UNESCO-IHE
UNESCO-IHE (ilé-èkó nípa ìmò omi) jé ilé èkó ìlú mo'kaye tí a dá sílè ní odún 2003. UNESCO- IHE jé ìtèsíwájú isé tí ó bèrè ní odún 1957 n'igbati IHE kókó bèrè èkó ìmò èro fún àwon amòye làti orílè èdè to sèsè n'dìde alè.
UNESCO-IHE f'ibujoko sí ìlú Delft, ni orílè èdè Nedalandi, ó sì jé àjoni gbogbo omo egbé orílè èdè UNESCO. A se ìsèdálè rè gégé bi ilé-èkó oní gireedi èkíní nípasè àjosepò UNESCO àti ìjoba orílè èdè Nedalandi.
Ilé- èkó yi lo tóbi julo l'agbalaye nínú ìmò èkó omi ohun nikan si ni ilé èkó ti a fi àse fun nínú ètò UN (United Nations) làti fun ni n 'íwê èrí èkó àgbà (Msc degree).
Àwon ojúse ilé èkó UNESCO -IHE n'iwonyi:
- Làti le je apeere rere l'agbalaye nínú èkó àgbà fun ìmò omi
- Làti pese ètò igbe ni n'igunpa sókè papa julo fun awon orílè èdè to sèsè n'dìde alè
- Làti le pese èkó, ìtóni àti ìwádî ìjìnlè
- Ìpèsè ìjìnlè ìrírí àti ìmòràn lórí èkó omi
Làti ìsèdálè re wa ni odún 1957, IHE- gégé bi ati moosi- ti pese èkó àgbà fún àwon amòye (onímò èro àti siensi) tí ólé ni egbèrún mérìnlá, òpòlopò won làti àwon orílè èdè to sèsè n'dìde alè ,lápapò bi orílè èdè ogójo. O ti fi oyè fún àwon òmòwé ti ólé ni aarun di l'ogorin, bakan naa o ti se àwon isé ìwádî ìjìnlè àti ti igbe ni n'igunpa sókè kakakiri àgbáyé.
Àyọkà yìí tàbí apá rẹ̀ únfẹ́ àtúnṣe sí. Ẹ le fẹ̀ jù báyìí lọ tàbí kí ẹ ṣàtúnṣe rẹ̀ lọ́nà tí yíò mu kúnrẹ́rẹ́. Ẹ ran Wikipedia lọ́wọ́ láti fẹ̀ẹ́ jù báyìí lọ. |
Itokasi
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- UNESCO-IHE Archived 2007-08-04 at the Wayback Machine.