Turai Yar'Adua

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Jump to navigation Jump to search
Turai Yar'Adua
Turai Yar'Adua.jpg
Aya Ààrẹ-àná, Umar Musa Yar'Adua
In role
Ọjọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n oṣù karùn-ún ọdún 2007 – Ọjọ́ karùn-ún, oṣù karùn-ún ọdún 2010
ÀàrẹUmaru Yar'Adua
AsíwájúStella Obasanjo
Arọ́pòPatience Jonathan
Àwọn àlàyé onítòhún
Ọjọ́ìbí26 Oṣù Keje 1957 (1957-07-26) (ọmọ ọdún 65)
Ìpínlẹ̀ Katsina
(Àwọn) olólùfẹ́Umaru Yar'Adua (1975–2010; his death)
Àwọn ọmọỌmọbìnrin márùn-ún, okùnrin méjì
Alma materAhmadu Bello University

Turai Yar'Adua tí wọ́n bí lọ́jọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n oṣù keje ọdún 1957,(26 July 1957)[1] jẹ́ opó sí Ààrẹ-àná tí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, ẹni tí ó tún jẹ́ Gómìnà-àná Ìpínlẹ̀ Kàtsínà, Umaru Musa Yar'Adua. Òun ní Obìnrin Àkọ́kọ́ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lọ́dún 2007 títí ọkọ rẹ̀, Ààrẹ-àná, Yar'Adua fi ta téru nípàá lọ́jọ́ karùn-ún oṣù karùn-ún ọdún 2010.

Ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n bí Turai Yar'Adua ní Ìpínlẹ̀ Kàtsínà lápá àríwá Naijiria lóṣù keje ọdún 1957.[1] Ó kàwé ní Government Girls Secondary School ní Kankiya nígbà èwe rẹ̀.[1]

Turai Yar'Adua kàwé àkọ́bẹ̀rẹ̀ ní Garama Primary School ní Katsina, tí ó sìn kẹ́kọ̀ọ́ girama ní ní Government Secondary School ní Kankia, ní Ìpínlẹ̀ Kàtsínà bákan náà. Lẹ́yìn náà, ó kàwé ní Katsina College of Arts, Science and TechnologyZaria, ní Ìpínlẹ̀ Kàdúná, níbi tí wọ́n ti sọ pé òun ní akẹ́kọ̀ọ́ tó mọ̀wé jù nígbà náà lọ́dún 1980.[1] In 1983, Yar'Adua received a bachelor's degree in Language from Ahmadu Bello University.[1][2]

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. 1.0 1.1 1.2 1.3 1.4 Gabriel, Chioma (2010-01-15). "Turai Yar'Adua - a Silent But Influential First Lady". Vanguard Media (AllAfrica.com). http://allafrica.com/stories/201001150880.html. Retrieved 2010-05-05. 
  2. Iliya, Christy. "Hajiya Turai: What Manner Of First Lady?". Leadership online (Leadership Newspapers Group). Archived from the original on 2007-09-30. https://web.archive.org/web/20070930002418/http://www.leadershipnigeria.com/product_info.php?%20products_id=7136. Retrieved 2007-09-22.