker-ties-knot-in-secret-wedding-id3297471.html. 
  7. "Toyosi Akerele". www.africayouthawards.org. 
  8. "Our Team". risenetworks.org. Archived from the original on 2018-06-12. Retrieved 2022-08-21.