Uduak Archibong
Uduak Emmanuel Archibong MBE jẹ Ojogbon ti difásítì àti Olùdarí Ilé-iṣẹ́ fún Ìfísí àti Difásítì n University of Bradford . Ó jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ ti Royal College títí Nọ́ọ́sì àti ọmọ ẹgbẹ́ ti Ilé ẹ̀kọ́ Gíga fún àwọn Nọ́ọ́sì ti Ìwọ̀oòrùn Áfíríkà.
Ìgbésí Ayé Èwe àti Ẹ̀kọ́
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Archibong tí á bí ti a sì tọ̀ọ́ dàgbà ni ìgbèríko Nàìjíríà . [1] Níbẹ̀ ni ó ti kẹ́kọ̀ọ́ Nọ́ọ́sì tí ó sì gbà àmì ẹ̀yẹ pé ó pègedé jùlọ láàárín àwọn akẹ́gbẹ́ rẹ̀ èyí tí àwọn elédè Gẹ̀ẹ́sì pé ní First Class Honours láti Ilé Ìwé Gíga tí Yunifásítì Nàìjíríà, Nsukka. Ó kó lọ sí Hull, ní Ìlú England , níbẹ̀ ni ó ti gba ìwé ẹ̀rí dọ́kítà nínú ṣíṣe ìwádìí ìtọ́jú tó dá lórí ẹbí àti ẹ̀kọ́ nọ́ọ̀sì ní Nàìjíríà . [2] O tún kẹ́kọ̀ọ́ gẹ́gẹ́ bí Nọọsi ní ètò Ìlù tí àwọn elédè Gẹ̀ẹ́sì ó sì ń ṣiṣẹ́ ní àwọn ilé ìwòsàn National Health Services. Ó ṣiṣẹ́ ní Ilé ìwòsàn Hull Royal àti ní Ilé Ìtọ́jú Queensgate. Archibong rí wípé a kò ṣe ìtọ́jú àwọn aláwọ̀ dúdú àti àwọn obìnrin àti ọkùnrin aláwọ̀ yòókù tí wọ́n kò pọ̀ ní ètò ìwòsàn tí Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti pé ìyapa máa dé bá àwọn alámọ̀dájú ìtọ́jú ìlera tí wọ́n jẹ́ aláwọ̀ dúdú láti ọ̀dọ̀ àwọn aláìsàn àti àwọn elẹ́gbẹ́ wọn. àwọ elédè Gẹ̀ẹ́sì no
Ìwádìí àti Iṣẹ́ Rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ní ọdún 1995 Archibong lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Gíga ti Bradford, níbẹ̀ ni ó ti ṣíṣe olùkọ́ni nínú Ẹ̀kọ́ ìtọ́jú aláìsàn.. Ó gba ìgbéga, ó di olùkọ́ni àgbà, ó sì padà di Adarí àwọn Olùtọ́jú Aláìsàn ní ọdún 1999. O di ọmọ ẹgbẹ́ ti Ilé ẹ̀kọ́ Gíga fún Nọ́ọ́sì ti Ìwọ̀ oòrùn Áfíríkà ní ọdún 2001 ati Ọjọgbọn ti Difásítì ni ọdún 2004. [2] Archibong ṣiṣẹ́ bi olùdámọ́ọ́ràn ìlànà ti Ilé-ẹ̀kọ́ Gíga fún ìbádọ́gba àti difásítì. [2] Ó ṣe àfihàn pé àwọn aláwò dúdú àti àwọn alámọ̀dájú tí wọ́n jẹ́ ẹ̀yà kékeré nínú Ilé-iṣẹ́ Ìlera ti Orílẹ̀èdè ni o ṣéṣe díẹ̀ fún láti gba ìbáwí ju àwọn ẹlẹ́gbẹ́ wọn tí wọ́n jẹ́ aláwọ̀ funfun lọ tí wọ́n sì ní ìgbàsílẹ̀ ìṣe àti ìhùwàsí kan náà.
A yàn ní Ọ̀jọ̀gbọ́n ti Difásítì àti Olùdarí ti Ilé iṣẹ́ fún Ìfíkún àti Difásítì ní Ilé Ìwé Gíga ti Bradford, níbẹ̀ ni ó ti ṣe àkóso nẹ́tíwọ́kì Genovate.
Àmì Ẹ̀yẹ àti Ọ̀la Tí a fún
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]O yàn gẹ́gẹ́ bí ọmọ ẹgbẹ́ ti Ilé Ìwé Gíga fún àwọn olùkọ́ tí ìtọ́jú ìlera ti Royal ni ọdún 2012. Ni ọdún 2015, á sọ́ di àṣẹ ti Ìjọba Gẹẹsi fún àwọn iṣẹ́ rẹ̀ si ètò-ẹ̀kọ̀ gíga àti ìbádọ́gba. [3] A dárúkọ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára Àwọn Obìnrin Agbára Àríwá ní ọdún 2019 àti ọ̀kan nínú Àwọn Obìnrin tí ń fún ni Ìmísí ti Bradford ni ọdún 2020.
Àwọn Ìtọkási
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ (in English) A champion for race equality and diversity: a high flyer throughout her career, Uduak Archibong has been appointed Bradford's first professor of diversity. https://go.gale.com/ps/i.do?p=AONE&sw=w&issn=00296570&v=2.1&it=r&id=GALE%7CA123330051&sid=googleScholar&linkaccess=abs.
- ↑ 2.0 2.1 2.2 Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid
<ref>
tag; no text was provided for refs named:0
- ↑ "New year honours 2015: the full list" (in en-GB). https://www.theguardian.com/uk-news/2014/dec/30/-sp-new-years-honours-2015-full-list.