Tunde Nightingale
Earnest Olátúndé Thomas (Túndé Nightingale) je olorin ara Naijiria.
Gbajúmọ̀ olórin, ọmọ orílẹ́-èdè Nàìjíríà, Earnest Olátúndé Thomas, tí gbogbo èèyàn mọ̀ sí Túndé Nightingale tàbí The Western Nightingale jẹ́ oní gìtá àrà tó ń kọ ẹ̀yà orin jùjú ní èyí tó ṣe àwòkọ́ṣe irúfẹ́ orin ìbílẹ̀ ti Ọ̀gbẹ́ni Túndé King.
A bí Túndé Nightingale ní ọjọ́ Kẹwà nínú oṣù Kejìlá ọdún 1922 ní Ìlú Ibadan. Ó lọ sii Ilé Ẹ̀kọ́ ní Ìlú Èkó, ó jẹ́ Ológun, ó ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Ilé iṣẹ́ Reluwè. Ó da ẹgbẹ́ olórin tirẹ̀ silẹ̀ pẹ̀lú àwon ọmọ ẹgbẹ́ olórin mẹ́ta ati Irinṣẹ́ mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí a mọ̀ sí gìtá, tanborín-ìn àti ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀ ní ọdún 1944. Àsìkò yí ni àwọn olórin Nàìjíríà ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rè sí ń lo gìtá láti ṣe àkójọpọ̀ orin tí wọ́n bá fẹ́ gbe jáde. Ṣùgbón, irúfẹ́ orin jùjú rẹ̀ kò fi bẹ́ẹ̀ gbàjúmọ̀ lásìkò yí láàrín àwọn aláfẹ́ àti àwọn jayé-jayé nílù Èkó, amọ́ ṣà ó máa ń kọrin ní àwon ilé ìgbafè kéréje-kéréje, tí owó diẹ̀díẹ̀ sì wọlé fún un.
Ní ọdún 1952, Túndé Nightingale àti ọmọ ẹgbẹ́ olórin rẹ̀ ti a mọ̀ sí Àgbà Jolly Orchestra, máa ń ṣeré ní gbogbo ìgbà ní ibi Ìgbafẹ́ tí a mọ̀ sí West African Club, nilu Ìbàdàn. Àwọn olórin ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ tí wọ́n ń figagbága lásìkò náà ni Àyìndé Bákàrè, I. K. Dairo àti Délé Òjó. Ẹ̀wẹ̀, láàrín ọdún 1952 yí náà ni ẹgbẹ́ yí pèlé sí i, tí wọ́n di ọmọ ẹgbẹ́ mẹ́jọ nilu Ìbàdàn.
Láàrín ọdún 1954 àti 1964, orin Nightingale tún mìgboro tìtì fún ìgbà ráńpẹ́. Ṣùgbón, láàrín ọdún 1960 yi náà ni Ó tọwó be Ìwé àdéhùn pẹ̀lú Ọ̀gbèni Jossy Fajimolu láti ṣe orin rẹ̀ jáde, léyìí tó mi orin rẹ̀ gbáfẹ́ àwọn jayéjayé àti àwọn gbàjúmọ̀ nilu Èkó, tí wọ́n gbàgbọ́ pé irúfẹ́ orin rẹ̀ dára fún òde ráńpẹ́ tàbí alábọ́ọ́dé yàtọ̀ sí èyí tí wọ́n ń ṣe nínú gbọ̀gàn ńlá.
Túndé Nightingale ri wí pé ìdàgbàsókè tó múnádóko dé sí orin rẹ̀, ti o sì di orin ìgbà ló dé ti wọ́n ló ní ibi ìnáwó onírúurú, ti ó ìlú mọ̀ọ́ká, tí wọ́n ń pè ní Ṣó Wàmbẹ̀, èyí tó túmọ̀ si ilẹ̀kẹ̀ tí àwọn Obìnrin máa nso sí ìbàdí wọn ti wọ́n bá n jo.
Ní àárín ọdún 1960 yìí bákannáà, tí orin yi ń mi Ìlú tìtì láàrín àwọn gbàjúmọ̀ Ìlú Èkó ni wọ́n ṣe agbátẹrù àti ràn-án lọ́wọ́ fun ìrìnàjò, láti lọ kọrin ní àwọn ìlú ńlá ńlá lóke òkun.
Àmọ́ ṣá, nígbà tí ó dé láti ìrìn àjò láti òkè òkun, o tún fọwọ́ sí Ìwé àdéhùn pẹ̀lú ilé iṣẹ́ TYC.
Ní àkótán, Nightingale tẹ àwo orin tó lè ní ogóji jáde fún iṣẹ́ tó yan láàyò. Àwọn olórin ìgbà ló dé bíiKing Sunny Ase ati Queen Ayọ̀ Balógun ni wọ́n fi orin rẹ̀ ṣe àwòkọ́ṣe. Yàtọ̀ sí Ohun orin tí kò láfiwé, o tún ń sin ẹyẹ olóhún dídùn tíírín nínú ilé tó ń gbé.
Itokasi
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
Àyọkà yìí tàbí apá rẹ̀ únfẹ́ àtúnṣe sí. Ẹ le fẹ̀ jù báyìí lọ tàbí kí ẹ ṣàtúnṣe rẹ̀ lọ́nà tí yíò mu kúnrẹ́rẹ́. Ẹ ran Wikipedia lọ́wọ́ láti fẹ̀ẹ́ jù báyìí lọ. |