Jump to content

Uju Ugoka

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Uju Ugoka Ogbodo
Uju Ugoka taking a foul shot at Virginia Tech in 2013
No. 1 – La Roche Vendée Basket Club
PositionPoint guard
LeagueLigue Féminine de Basketball
Personal information
Born24 Oṣù Kàrún 1993 (1993-05-24) (ọmọ ọdún 31)
Lagos, Nigeria
NationalityNigerian
Listed height6 ft 1 in (1.85 m)
Listed weight146 lb (66 kg)
Career information
College
NBA draft2014 / Undrafted
Pro playing career2014–present
Career history
2014-2015Pallacanestro Vigarano
2015First Bank Basketball Club
2015-2016Basket Parma
2016-2018AZS-UMCS Lublin
2018-presentLa Roche Vendée Basket Club

Uju Ugoka Ogbodo (tí wọ́n bí ní 24 May 1993) jẹ́ agbábọ́ọ̀lù alájùsáwọ̀n ti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, fún ẹgbẹ́ La Roche Vendée Basket Club àti Nigerian national team.[1][2] Ó gbá bọ́ọ̀lù náà fún ilé-èkọ́ rẹ̀, lábẹ́ ẹgbẹ́ Virginia Tech Hokies women's basketball.[3]

Iṣẹ́ tó yàn láàyò ní ilé-ẹ̀kọ́ gíga

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ugoka kó lọ sí United States lẹ́yìn tó ṣiṣẹ́ ní Hope for girls basketball camp, èyí tí Mobolaji Akiode dá sílẹ̀. Ó gbá bọ́ọ̀lù alájùsáwọ̀n gẹ́gẹ́ bíi ọmọ ọlọ́dún kìíní ní Grayson County College, ṣíwájú àkókò kí wọ́n tó mú ìdádúró bá gbígbá bọ́ọ̀lù alájùsáwọ̀n ní ọdún 2011, wọ́n mú u wọ ẹgbẹ́ NJCAA All-America honors.[4] Ó wá lọ sí Gulf Coast State College Commodores ní ọdún kẹta rẹ̀, pẹ̀lú ipò 16.69, 8.79 àti ìránlọ́wọ́ 0.93. Ó gba àmì-ẹ̀yẹ agbábọ́ọ̀lù tó dára jù ti NJCAA All-America honors.[5] Lẹ́yìn náà ni wọ́n gbé e lọ sí Virginia Tech Hokies women's basketball ní ọdún 2012 fún ẹ̀kọ́ ọlọ́dún kékeré àti ọlọ́dún àgbà.[6] Lásìkò tó wà ní ọdún kékeré, ó gba ipò 12.5 àti àtúnṣe 8.5.[7] Ní ọdún àgbà rẹ̀, ó gba ipò 18.4, àtúnṣe 9.6 àti ìrànlọ́wọ́ fún ayò kọ̀ọ̀kan.[8][9]

Iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí i agbábọ́ọ̀lù fún orílẹ̀-èdè

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ugoka ṣojú Nàìjíríà ní 2008 FIBA Africa Under-18 Championship for Women níbi tí ó ti gba ipò 3 points àti àtúnṣe 3.[10][11]

Ugoka ṣojú Nàìjíríà bákan náà 2009 FIBA Africa Championship for Women, níbi tí ó to gba 7 points, àti àtúnṣe 3.2 pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ 0.5 nínú ayò kọ̀ọ̀kan.[12] Ní 2009 FIBA Africa Championship for Women, ó gba 7.4 points, àtúnṣe 5.1 àti ìrànlọ́wọ́ 0.3 nínú ayò kọ̀ọ̀kan.[13] Ugoka tún ṣojú Nigerian national team ní 2016 FIBA World Olympic Qualifying Tournament for Women tó wáyé ní France, ó gba 5 points, àtúnṣe 5 àti ìrànlọ́wọ́ 1 nínú ayò kọ̀ọ̀kan.[14][15]

Àwọn ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]