Jump to content

Uche Ekwunife

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Uche Ekwunife
Senator Uche Ekwunife
Senator ikọ̀ Anambra Central Senatorial District
Lọ́wọ́lọ́wọ́
Ó gun orí àga
June 2015
AsíwájúVictor Umeh
Member of the Nigerian House of Representatives from Anambra
In office
June 2007 – June 2015
ConstituencyAnaocha/Njikoka/Dunukofia
Àwọn àlàyé onítòhún
Ọjọ́ìbí
Uche Lilian Ogudebe

12 Oṣù Kejìlá 1970 (1970-12-12) (ọmọ ọdún 54)
Igbo-Ukwu, Anambra, Nigeria
Ẹgbẹ́ olóṣèlúPeople's Democratic Party (PDP)
(Àwọn) olólùfẹ́Larry Ekwunife
Alma materUniversity of Calabar (BSc)
Nnamdi Azikiwe University (MBA)
Websitehttps://senucheekwunife.com

Uche Lilian Ekwunife (Orúko abiso rè ni Ogudebe) ti a bi 12 January 1970 jẹ oloṣelú omobibi orílè-èdè Nàìjirià. Ó wà lara awon ti ọmọ ile igbimọ aṣo(Senato) kesan ti Nàìjirià, óún se a o ṣoju awọn eniyan Anambra Central Senatorial District ti Anambra. [1]

Àárò ayé àti èkó rè

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

A bi Ekwunife ni 12 December 1970 ni ilu Igbo-Ukwu, Anambra si inú idile Emmanuel ati Lucy Ogudebe. Ekwunife losi yunifasiti ti Calabar, o si kékó gboye ninu Business ati Accounting ni odun 1993. O tesiwaju lati gba oye MBA re ní ilé-ìwé giga Nnamdi Azikiwe ni 2002. [2] Ó fé Chief Larry Ekwunife [3]

Ekwunife díje fun ipo gomina Anambra lẹẹmeji laisi aṣeyọri. O díje fun ile igbimo asofin kekere(house of representative) lati se aṣoju agbegbe Anaocha/Njikoka/Dunukofia ti Anambra ni odun 2007, o sì jawe olubori.[4] O jẹ ọkan ninu awọn obinrin mokanla ti a diboyan sí ipò náà ní ọdun 2007 ti a tún diboyan ni ọdun 2011. Awọn obinrin toku ti a yan ni Juliet Akano, Mulikat Adeola-Akande, Abike Dabiri, Nkiru Onyeagocha, Nnena Elendu-Ukeje, Olajumoke Okoya-Thomas, Beni Lar, Khadija Bukar Abba-Ibrahim, Elizabeth Ogbaga ati Peace Uzo.

Ní ọdún 2015, a yàn sí ipò Sẹ́nétọ̀ Nàìjíríà. Ó jẹ́ ọ̀kan lára ​​àwọn obìnrin mẹ́fà tí a yàn sí National Assembly kejo. Awọn obinrin yooku ni Rose Okoji Oko, Stella Oduah, Fatimat Raji Rasaki, Oluremi Tinubu ati Binta Garba.[5] Nitoripe Ekwunife yí padà lati egbé oselu kan sí imiran láti jawe olubori ninu idibo odun 2015, a yó kuro nípò Senato ní December 2015, a si yan Victor Umeh sí ipò Senato. [6]

O jawe olubori fún ipo ile igbimọ aṣofin agba ti ipinlẹ Anambra ni ọdun 2019 labẹ egbe oselu People's Democratic Party(PDP) , o se asoju Anambra Central Senatorial District, Nàìjirià, oludije alatako rè, Victor Umeh fìdíremi.

  1. "ShineYourEye". ShineYourEye. Retrieved 2022-05-20. 
  2. "EKWUNIFE, Sen Uche Lilian". Biographical Legacy and Research Foundation. 2017-08-23. Retrieved 2022-05-20. 
  3. "Lilian Ekwunife biography, net worth, age, family, contact & picture". Nigeria Business Directory - Find Companies, People & Places in Nigeria. 2015-12-07. Retrieved 2022-05-20. 
  4. "Ekwunife wins re-run poll in Anambra". Premium Times Nigeria. 2012-02-16. Retrieved 2022-05-21. 
  5. Obiajuru, Nomso (2015-05-29). "MEET The 6 Female Senators In 8th National Assembly (PHOTOS)". Legit.ng - Nigeria news. Retrieved 2022-05-21. 
  6. Owete, Festus (2016-01-21). "APC panel disqualifies “fair-weather” Ekwunife from contesting Senate rerun on party’s platform". Premium Times Nigeria. Retrieved 2022-05-21.